Tinubu ko fún ẹnikẹ́ni ní rìbá, ìtọrẹ àánú ló ṣe – APC

Tinubu

Oríṣun àwòrán, Reno Omokri

Igbakeji agbẹnusọ ikọ ipolongo ibo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Hannatu Musawa ti sọ pe irọ ni iroyin to n lọ nigboro pe Bola Tinubu n n fun awọn eeyan ni riba ṣaaju eto idibo ọdun 2023.

Iroyin naa gbode lẹyin ti fidio ibi ti Tinubu ti fun ọkunrin kan lowo ti fa ori ayelujara ya.

Fidio naa lo mu ki ọpọ awọn araalu atawọn ọmọ ẹgbẹ alatako maa sọ pe Tinubu fun ọkunrin to wa ninu fidio naa ni riba.

Amọ ninu atẹjade kan lọjọru, Musawa, to sọ pe oun funra oun gan loun ya fidio naa sọ pe ọrọ ko ri bi ọpọ awọn araalu ṣe lero.

Oloju aanu ni Tinubu, o fẹrtan lati maa ṣe iranlọwọ

O ni itọrẹ aanu lasan ni Tibunu n ṣe fun ọkunrin ọhun to jẹ akanda ẹda, kii ṣe riba.

Musawa tun bu ẹnu atẹ lu ẹgbẹ alatako pe awọn ló n lo fidio naa lati fi da wahala silẹ laarin ilu nigba ti ọrọ ko ri bi wọn ṣe n sọ.

Atẹjade naa ni “Mo ti ri awọn ọrọ kobakungbe ti awọn eeyan n sọ nipa fidio ti mo fi lede lori ayelujara nibi ti ọga mi ti n ṣe itọrẹ aanu.”

“Ko yẹ ki n sọrọ kankan lori nnkan ti awọn eeyan n sọ amọ mo ni lati sọrọ nitori awọn araalu ti ko mọ ohun to n ṣẹlẹ.”

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

“Emi ni mo ya fidio naa ti mo si mọọmọ fi lede lati ṣafihan bi ọga mi Asiweaju Bola Ahmed Tinubu ṣe jẹ oloju aanu, amọ awọn eeyan yi ọrọ naa si nnkan mii.”

O pari ọrọ rẹ pe “Fidio ọhun to jẹ iṣẹju meji ṣafihan bi ọga mi ṣe jẹ oloju aanu to si maa n ṣe iranlọwọ fun awọn ti ko ni.”

Lẹyin naa lo rọ awọn ọmọ Naijiria lati maṣe maa tẹti si awọn gbọyisọyi to maa n sọ ohun ti oju wọn ko to.

O tun gbadura pe ki Ọlọrun bukun Naijiria, ko si jẹ ki Tinubu ati igbakeji rẹ ṣaṣeyọri ninu eto idibo ọdun to n bọ