Ọmọ Yorùbá kan ló ta kò mi, tí ń kò fi bá iléèpò Shell ṣiṣẹ́ lẹ́yìn NYSC - Seyi Makinde

Ẹni tí mo gbàgbọ́ pé yóò ràn mí lọ́wọ́, ló jẹ́ kí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ mi níléeṣẹ́ elépo Shell - Makinde

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Gomina ipinlẹ oyo, Seyi Makinde ti sọrọ lori iriri aye rẹ, atawọn nnkan mii to ti lakọja ko to di gomina.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹle kan, Nigerian Tribune, Makinde tu ọpọ ọrọ ti awọn eeyan ko mọ nipa ohun ti oju rẹ ri lasiko to n ṣe agunbanirọ, bo ṣe fẹ gba bọọlu jẹhun atawọn nnkan mii.

Ifọrọwerọ naa lo n waye lati sami ọdun marundinlọgọta gomina Makinde loke eepẹ.

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

''Bọọlu ni mo fẹ kọkọ gba jẹun amọ..."

Makinde ninu ifọrọwerọ naa ṣalaye pe bọọlu ni oun kọkọ fẹ gba jẹun, amọ ibeere kan ti baba oun beere lọwọ oun, ti oun kuna lati dahun rẹ, lo mu ọkan oun kuro ninu bọọlu gbigba.

Yatọ si bọọlu gbigba, o tun ṣalaye pe oun fi akoko igba kan nifẹ si iṣẹ orin kikọ, to fi mọ ẹṣẹ kikan.

O ni “Mo ro pe mo le maa kan ẹṣẹ, mo tun fẹ maa kọ orin nitori King Sunny Ade.”

“Mo sọ fun iya mi ko ra ‘guitar’ ọmọde fun ni, mo si maa n kọ orin bii Sunny Ade pẹlu igbagbọ pe iṣẹ orin ni mo maa ṣe.”

Gẹgẹ bii ohun to sọ, ija laarin Dele Jonathan ati oyinbo alawọ funfun kan lo mu ko fẹran ẹṣẹ kikan.

Ṣugbọn bọọlu ti awon kan maa n gba ladugbo rẹ tun fa ọkan rẹ si ere bọọlu pẹlu.

"Mo fi ikọ agbabọọlu Shooting Stars pe Water Corporation ni mo se kuna lati gba bọọlu jẹun"

O ni “Lọdun naa lọhun, mo maa n gege daadaa lori papa, lọdun 1976, Shooting Stars gba ami ẹyẹ ifẹ ẹyẹ ilẹ Afrika.

Mo si lọ wo ifẹsẹwọnsẹ naa, mo wo Segun Odegbami, Besty Ogedengbe, Muda Lawal atawọn mii bi wọn ṣe n gba bọọlu.”

Lẹyin naa ni Makinde lọ sọ fun baba rẹ pe oun fẹ gba bọọlu jẹun, amọ nigba ti baba rẹ beere ẹgbẹ agbabọọlu ti yoo gba bọọlu fun, o ni Water Corporation.

Igbagbọ rẹ ni pe Water Corporation ni Sam Ojebode n gba bọọlu fun.

Amọ nitori baba rẹ ọhun jẹ alatilẹyin Shooting Stars, to si ṣi Shooting Stars gbe fun Water Corporation, ni ko fi nifẹ si bọọlu mọ.

"Ọmọ Yoruba ti mo ro pe o maa ran mi lọwọ lo jẹ ki iṣẹ Shell bọ lọwọ mi"

Seyi Makinde tun fi ọjọ ibi rẹ naa sọrọ nipa bi ọkunrin kan ṣe ja kulẹ lasiko to n ṣe agunbanirọ nipinlẹ Rivers.

O ṣalaye pe oun ṣakitiyan ki wọn le gbe oun sabẹ ọga kan to jẹ ọmọ Yoruba, ko ba le daabo bo oun nileeṣẹ Shell to ti n sinru ilu.

Amọ si iyalẹnu rẹ, nigba ti wọn yoo fi gba awọn agunbanirọ siṣẹ lẹyin ọdun kan, ninu awọn meje ti orukọ wọn jade gẹgẹ bii awọn to pegede, wọn fun awọn mẹfa niṣẹ yatọ si oun nikan ṣoṣo.

O ni “Mo wa lọ ṣe iwadii lati mọ eredi ti wọn ko ṣe fi orukọ mi si ara awọn ti wọn fun niṣẹ.

Wọn sọ fun mi pe ọmọ Yoruba yẹn gan ti mo lero pe yoo daabo mi lo ni ki wọn ma fun mi niṣẹ ọhun.”

“Ọjọ naa ni isẹ mi pin nileeṣẹ Shell, ti mo si yan ọna mii laayo.”

"Bi mo ṣe di amojuẹrọ ree"

Makinde sọ pe ipele ẹkọ ‘Form4’ ni oun ti gbegba oroke julọ, ti oun si mọ pe ‘Form 4A’ ni wọn yoo fi oun si, eyii tii ṣe kilaasi awọn akẹkọọ to n se isẹ sayẹnsi.

O ni “Igba naa ni mo ti bẹrẹ si n ronu oun ti mo maa da laye.”

“Mi o fẹran imọ ẹkọ Biology pupọ, amọ mo fẹran imọ ẹkọ iṣiro, Chemistry, Physics, ati Geography.

Nigba naa ni mo pinnu lati di awakọ ofurufu tabi amojuẹrọ.

Lẹyin ti gomina ọhun kọ idanwo aṣewọle JAMB tan, lo sọ fun baba rẹ pe imọ erọ ni oun yoo kọ nipa rẹ, bo tilẹ jẹ pe baba rẹ fẹran imọ nipa eto iṣegun.