Ademola Adeleke ṣe àbẹ̀wò sí Buhari, ó gbósùbà káre fun

Aworan

Oríṣun àwòrán, State House

Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ti kan sara si aarẹ Muhammadu Buhari fun bi o ṣe buwọlu ofin lori eto idibo ti ọdun 2022.

Adeleke sọ eleyi nigba to ṣe ipade akọkọ pọ pẹlu Aarẹ niluu Abuja.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, o ni, “ Lati igba eto idibo ni o ti wu mi lati wa yọju si Aarẹ, lati dupẹ lọwọ rẹ lori bi o ṣe buwọlu ofin eto idibo nitori mo jẹ anfani rẹ.

“Ofin naa fi aye silẹ fun eto idibo lati lọ lia si rogbodiyan, ti awọn ajọ agbaye si kan sara si orilẹede Naijiria lori igbesẹ naa.

“Mo wa nibi bayii loni lati dupẹ lọwọ Aarẹ, ti mo si gba ladura pe ki Ọlọrun duro ti wọn pẹlu igba diẹ ti saa wọn yoo fi pari.”

Adeleke tẹsiwaju pe oun yoo ba osisẹ agba fun aarẹ sọrọ lori bi ibaṣepọ ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ Osun yoo ṣ dan mọran.

Isiaka Adeleke, Oyinlola àti Aregbesola ló ya owó lórúkọ Osun- agbenuso Oyetola

Àkọlé fídíò, Adeleke ni Òṣìṣẹ́ Oyetola tó bá fẹ́ gba ẹ̀tọ́ rẹ̀, gbọdọ kọ́kọ́ da dúkìá ìjọba padà

Lori ọrọ gbese ipinlẹ Osun to ti n fa awuyewuye lati igba ti ajọ eleto idibo INEC ti kede pe Senato Adeleke Ademola lo jawe olubori ninu idibo gomina Osun naa ni.

BBC wa agbenuso fun gomina Oyetola ati gomina Adeleke kan ki a le fi oju aje kan oniṣo lati mọ ohun to n ṣẹlẹ gangan.

Ninu fọnran fidio oke yii ni onikaluku ti ni oore ọfẹ lati ṣalaye ohun to ṣẹlẹ lati iha koowa wọn.

Ki alaafia jọba ni ipinlẹ Osun lo jẹ BBC Yoruba logun ki awon ara ilu si jẹ anfani iṣejọba alagbada bo ti yẹ.

Awọn agbẹnusọ Oyetola ati Adeleke

Òṣìṣẹ́ Oyetola tó bá fẹ́ gba ẹ̀tọ́ rẹ̀, kó kọ́kọ́ da gbogbo ọkọ̀ àti dúkìá ìjọba padà– Adeleke

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Osun ti funpe sì gbogbo awọn tí wọn ṣiṣẹ́ lábẹ́ ijọba ana pe ki wọn da gbogbo ọkọ àti dukia to jẹ ti ijọba to ṣi wa ni ikawọ wọn padà ki wọn to le gba ẹtọ kankan.

Nínú atejade ti agbẹnusọ gomina Ademola Adeleke fi ṣọwọ si awọn akọroyin, Mallam Olawale Rasheed sọ pé àwọn to ba ijoba Adegboyega Oyetola ṣiṣẹ́ ko awọn ọkọ àtàwọn dúkìá mii fun ilo ti ara wọn èyí to ni o lodi si ofin ijọba Ìpínlẹ̀ náà.

Rasheed sọ ninu atẹjade naa pe “Awọn oṣiṣẹ yii ko kan kuro ni ọ́fíìsì pẹlu ọkọ iṣẹ ti wọn n lo nìkan, wọn tun ko ọkọ Ileeṣẹ gangan àtàwọn nnkan mii, eyii to si lodi si ofin.”

Osun CPS

Bo tilẹ̀ jẹ pe lara àwọn oṣiṣẹ gomina to lọ ti sọ pe, Oyetola lo fun awọn ni àṣẹ lati maa lo awọn ọkọ ọhun, agbenuso fun gomina Ademola Adeleke ni ko si ofin to faaye gba eyi fún gomina ana ko gbe igbesẹ naa.

O ni “Awọn ara ipínlẹ̀ Oṣun naa mọ nipa ikọlu ti wọn ṣe si ile ijọba to wa ni Osun ati eyi to wa ni Abuja ti wọn si ko ọpọlọpọ nnkan lọ."

Gboyega Oyetola fesi

CPS Osun

Ninu iforowanilenuwo pẹlu BBC Yoruba agbenuso gomina ana, Gboyega Oyetola, ìyẹn Ismail Omipidan, jẹ ko di mimọ pe irọ awọn ìjọba Adeleke pọ.

O ni ki awọn eeyan lọ wo gbogbo ibi ti ijọba PDP n fẹ̀sùn kan awọn si yii lati foju aje ko onisọ funra wọn torí o da oun loju pe ọga oun kii ṣe oni wahala eniyan.