CBN ṣe àtúnṣe sí gbèdéke iye owó tí aráàlú lè gbà láàrín ọ̀sẹ̀, àlàyé rèé

Oríṣun àwòrán, @chricedng
Banki apapọ Naijiria, CBN, ti ṣe atuyẹwo gbedeke iye owo ti awọn araalu le maa gba laarin ọsẹ kan ninu apo ifowopamọ wọn.
Bayii, awọn eeyan le gba ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira laarin lọsẹ kan, nigba ti awọn ileeṣẹ le gba miliọnu marun un naira lọsẹ kan.
CBN lo fi ikede naa lede ninu lẹta kan lọjọru.
Gẹgẹ bii ohun to sọ ninu lẹta ọhun, wọn gbe igbesẹ naa lẹyin ti awọn ti ọrọ kan da si gbedeke to fi le iye owo ti awọn eeyan le gba ṣaaju.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọsẹ meji sẹyin ni banki apapọ ọhun sọ pe awọn eeyan ko gbọdọ gba ju ẹgbẹrun lọna ogun naira ninu ẹrọ ATM ati POS lojumọ.
CBN tun sọ pe awọn ile ifowopamọ ko gbọdọ san ju ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira fun eeyan ati ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira fun awọn ileeṣẹ lọ laarin ọsẹ kan.
Amọ lẹyin aṣẹ ọhun ni ile igbimọ aṣofin paṣẹ fun CBN lati yi aṣẹ naa pada nitori gbedeke ti wọn sọ pe awọn araalu ati ileeṣẹ le gba ti kere ju.
Awọn aṣọfin fẹnuko bẹẹ lẹyin itakurọsọ kan ti wọn ṣe lọjọru.
Wọn ni aṣẹ CBN naa ko le ni le mulẹ lailai nitori irufẹ ipo ti eto ọrọ aje Naijiria wa.
Bẹẹ naa lawọn araalu kan, paapaa awọn to n ṣowo POS sọ pe ilana tuntun ọhun yoo mu ki awọn kogba wọle.
Wayi o, ọjọ kẹsan an, oṣu Kinni, ọdun 2023 ni ofin tuntun nipa iye owo ti awọn araalu atawọn ileeṣẹ le gba laarin ọsẹ naa yoo bẹrẹ si n ṣiṣẹ.
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Gómìnà CBN tún kọ̀ láti yọjú sílé aṣòfin lórí gbèdéke iyé tí èèyàn le gbà lákoto báǹkì lójúmọ́

Oríṣun àwòrán, Others
Gómìnà ilé ìfowópamọ́ àgbà Nàìjíríà, Godwin Emefiele kò tún yọjú sí ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin fún ìgbà kejì lẹ́yìn tí ilé ránṣẹ́ pè é.
Ní ọjọ́bọ̀ ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin ti kọ́kọ́ ní kí Emefiele yọjú sí ilé náà ṣùgbọ́n tó kọ̀ tí kò yọjú.
Ohun tí àwọn aṣòfin náà fi ránṣẹ́ sí Emefiele ni láti wá wí tẹnu rẹ̀ lórí ìlànà tuntun tí ilé ìfowópamọ́ náà gbé kalẹ̀ wí pé èèyàn kò ní lè máa gbà ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún náírà lọ ní akoto owó báǹkì rẹ̀ lójúmọ́.
Nínú àkọránṣẹ́ kan tí igbákejì gómìnà CBN, Edward Adamu fi ránṣẹ́ sí ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin ní gómìnà Emefiele wà lára awọn tó bá ààrẹ Buhari rin ìrìnàjò lọ sí orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ni kò ṣe lè yọjú sílé.
Igbákejì abẹnugan ilé aṣòfin, Ahmaed Wase tó ka ìwé àkọránṣẹ́ náà sáwọn ọmọ ilé létí ní abẹnugan ilé Femi Gbajabiamila ti sun yíyọjú Emefiele sí òní.
Ẹ̀wẹ̀, Emefiele kò tún yọjú lónìí.
Gbajabiamila ní àwọn fẹ́ mọ iṣẹ́ tí Emefiele ń ṣe tó fi ks láti jẹ́ ìpè àwọn.
Bákan náà ni olórí ọmọ ilé tó kéré jùlọ, Ndudi Elumelu ní gómìnà CBN mọ̀-ọ́n-mọ̀ láti má jẹ́ ìpè àwọn ni.
Ohun tí a mọ̀ nípa ìgbìyànjú DSS láti ti gómìnà CBN, Godwin Emefiele mọ́lé rèé

