Ṣé lóòtọ́ ni gómìnà Adeleke dìgbájú lu òṣìṣẹ́ DSS, tí wọ́n fi kó gbogbo ẹ̀ṣọ́ aláàbò rẹ̀ kúrò?

Oríṣun àwòrán, other
Lati ọjọ diẹ sẹyin bayii ni ọrọ ti n ja ranyinranyin ni ipinlẹ Ọṣun pe awọn alaṣẹ ileeṣẹ agbofinro DSS ti ko gbogbo awọn oṣiṣẹ rẹ to n ṣọ gomina Ademọla Adeleke ti ipinlẹ Ọṣun kuro.
ọhun ti awọn kan n sọ pe o faa igbesẹ yii ni pe ọwọ ti gomina tuntun naa fi n mu awọn ẹṣọ alaabo rẹ ko dara rara.
Gbogbo awọn gomina lorilẹede Naijiria, labẹ ofin, lo lẹtọ si awọn ẹṣọ alaabo paapaa ti ọlọpaa ati DSS fun abo wọn ati ẹbi wọn. Idi gan niyi ti iroyin naa fi ṣe ọpọ ni haahin pe eeṣe ti wọn yoo fi ko awọn to n ṣọ gomina Adeleke kuro.
Awọn iroyin wo lo kọkọ jade?
Ẹgbẹ kan ti wọn pe orukọ wọn ni osun Shall Rise Again (OSRA) lo kọkọ kọwe atẹjade kan ista fawọn akọroyin lọjọ Aiku nibi ti wọn ti sọ pe Gomina Adeleke yoo fara han lolu ileeṣẹ DSS nilu Abuja lati wa wi ti ẹnu rẹ lori ẹsun ti wọn ni awọn ẹṣọ kan fi kan an pe o n hu iwa kotọ si wọn.
Ẹgbẹ naa ni “Ọrọ alufansa ti gomina Adeleke n sọ si awọn ẹṣọ alaabo rẹ lo mu ki ajọ agbofinro DSS o ko gbogbo awọn oṣiṣẹ rẹ kuro ni sakani rẹ.”
Ede aiyede laarin ọlọpaa ati DSS ni, abo to daju wa fun gomina Adeleke – ijọba ipinlẹ Ọṣun
Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti fesi lori ọrọ naa, eleyi ti wọn ni ija orogun laarin ileeṣẹ ọlọpaa ati ileeṣẹ agbofinro DSS lo fa iṣẹlẹ naa, kii ṣe iwa kankan latọdọ gomina Adeleke tabi mọlẹbi rẹ gẹgẹbi awọn eeyan kan ṣe n sọ ọ kiri.
Agbẹnusọ fun gomina Adeleke, Rasheed Ọlawale ṣalaye ninu atẹjade kan eyi to fi sita pe, “aigbọra ẹniye ranpẹ laarin awọn oṣiṣẹ agbofinro ọlọpaa ati DSS lo ṣokunfa rẹ.”
Atẹjade naa sọ pe wọn ti fi ọrọ ọhun to awọn olu ileeṣẹ awọn mejeeji leti fun asọyepọ to yanju.

Oríṣun àwòrán, other
Iroyin kan ti a tun gbọ nipe ohun to fa edeaiyede naa sọ pe, ni kete ti wọn yan Ademọla Adeleke si ipo ni ileeṣẹ agbofinro DSS ti yan oṣiṣẹ rẹ kan ranṣẹ gẹgẹ bi olori awọn ẹṣọ alaabo (CSO) fun un.
Ko pẹ pupọ lẹyin ọsẹ diẹ ni ileeṣẹ ọlọpaa pẹlu naa tun yan ọlọpaa kan ranṣẹ si ipo yii kan naa. Dẹrẹba meji ninu ọkọ kan naa yii lo fa edeaiyede to n fi ojojumọ waye laarin awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ agbofinro mejeeji.
Atẹjade naa ni abo to peye wa fun gomina Adeleke bayii.












