''Wike jẹ̀bí pé ó pe ọmogun ní òmúgọ̀ àmọ́ iléeṣẹ́ ológun gbọdọ̀ dá ṣèríà fún ọmogun tó gbéná wojú Wike, káwọn ọmogun má ba à dáwọ́jọ lu mínísítà lọ́jọ́ kan''

Oríṣun àwòrán, Collage
Onimọ nipa eto abo kan to jẹ ajagun fẹyinti, Akin Adeyi, ti sọ pe ẹbi kan pere ni minisita ilu Abuja, Nyesom Wike, ni lori faakaja to waye laarin rẹ ati ọmogun oju omi kan l'Abuja lọjọ Iṣẹgun.
Ajagun fẹyinti Adeyi ni ẹbi Wike ni wi pe o pe ọmogun ni omugọ ni gbangba, ''amọ, nnkan to ṣokunfa faakaja yii ni pe ọga ileeṣẹ ọmogun oju omi tẹlẹ, Awwal Gambo, ko ri iwe ilẹ ko silẹ.
Iṣẹ Wike lo n ṣe pẹlu awọn oṣiṣẹ ajọ FCTA to n ri si eto iṣejọba ilu Abuja.
Ti wọn ba beere iwe ilẹ lọwọ eeyan, o ni lati ko o silẹ, kii ṣe pe ko wa ko awọn ọmọ ologun lọ sori ilẹ wi pe ki wọn maa yinbọn pa ẹnikẹni ti wọn ba ri lori ilẹ.
Iru ihuwasi yii ko tọna rara, eyi tumọ si pe ọgagun to ni ilẹ naa ko ni iwe.
Ẹkeji ni pe jija ilẹ onilẹ gba ni wọn maa n pe iru nnkan bayẹn,'' Ọgbẹni Adeyi ṣalaye.
''Didena mawọn oṣiṣẹ ijọba lati ṣiṣẹ wọn lodi sofin''
Onimọ nipa eto aabo naa tun sọ pe ta lo fawọn ọmogun to pọ to bayẹn laṣẹ lati lọ maa ṣọ ilẹ ọgagun to ti fẹyin ti lẹnu iṣẹ.
Ọgbẹni Adeyi ni iṣẹ ti ko tọna ni wọn maa n pe iru iṣẹ tawọn ọmogun yii n ṣe lori ilẹ naa.
''Fifi ibọn dẹru bawọn eeyan tawọn ologun yii n ṣe ko ba ofin mu.
Ati pe didena mawọn oṣiṣẹ ijọba lati ṣiṣẹ wọn naa lodi sofin.''
Ajagun fẹyinti Adeyi ni iyalẹnu lo jẹ foun wi pe ọpọ ọmọ Naijiria lo n fi oju oṣelu wo nnkan to ṣẹlẹ.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
''Afaimọ kawọn ọmogun ma dawọ jọ lu minisita tabi gomina lọjọ kan, pẹlu bi ọpọ eeyan ṣe n gboriyin fun ọmogun yii''
Ọgbẹni Adeyi ni iwa arifin ni ọmogun oju omi tawọn eeyan n gboriyin fun yii lori ayelujara hu si Wike to jẹ minisita orilẹede Naijiria.
''Wọn kọ wa ninu iṣẹ ologun wi pe awọn alagbada to wa ni ijọba lọga wa.
Iwa abuku ni ọmogun yii hu, o yẹ ko ranti wi pe ọga lawọn minisita jẹ fun awọn ọga ileeṣẹ ologun Naijiria gan an.
Yatọ si iṣẹ ologun gan an, ọmogun yii ko huwa bi ẹni to ti ile rere jade.
Ọmogun yii ko huwa bi ẹni pe iwa ibọwọfun agba si tun wa ninu iṣẹ ologun.
To ba jẹ pe ologun ni Wike ni, ọgagun agba ni ko ba jẹ ninu iṣẹ ologun.''
Ajagun fẹyinti Adeyi ni awọn araalu naa lo n kanrin mọ awọn ọmogun lapa ti wọn fi n ṣiwa hu.
Onimọ nipa eto aabo naa sọ pe ileeṣẹ ologun gbọdọ da ṣeria fun ọmogun yii kawọn akẹgbẹ rẹ to maa wo o bi awokọṣe.
Ọgbẹni Adeyi ni pẹlu bi ọpọ eeyan ṣe n gboriyin fun ọmogun yii, afaimọ kawọn ọmogun ma dawọ jọ lu minisita tabi gomina lọjọ kan.
