Ogun Police: Afurasí ọmọ Yahoo gba N26m owó jìbìtì, ó fáwọn akẹẹgbẹ́ rẹ̀ mẹ́ta ní N2m, ní wọn bá ji gbé

Ọlọ́pàá Ogun mú afurasí gbájúẹ̀ mẹ́rin tí jìbìtì N26m dá ìjà sílẹ̀ láàrin wọn

Afurasí ọmọ Yahoo gba N26m owó jìbìtì, ó fáwọn akẹẹgbẹ́ rẹ̀ mẹ́ta ní N2m, ní wọn bá ji gbé - Ọlọ́pàá Ogun

yahoo

Oríṣun àwòrán, Abimbola Oyeyemi

Ile iṣe ọlọpa ipinlẹ Ogun ti mu afurasi mẹrin kan fun ẹsun ijinigbe.

Awọn afurasi mẹrẹẹrin naa ni wọn fẹsun kan pe wọn n ṣe gbajuẹ lori ẹrọ ayelujara, ti ọpọlọpọ eniyan mọ si Yahoo.

Atẹjade kan ti agbẹnusọ ile-iṣẹ ọlọpa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi fi lede, lo sisọ loju ọrọ yii.

Ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun ni saaju ni awọn afurasi gbajuẹ yii ti ji ọkan lara wọn gbe nitori ko fun wọn ni ẹtọ wọn.

Isẹlẹ naa waye lẹyin ti ẹni wọn lu ni jibiti san owoti wọn beere fun wọn.

Awọn afurasi naa ni wọn tan Haruna Usman lọ si ile oniṣegun ibilẹ kan ni agbegbe orile Imo nijọba ibilẹ Obafemi Owode.

Abimbola ni awọn kan lọ ta ile iṣe ọlọpa Owode Ẹgba lolobo nipa isẹlẹ naa, ti wọn si ri awọn afurasi mẹrẹẹrin naa mu lẹyin ti meji ninu wọn fi papa bora.

"Afurasi gbajuẹ gba N26m owo jibiti amọ N2m lo fun awọn akẹẹgbẹ rẹ, ni wọn se ji gbe"

Atẹjade ọhun ni awọn afurasi naa ti fi ọna aitọ gba miliọnu mẹrindinlọgbọn lọwọ ẹnikan ti wọn lu ni jibiti.

Amọ Haruna, ti wọn jigbe, tii se ara awọn gbajuẹ ọhun, to gba owo naa lorukọ awọn akẹẹgbẹ rẹ lọwọ ẹni ti wọn lu ni jibiti naa, lo fun awọn ọrẹ rẹ ni millionu meji pere ninu owo naa.

Orukọ awọn afurasi naa ni Agbe Simeon, Messiah Nicky, Oladapo Dolapo ati Yetunde Shonola.

Komisana ọlọpa nipinlẹ Ogun, Lanre Bankole, ti ni ki ẹka to risi iwa ijinigbe ninu ileeṣẹ ọlọpa ṣe iwadii to tọ lori iṣẹlẹ naa.

Bankole fikun pe awọn afurasi naa yoo foju ba ile ẹjọ lẹyin ti iwadii ba pari lori awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Àkọlé fídíò, Florence Ajimobi: Ọkọ mi fẹ́ ká rántí òun bíi Bàbá ìpínlẹ̀ Oyo tuntun
Àhámọ́ ọlọ́pàá ni Adeyẹmi, ọmọ gbajúmọ̀ Ọba yóó ti ṣọdún Kérésìmesì
Adeyemi Babatunde

Oríṣun àwòrán, Ogun Police

Lasiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, ohun to daju ni pe ahamọ ọlọpaa ni gendekunrin, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn kan, Adeyẹmi Babatunde yoo ti ṣe ayẹyẹ ọdun Keresimesi to wọle de yii.

Eyi ko si ṣẹyin bo ṣe fi mọto pa baba agbalagba kan niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe Adeyẹmi, ọmọ ọkan lara awọn ọba to gbajumọ daadaa niluu Abẹokuta lo fi mọto rẹ pa baba agbalagba, ẹni ọdun mẹrindinlaadọta ti wọn n pe ni Ọbafunṣọ Ismail.

Gẹgẹ bi alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi to gbe iroyin naa si wa leti ṣe ṣalaye.

O ni ọjọ kẹjọ, oṣu kejila, ọdun ti a wa yii ni Adeyẹmi fi mọto kọlu mọto baba naa.

Oyeyẹmi ni bi Adeyẹmi ṣe fi mọto baba rẹ to jẹ jiipu Lexus to ni nọmba idanimọ ‘Olu of Oya’ kọlu mọto Ismail lati ẹyin, niyẹn ti sare bọ silẹ lati yẹ ẹ wo.

Wọn ni loju ẹsẹ ni Ismail ti sọ fun Adeyẹmi pe ko bọ silẹ, ko si wa a wo bo ṣe ba mọto oun jẹ, ṣugbọn ti wọn sọ pe ko daa lohun.

Kaka ki Adeyẹmi bọ silẹ lati bẹ baba naa, wọn sọ pe ṣe lo bẹrẹ sii ṣepe fun baba yii, to si tun fẹẹ maa salọ.

Eyi lo jẹ ki baba naa sare bọ sori mọto Adeyẹmi wi pe oun ko nii jẹ ko salọ.

Loju ẹsẹ ni wọn sọ pe Adeyẹmi ti bọ silẹ, to si n kilọ nla fun un pe bi ko ba fẹẹ fi ẹmi ara rẹ ṣofo danu, ko tete yaa kuro lori mọto oun, nitori pe ṣe loun yoo fi mọto naa tẹ ẹ pa.

Ere ni wọn l’awọn to wa nibẹ kọkọ pe e, afi bi Adeyẹmi ṣe wọnu mọto naa, to si fi agidi wa a debi wi pe baba naa jabọ kuro lori mọto ọhun.

Nibi ti wọn sọ pe baba naa ti n yira nilẹ, to si n du ara rẹ, la gbọ pe Adeyẹmi tun fi ẹyin mọto naa rin, to si gun un mọlẹ, titi tiyẹn fi gbabẹ ku.

Bo ṣe rii pe baba naa ti ku lo ba juba ehoro, ti ko si sẹni to mọ bo ṣe rin in, iyẹn ni nnkan bi aago mẹjọ alẹ ọjọ naa.

Lara awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn la gbọ pe wọn gba teṣan ọlọpaa lọ lati fi to wọn leti, ti a si gbọ pe wọn wa Adeyẹmi dele, ṣugbọn ti wọn ko rii.

Gbogbo akitiyan awọn ọlọpaa lati rii mu lo ja si pabo, ko to di pe awọn kan ta ileeṣẹ ọlọpaa lolobo, ti wọn si lọ gbe e nile baba rẹ to wa lagbegbe Idi-Aba niluu Abẹokuta.

Oyeyẹmi fidi rẹ mulẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa tun ti gba mọto to fi pa Ismail danu lọwọ ẹ.

Ni bayii, o fi ye wa pe ọga awọn, Lanre Bankọle ti paṣẹ pe ki ẹka ileeṣẹ wọn to n ri sọrọ ipaniyan ati iwadii ọdaran tẹsiwaju iwadii, ki wọn si rii pe wọn f’oju ẹ ba ile-ẹjọ lai fi akoko ṣofo.