Wọ́n pè mí ní olè, ajagungbalẹ̀ lórí ọ̀nà Circular Road àmọ́ mi ò jẹ ẹnìkankan ní àlàyé - Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Tinubu

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde ti sọ gbogbo orúkọ tí kò dára táwọn èèyàn kan ń pe òun nítorí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ Circular Road ti ìlú Ibadan kò tui run kankan lára òun.

Makinde ní ọ̀kan lára òun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn olórí ni.

Ó sọ èyí lásìkò tó ń ṣí ibùdókọ̀ Ibadan sọ pé àwọn tó ń ṣe ìfẹ̀hónúhàn ti pe òun ní àwọn orúkọ oríṣiríṣi bíi ẹni tó ń já ilẹ̀ gbà olè àtàwọn orúkọ míì tí kò dára.

Ó fi kun pé ẹnikẹ́ni tó bá ẹ̀rí pé òun jẹ lára ilẹ̀ circular road náà láti mú ẹ̀rí wọn síta, bó ṣe ní àfíkún ilẹ̀ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta mítà tí wọ́n fi kun ilẹ̀ náà ló wà fún mínú ìgbèrú bá ètò ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ Oyo.

Ó tẹ̀síwájú pé gbogbo ìfẹ̀hónúhàn táwọn èèyàn ń ṣe ni òun rí àmọ́ òun kò ní bá àwọn tó ń ṣe ìfẹ̀hónúhàn náà sọ̀rọ̀.

Makinde ní káwọn tí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ náà kàn jẹ́ kí àwọn pàdé ní òpópónà circular road fún ìjíròrò, tó sì tẹnumọ pé àwọn tó ń ṣe ìfẹ̀hónúhàn báyìí kìí ṣe àwọn tó ni ilẹ̀, pé àwọn kan ló ń ṣe agbátẹrù wọn.

Ó ní àkànṣe iṣẹ́ òpópónà náà ti ń wáyé fún ọdún pípẹ́, tó sì nílò kí wọ́n mú ìgbòòrò bá a fún ètò ọrọ̀ ajé.

Lẹ́yìn ò rẹyìn, ìjọba Oyo wẹ ara rẹ̀ mọ́ lórí ìwọ́de nípa ọ̀nà Circular, di ẹ̀bi ru ọ̀pọ̀ àwọn olùwọ́de tí wọn fẹ́ wó ilé wọn

Latigba ti ifẹhonuhan ti bẹrẹ niluu Ibadan, lati ọdọ awọn ti ijọba Gomina Seyi Makinde fẹ wo ile wọn lori atunṣe ọna Circular, ni awọn eeyan ti n reti pe ki ijọba ipinlẹ Oyo sọrọ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bi ifẹhonuhan naa ṣe n tẹsiwaju, ijọba Gomina Seyi Makinde ti pada sọ abala tirẹ ninu igbesẹ naa.

Olugbani-nimọran pataki fun Gomina Makinde lori idasilẹ ilu tuntun ati igboro, Mofoluke Adebiyi, ṣalaye pe ọpọ awọn ile ti ọrọ yii kan ni ko ni iwe aṣẹ ikọle gidi.

Adebiyi, to sọrọ nibi ipade awọn oluwoye awujọ to waye niluu Ibadan lọjọ Iṣẹgun ana, sọ pe, awọn ile ti wọn kọ ni ibamu pẹlu ofin ile kikọ ni ijọba ipinlẹ Oyo n fẹ.

O ni o ṣe pataki lati tun jẹ ki iru rẹ pọ si i nipinlẹ Oyo.

Gẹgẹ bo ṣe wi, aaye mita ẹẹdẹgbẹta( 500m) to wa lẹgbẹ mejeeji ọna Circular ọhun ni wọn ti se agbekalẹ bi wọn yoo ṣe ṣe e lati ọdun 2018, ti wọn si tẹ ẹ jade .

'Apejuwe ọna Circular Road yii, ninu iwe naa fi han pe wọn fi aaye ẹsẹ bata (60m), ati ọgbọ̀n (30 m) silẹ ni ẹgbẹ mejeeji, ati 470m ni ẹgbẹ mejeeji lapa ibi to jẹ horo loju ọna yii.'

Adebiyi lo ṣalaye bẹẹ.

O fi kun un pe, mita marundinlọgọrin to jẹ dandan (75 meters) lẹgbẹ mejeeji to ṣẹku, ni ijọba yoo lo lati fi ṣe iloro ti awọn eeyan le gba.

Ṣé àwọn tọ́rọ̀ kàn tí rí owó gbà-má-bínú gbà?

Nigba to n sọrọ nipa awọn eeyan ti ọrọ ile wiwo yii kan, pe ṣe wọn ti ri owo gba-ma-binu gba lati ọdọ ijọba, Adebiyi sọ pe awọn ọgọsan-an (190) ninu 298 ile ti ọrọ naa kan ni wọn ti ri owo gba.

' Oriṣiiriṣii ọna lo wa ti awọn eeyan ti ọrọ yii kan le gba ri ohun ti wọn fẹ; o le jẹ nipasẹ owo tabi kiko wọn lọ si agbegbe miran lati maa gbe.

" Ohun to ṣee ṣe ni, ṣugbọn bawọn eeyan ba ṣe sọrọ ni yoo sọ ohun to maa ṣẹlẹ.

Bẹẹ ni Olugbani-nimọran lori ile tuntun kikọ ati igboro fun Gomina Makinde sọ.