O ni ko si apọnlẹ ninu ki ọmọde maa ṣe arifin si agbalagba
Olórí ọmogun ilẹ̀ tẹ́lẹ̀ ní Wike gbọdọ̀ tọrọ àforíjìn lórí ìhùwàsí rẹ̀, Igbokwe ní ọmogun tó bá Wike fa aáwọ̀ gbọdọ̀ fiṣẹ́ sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Lere Olayinka/X
Awuyewuye si n lọ lori faakaja to ṣẹlẹ laarin minisita ilu Abuja, Nyesom Wike, ati ọmogun oju omi Naijiria kan l'Abuja lanaa ọjọ Iṣẹgun ọjọ kọkanla oṣu Kọkanla ọdun yii.
Ọga agba ọmogun oriilẹ Naijiria tẹlẹri, Tukur Buratai, ti sọ pe ihuwasi Wike kudiẹ kaato gẹgẹ bii aṣoju Aarẹ Bola Tinubu.
Ede-ai-yede bẹ silẹ nigba ti Wike atawọn iṣọmọgbe rẹ lọ sori ilẹ kan niluu Abuja eyi ti wọn bawọn ọmogun lori rẹ.
Wike, to ṣalaye wi pe ẹni to ni ilẹ naa to jẹ ọga ọmogun oju omi tẹlẹri, Awwal Gambo ko ni awọn iwe ilẹ ọhun, fẹ fi ipa wọ ori ilẹ naa, amọ, ọmogun to ba nibẹ ko gba a laaye.
Eyi lo jẹ ki Wike maa tabuku ọmogun naa ti o si n pe ni oniruuru orukọ kobakungbe.
Amọ, pẹlu gbogbo ọrọ ti Wike sọ, ọmogun naa ko gba a laaye lati wọ ori ilẹ ọhun.
Ninu ọrọ tiẹ, ọgagun Buratai ni ihuwasi Wike le ṣakoba fun eto aabo Naijiria, o si yẹ ki ijọba apapọ gbe igbesẹ lori rẹ.
Olori ọmogun oriilẹ ni Naijiria tẹlẹri sọ pe Wike gbọdọ aforijin pẹlu bi o ti tabuku ọmogun Naijiria.
Buratai ni nnkan ti Wike ṣe si ọmogun Naijira tabuku Aarẹ Tinubu funra rẹ to jẹ olori ologun Naijiria.
O yẹ ki wọn le ọmogun to fa aawọ pẹlu Wike kuro ninu iṣẹ ologun - Igbokwe
Ẹwẹ, eekan inu ẹgbẹ oṣelu APC kan, Joe Igbokwe, ti sọ pe o yẹ ki ileeṣẹ ologun le ọmogun to fa aawọ pẹlu Wike lori ilẹ l'Abuja kuro ninu iṣẹ ologun.
Igbokwe ni iwa abuku gbaa ni ọmogun naa hu si minisita olu ilu orilẹede Naijiria, Abuja.
''Ta ni ọmogun yii gan an to wo aṣọ ologun? Ta lo n lulu fun un gan an ti o fi n jo?
Iwa buruku gbaa ni ọmogun yii hu o, koda, o yẹ ki wọn le kuro ninu iṣẹ ologun ni,'' Igbokwe lo sọ bẹẹ.
Oludamọran minisita Abuja lori eto iroyin, Lere Olayinka, ni tiẹ fẹsun kan ọga ọmogun oju omi tẹlẹ pe oun lo ni ki ọdọmọde ọmogun naa dena mọ Wike ki o ma ba raye wọ ori ilẹ ti ẹjọ wa lori rẹ naa.
Ileeṣẹ ologun fi iṣẹ wọn silẹ, ilẹ ni wọn n lọ ṣọ l'Abuja - Sowore
Oludije fun ipo aarẹ lọdun 2023 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu AAC to tun jẹ ajafẹtọọ ọmọniyan, Omoyele Sowore, ti bẹnu ẹtẹ lu bi awọn ọmogun to yẹ ki wọn maa daabo bo araalu ṣe n lọ ṣọ ilẹ ọga ologun niluu Abuja.
Nigba to n sọrọ loju opo X rẹ, Sowore ni imọtaraẹni nikan lo n ba awọn ọga ileeṣẹ ologun ja, ohun lo si jẹ ki wọn maa ko ọmogun lọ sori ilẹ.