Oríṣun àwòrán, GODWIN EMEFIELE/TWITTER
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ Naijiria, DSS, gbiyanju lati fi ṣikun ofin mu gomina banki apapọ, CBN, Godwin Emefiele lọjọ Aje.
Igbesẹ yii lo n waye laye lẹyin ti ile ẹjọ giga kan l’Abuja kọ ẹbẹ DSS lati fi Emefiel si atimọle.
Ṣaaju ni DSS ti kọkọ fẹsun kan Emfiele pe n ṣeranwọ owo fun awọn agbesumọmi, eyii ti ile ẹjọ naa ti tẹti si, to si sọ pe ki DSS lọ wa awọn ẹri to dantọ wa lori ẹsun naa.
Bi ẹjọ naa ṣe bẹrẹ
Ọjọ keje, oṣu Kejila, ọdun 2022 yii ni ile ẹjọ gba iwe ipẹjọ ẹsun ti DSS fi kan Emefiele.
Ninu eyii ti DSS ti sọ pe awọn yoo fẹ lati gbe gomina CBN naa si atimọle fun iwadii ni kikun, amọ adajọ to n gbọ ẹsun ọhun, John Terhemba kọ ẹbẹ wọn.
Adajọ Terhemba sọ pe DSS ko pese ẹri to ni gbongbo lati kin ẹsun naa lẹyin, ati pe Aarẹ Muhammadu Buhari gbọdọ gbọ nipa ẹsun naa.
“Tori owo naira tuntun ni wọn ṣe n gbogun ti Emefiele”

Oríṣun àwòrán, BAYO OMOBORIOWO
Ọjọ Aje ọsẹ yii ni awọn ẹgbẹ ajafẹtọ ọmọniyan kan ṣe iwọde lodi si igbeṣe DSS.
Awọn eeyan naa, labẹ asia ẹgbẹ National Interest Defenders (CNID), sọ pe ṣe ni DSS mọọmọ fẹ koba Emefiele.
Lẹyin naa ni wọn ke si Aarẹ Muhammadu Buhari ko da si ọrọ ọhun.
Bẹẹ naa ni ọpọ eeyan gbagbọ pe gbogbo awuyewuye naa ko ṣẹyin owo naira tuntun ati eto idibo ọdun 2023.
Ẹwẹ, DSS ti fesi pe ọrọ ko ri bẹẹ rara.
Wọn ni ojuṣẹ awọn ni lati ṣe iwadii ohunkohun ti yoo ba ṣakoba fun eto abo orilẹ-ede Naijiria.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ajọ naa, Peter Afunanya fi lede, o ni ija awọn awọn ọmọ Naijiria lawọn n ja.
Emefiele gbọdọ yọju siwaju ile igbimọ aṣofin
Ẹwẹ, awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ati ile aṣojuṣofin ti ke si Emefiele lati yọju siwaju wọn.
Wọn ni ko wa ṣalaye lẹkunrẹrẹ nipa ofin tuntun to fi idiyele si iye owo ti eeyan le gba lojumọ ninu banki, to fi mọ ATM ati POS.
Ọpọ araalu lo ti n reti boya Emefiele yoo yọju si awọn aṣofin naa ti ohun ti yoo ba bọ lati ibẹ.