N jẹ ijọba le ṣiju aanu wo awọn eeyan naa, ko si din ẹẹdẹgbẹta mita yii ku?

Adebiyi sọ pe ijọba wulẹ ti gbiyanju pẹlu 150 mita ti wọn la kalẹ fun awọn agbegbe to ba ti di igboro.

Ati 500m fun awọn ti ko ti i di ilu nla.

Ṣaa, ẹni ebi n pa ko ni i ye wi, ni ọrọ yii jẹ fun awọn eeyan ti ile wọn fẹ di wiwo yii, wọn ko yee ṣipẹ fun oju aanu ijọba Seyi Makinde.

Àkọlé fídíò, Ọlọ́pàá tó wà lórí àárẹ̀

Àwọn olùgbé ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́fà ṣe ìwọ́de n'Ibadan, fẹ̀sùn kan Makinde pé ó ta ilẹ̀ ilé wọn fáwọn abulẹ̀ṣowó torí ó fẹ́ la ọ̀nà

Ọpọ awọn olugbe ijọba ibilẹ mẹfa ni ilu Ibadan, olu ilu Ipinlẹ Oyo, ni wọn fi ehonu wọn han lọjọ Aje, ọjọ kẹwaa oṣu kọkonla ọdun 2025.

Kókó ẹhonu náà ni bi ijọba Ipinlẹ Oyo se n gbiyanju lati wo ile won lulẹ torí ojú ọ̀nà olobiripo Circular to fe la.

‎Awon olugbe ijọba ibilẹ, Egbeda, Ido, Akinyele, Ona Ara, Lagelu ati Oluyole ni wọn ko ara wọn jọ sí iwájú iléeṣẹ́ ìjọba lọ́gbà Secretariat láti ṣe ìwọ́de náà.

Ìdí ni pé ijọba Ipinlẹ Oyo fẹ mú ẹẹdẹgbẹta mita ilẹ̀ si apa ọtun ati osi opopona obiripo (Circular Road) ti ijọba Ipinlẹ Oyo n ṣe lọwọ.

‎Awon olufehohan naa ni wọn bẹrẹ iwọde laarọ ni agbegbe Iwo Roa, ti wọn si daa lílọ bibo ọkọ ati Irina duro ni agbegbe ọhun.

"A fún gómìnà ní ọjọ́ meje láti yí ìpinnu rẹ̀ padà lórí wiwo ilé wa, a kò ní dẹkùn ìwọ́de wá"

‎Awon apa kan olufehonuhan naa wa si ile ṣe ijọba Ipinlẹ Oyo, ti wọn si gbe opolopo àkọlé lọwọ lati fi aidunnu wọn han si igbese ìjọba Ipinlẹ Oyo yii.

‎Awọn olugbe ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́fà ọhun ṣàlàyé pé bi ijọba ipinlẹ Oyo ba tesiwaju pẹlu igbesẹ yìí, o le ni eeyan ẹgbẹrun lọna ọọdunrun 300,000 ti yoo di alainilelori ni ìjọba ibile mẹ́fà tí opopona naa yoo gba kọja.

‎Ninu ifọrọwerọ pẹlu akọroyin BBC News Yorùbá, Ọmọọba Niyi Fasoye ni, Gomina Ipinlẹ Oyo Seyi Makinde ti kuna lati mu ileri rẹ ṣẹ pẹlu bii àwọn oṣiṣẹ ileeṣẹ to ń ri si ilegbe ati idagbasoke Ipinlẹ Oyo ti gunle wiwo awọn ile awọn.

‎Fasoye tẹsiwaju wi pe ọjọ meje ni awọn olugbe agbegbe ìjọba Ipinlẹ mefefa ti ọrọ naa kan fun ìjọba Ipinlẹ Oyo lati yii ìpinnu rẹ pada, laijebẹ awọn ko ni sinmi ifẹhonuhan naa, ko si ni dópin.

‎O fikun pe inu awọn dun ii ìjọba Ipinlẹ Oyo ṣe n ṣe opopona marose circular road naa sugbọn igbese ijọba lati mu ju mita 75 to wa ninu iwe akosile Ṣaaju ni ko dun mọ awọn ninu.

"Ilẹ ti ijọba Ipinlẹ Oyo fẹ gba lọwọ wa to pulọti ilẹ ogun si apa ọtun àti ogun pulọti si apa osi"

Fasoye tesiwaju wi pe "Ọjọ meje la fún ijọba Ipinlẹ Oyo lati jade bá wà sọrọ, papa julọ, Gomina Seyi Makinde, ti wọn ba kọ lati ba wa sọrọ lori rẹ, ifẹhonuhan naa ko ni tan".

‎Azeez Abass, ọkan lara awọn to n ṣe ifẹhonuhan naa ni,"ilẹ ti ijọba Ipinlẹ Oyo fẹ gba lọwọ wa to plot ilẹ ogun si apa ọtun àti ogun plot si apa osi.

Igbesẹ yii yoo sọ ọpọ eeyan di alaini ile lórí, a sì ni ẹri to dájú wi pe ijọba ti ta ilẹ wa fun awọn abulẹ sowo.

‎Lara awọn eeyan ti wọn wo ile wọn lọ́dún to kọja, owo gba mabinu ti ijọba Ipinlẹ Oyo fun wọn ko to ra ile dipo ti yoo kọ ile, nibo ni ijọba fẹ ki wọn maa sun".

‎Awon oluwode naa wa ṣeleri lati tẹsiwaju ninu ifẹhonuhan naa titi ti ijọba yoo fi tẹti si ẹbẹ awọn.