Ilé ẹjọ́ ju àyédèrú LASTMA sẹ́wọ̀n oṣù mẹ́rin

Oríṣun àwòrán, LASTMA
Ilé ẹjọ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àyíká àti àwọn àkànṣe ẹ̀ṣẹ̀ tó wà ní agbègbè Bolade, Oshodi ní ìpínlẹ̀ Eko ti sọ David Oluchukwu sí ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́rin fẹ́sùn wí pé ó ń pe ara rẹ̀ ní òṣìṣẹ́ àjọ tó ń mójútó ìrìnnà ojú pópó ní ìpínlẹ̀ Eko, LASTMA.
Ẹ̀sùn wí pé ó jẹ́ ayédèrú LASTMA àti lílọ́ àwọn ọlọ́kọ̀ pàápàá àwọn ọlọ́kọ̀ èrò lọ́wọ́ gbà ni David Oluchukwu kojú.
Adarí ẹ̀ka tó ń rí sí líla àwọn ará ìlú lọ́yẹ̀ ní LASTMA, Taofiq Adebayo tó fi ìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun ní ẹ̀sùn méjì ni wọ́n kà sí Oluchukwu lọ́rùn.
Olùpẹjọ́, Agbaje Oladotun sọ wí pé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n kà sí Oluchukwu lọ́rùn lòdì sí ẹ̀ka 168 àti 78 òfin ìwà ọ̀daràn ìpínlẹ̀ Eko.
Adájọ́ Adesanya Ademola sọ Oluchukwu sẹ́wọ̀n oṣù mẹ́rin láì fun láàyè láti san owó ìtanràn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ lágbára ju ohun tí wọ́n le gba owó ìtanràn fún.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ náà, ọ̀gá àgbà LASTMA, Bolaji Oreagba sọ wí pé ìdájọ́ náà dùn ma àwọn nínú nítorí yóò jẹ́ àríkọ́gbọ́n fún àwọn mìíràn.
Oreagba ní àwọn mìíràn tí wọ́n bá ń gbèrò láti máa lọ àwọn ènìyàn lọ́wọ́ gbà ni wọn yóò fojú winá òfin tí ọwọ́ bá tẹ̀ wọ́n.
Ó ní ẹ̀ka ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ iléeṣẹ́ àwọn ní àwọn ti ṣe àtúnṣe sí láti tún ṣe àwárí àwọn tó ń bá ń da àláfíà ìlú láàmú bíi ti Oluchukwu láti fojú wọn winá òfin.
Bákan náà ló tún rọ àwọn awàkọ̀ láti máa tẹ̀lé ìlànà àti òfin ẹ̀ka ìrìnnà ojú pópó ní ìpínlẹ̀ Eko ti tọdún 2018.
Ẹ ó rántí pé a mú ìròyìn wá pé ní agbègbè Lekki ni ọwọ́ ti tẹ David Oluchukwu níbi tó ti ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí òsìṣẹ́ LASTMA.
Oluchukwu jẹ́wọ́ nígbà náà pé òun máa ń rí tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì náírà lójúmọ́ ní ẹnu iṣẹ́ náà.