''Iṣẹ awọn ọmogun ni lati maa ṣọ ibode orilẹede Naijiria, amọ, ilẹ awọn ọga ologun ni wọn n ṣọ kaakiri.
Ṣugbọn o ṣeni laanu wi pe iṣẹ ara wọn lawọn ọga ologun n fun awọn ọmogun lati maa ṣe.
Iru iwa yii wọpọ laarin awọn to wa nipo kan tabi omiran ni ijọba to fi mọ Wike funra rẹ,'''Sowore lo sọ bẹẹ.
Sowore ni Wike naa ti tako awọn agbofinro ri lẹnu iṣẹ wọn lasiko to wa nipo gomina ipinlẹ Rivers.
Wike, yago fun aawọ pẹlu awọn ologun – Shehu Sani
Sẹnẹtọ Shehu Sani toun naa jẹ ajafẹtọọ, ti rọ Wike wi pe ko yago fun aawọ pẹlu awọn ologun.
Sani sọ loju opo X rẹ wi pe iṣẹ ribi ribi ni Wike n ṣe loootọ lati gba ilẹ ijọba tawọn kan ti gba lọna aitọ pada.
Amọ, o rọ Wike wi pe ko ṣe pẹlẹ pẹlu awọn ọmogun orilẹede Naijiria.
''Wike n gbiyanju pẹlu iṣẹ ti o n ṣe niluu Abuja, amọ, o yẹ ko semẹdọ pẹlu ileeṣẹ ologun.
Kii ṣe Wike lo yẹ ko maa fa ijangbọn pẹlu awọn ọmogun.''
Faakaja to ṣẹlẹ laarin Wike ati ọmogun oju omi naa ti di nnkan ti ọpọ eeyan n sọ nipa rẹ lori ayelujara.
Ọpọ eeyan lo ti gboṣuba kare lai fun ọmogun naa lori ihuwasi rẹ pẹlu bi Wike ṣe sọrọ kobakungbe si i to.
Àlàyé rèé lórí ohun tó fa aáwọ láàrin Wike àti ọmọ ogun èyí tó ń fà awuyewuye

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ní ọ̀sán ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni fídíò kan gba orí ayélujára èyí tó ń fa awuyewuye.
Nínú fídíò náà ni mínísítà fun olú ìlú orílẹ̀ èdè yìí, Nyesom Wike àti ọmọ ogun ojú omi kan ti ń tahùn síra wọn.
Ohun tó jọ ni pé ọ̀rọ̀ ilẹ̀ kan ló ṣokùnfà àìgbọ́ra ẹni yé tó wáyé láàárín mínísítà àti ọmọ ogun náà.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló wáyé nígbà tí Wike àtàwọn òṣìṣẹ́ ìjọba fẹ́ wọ orí ilẹ̀ kan ṣùgbọ́n tí ọmọ ogun náà dáwọn dúró wí pé wọn kò lè wọ ibẹ̀.
Wike, ẹni tó ń bínú nínú fídíò náà ń bèèrè lọ́wọ́ ọmọ ogun náà pé ìwé àṣẹ wo ló ní tí wọ́n fi wà lórí ilẹ̀ náà tàbí láti fẹ́ ṣiṣẹ́ le lórí?
Amọ tí ọmọ ogun náà kò kúrò níwájú rẹ̀, tó sì ń da lóhùn àwọn ìbéèrè rẹ.
Mínísítà náà bèèrè pé kí ọmọ ogun náà ṣàfihàn ìwé ilẹ̀ tó wà lọ́wọ́ wọn, tí wọ́n fi ń dá ààbò bo ilẹ̀ náà.
"Fi ìwé ilẹ̀ tí ẹ ní hàn mí, ẹ ò ní ìwé.
Ìwé tí wọ́n fún-un yín láti fi ṣiṣẹ́ lórí ilẹ̀ yìí dà, báwo ni ọkùnrin náà pẹ̀lú ipò tó wà, tí kò ní ìṣòro kankan, kí ó kọ̀wé láti rí àwọn nǹkan tí mo ní, àmọ́ àwọn ọmọ ogun ló kó wá láti fi halẹ̀ mọ́ ta a ni?"
Ṣùgbọ́n ọmọ ogun náà fún Wike lésì pé níṣe ni òun ń tẹ̀lé àṣẹ tí wọ́n fún òun.
Èyí ló bí Wike nínú tó sì sọ pé kò sí ẹnikẹ́ni tó tóbi ju òfin lọ.
