Obìnrin kán gan mọ́ná ní ibùdó ìgbafẹ́ ọmọdé lọ́jọ́ kejì Kérésì, ìjọba Eko faraya

Aworan

Oríṣun àwòrán, Lagos State Government

Lọjọ Aje ni obinrin kan, tí a ko le sọ orúkọ rẹ padanu ẹmi rẹ lẹyin ti ina mọnamọna gbe ni ibudo igbafẹ awọn ọmọde kan, ti wọn pe ni Wonderland.

Agbegbe Apapa niluu Eko ni ibudo igbafẹ ọhun wa, ti isẹlẹ naa ti waye.

Iṣẹlẹ yii waye níbi ayẹyẹ ọdun keresimesi, tí wọn gbe kalẹ fun awọn eeyan lati gbafẹ niluu Eko.

Kete ti iṣẹlẹ naa waye ni awọn eeyan to wa nibẹ lasiko naa sare kuro ni agbegbe ọhun.

Ìjọba Eko kede pe ki wọn ti ibudo igbafẹ naa pa

Lẹyin iṣẹlẹ naa, ìjọba ìpinlẹ Eko ti palasẹ pe ki wọn ti ile igbefẹ ọmọde Wonderland paa, kí wọn da gbogbo karakata wọn duro lẹsẹkẹsẹ.

Ọga agba fun Ileeṣẹ to n mojuto isẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, Lanre Majola ni awọn gbe igbesẹ naa lati daabo bo awọn ọmọde lọjọ iwaju eyi to le pa wọn lara.

Majola wa koro oju si oludasilẹ ibudo igbafẹ naa, Ezekiel Adamu fun bo ṣe kuna lati tẹle ilana ti ajọ ọhun fi lelẹ.

O ni ọpọ igba ni awọn ti pe oludasilẹ ibudo igbafẹ naa wa si ipade pe ko ṣe ohun to tọ lati ri pe iru iṣẹlẹ bẹẹ ko waye.

Sugbọn wọn ni o kọ lati tẹle gbogbo imọran awọn.

Àkọlé fídíò, Quest University Ghana: Ìyá àti ọmọ bọ́ sọ́wọ́ gbájúẹ̀ fásitì torí ìyanṣẹ́lódì ASUU

Ṣé ẹ̀mí òkùnkùn ló ń fa ìjàmbá ọkọ̀ lópin ọdún bí? FRSC, NEMA sọ̀rọ̀

aworan

Ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri ni Naijiria (NEMA) pelu ajọṣepọ ikọ to risi igboke-gbodo ọkọ loju popona (FRSC) ati awọn oṣiṣẹ aabo miran ti sekilọ nipa ọdun sise.

Nilu Ibadan, olu-ilu ipinlẹ Ọyọ ni wọn ti ṣe ipolongo idaabo bo ẹmi laarin awọn awakọ ati ero wọn lọna ati dena ijamba ni akoko Keresimesi ati ọdun titun.

Nigba to n ba awon akọroyin sọrọ lasiko ti wọn n ifọrọwerọ pẹlu awọn awakọ ni opopona Ibadan si Eko, Saheed Akiode, ̀oludari ajọ NEMA ni ekun guusu iwọ oorun ran wọn leti nipa awọn ofin ati ilana rinrin loju awọn opopona.

O ni eto ọhun ni ajọ NEMA pe ni Operation Eagle Eye lati ri daju wi pe awọn awakọ kò sare aṣapajude lakoko ọdun yii.

Akiode ro awọn awakọ lati mase mu ọti tabi faa ohun elo oloro lakoko ti wọn wa mọto, kí wọn le baa lè doola ẹmi awọn ti wọn gbe rinrin ajo.

aworan

Akiode sọ pe, o ṣe pataki lati ṣe akiyesi ati ipolongo yii ni akoko ọdun nitori ọpọlọpọ awọn ẹniyan ni wọn maa n sọ nkan buruku nipa awọn oṣu to pari ọdun.

Ogbeni Adewale Latiff ọkan ninu awako to peju sibi eto naa rọ awọn akẹẹgbẹ rẹ lati mase lodi si awọn ofin to rọ mọ ọkọ wiwa ati awọn onikẹkẹ pẹlu ọlọkada lati mase sare ju lasiko yii.

O ni ẹmi ẹniyan ṣe pataki ju owo lọ, ti oun ati awọn akegbe oun yoo si sá ipaa wọn lati ri wi pe ijamba loju opopona dikun.