"Kò sí ẹni tó tóbi ju ìjọba lọ, ẹ ò lè máa gbé ìbọn láti fi máa halẹ̀ mọ́ àwọn èèyàn láti má ṣe iṣẹ́ wọn."
Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ogun náà tó fún Wike lésì sọ pé àwọn ní ìwé ilẹ̀ àti pé àwọn tẹ̀lé ìlànà òfin bí àwọn ṣe wà lórí ilẹ̀ náà.
"Gbogbo ìwé ilẹ̀ ni a gbà ní ìlànà tó yẹ.
Ọmọ ogun tó máa ń ṣe òótọ́ ni mí. Mi ò ní dákẹ́, ẹ ò ní pa mí lẹ́nu mọ́.
Bí ìfaǹfà náà ṣe ń peléke si ni Wike pe ọmọ ogun náà ní ọ̀dẹ̀ tó sì fún Wike lésì padà wí pé òun kìí ṣe ọ̀dẹ̀.
"Ọ̀gá, mi ò kí ṣe ọ̀dẹ̀, àṣẹ nim ò ń tẹ̀lé. Ológun ni mí, àṣẹ ni mo máa ń tẹ̀lé."
Wike fèsì pé òun kò ní jẹ́ kí wọ́n kọ́lé sórí ilẹ̀ náà, "tí ẹ bá fẹ́ pa gbogbo èèyàn, ẹ pa gbogbo èèyàn. A ò ní sọ pé nítorí ẹ jẹ́ ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ológun orí omi, kí o bẹ̀rẹ̀ sí ní gba gbogbo ilẹ̀."
Wike ṣàlàyé nípa bí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ tó fa ìfaǹfà láàárín rẹ àti ọmọ ogun ṣe jẹ́
Lẹ́yìn ìfaǹfà tó wáyé láàárín ọmọ ogun náà ni Wike bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ láti ṣàlàyé nǹkan tó wáyé gangan ní pàtó.
Ó ní àwọn òṣìṣẹ́ tó ń mójútó ọ̀rọ̀ ilẹ̀ ni wọ́n ń bá iṣẹ́ oòjọ́ wọn lọ, kí òun tó gbọ́ pé àwọn èèyàn kan lọ fi àwọn ọmọ ogun lé wọn kúrò lẹ́nu iṣẹ́.
Ó ní ó jẹ́ nǹkan tí kò bójúmu rárá nítorí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí ló máa ń dá ètò ìdàgbàsókè dúró.
"Ẹ̀ka tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ ní àṣẹ láti lọ máa wo àwọn ibi tí kò yẹ láti kọ́lé sí àtàwọn tó ń gba ilẹ̀ lọ́nà àìtọ́."
"Nígbà tí wọ́n wá síbí, wọ́n ní àwọn ọmọ ogun lé àwọn jáde, mo ní ó ṣeéṣe kí wọ́n máa ṣe iṣẹ́ tí kò tọ́ ló jẹ́ kí n wá síbí láti wá wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ fúnra mi."
Gẹ́gẹ́ bí Wike ṣe sọ, ó ní ohun bèèrè ìwé ilẹ̀ àti ìwé àṣẹ tí wọ́n gbà láti fi kọ́ ilé tí wọ́n fẹ́ kọ́ sórí rẹ̀.
Ó ní òun kò ní gbà kí ẹnikẹ́ni dúnkokò tàbí pa òun lẹ́nu mọ́ láti má ṣe iṣẹ́ òun.
"Ẹ gbọ́ ohun tí ọmọ ogun náà sọ pé ọ̀gá tẹ́lẹ̀ rí fún iléeṣẹ́ ológun orí omi kan ló rán àwọn wá.
"Kò yé mi bí ẹni tó wà ní irú bẹ́ yẹn ṣe máa ní ìṣòro tí kò ní lè kàn sí ọ́fíìsì mi láti sọ pé nǹkan báyìí ni òun ń fẹ́.
"Àmọ́ mi ò kí ṣe èèyàn tó máa ń tẹ̀rì sí ìdúnkokò tàbí jẹ́ kí wọ́n halẹ̀ mọ́ òun."
Ó fi kun pé òun ti bá àwọn ọ̀gá iléeṣẹ́ ológun sọ̀rọ̀ tí wọ́n sì ti fi dá òun lójú pé ọ̀rọ̀ náà níyanjú.
















