Akọ̀rọ̀yìn tó gbé ìròyìn yìí ṣì mí gbọ́ ní, Aregbesola kó tíì sọ̀rọ̀ lórí gbèsè Osun- Agbẹnusọ

Oríṣun àwòrán, others
Agbẹnusọ fun gomina ana nipinlẹ Osun, Rauf Aregbesola ni iroyin to lọ kiri pe ọga oun ti sọrọ lori ọrọ to n fa ede aiyede lọwọ laarin Gomina to sẹsẹ kogba wọle, Gboyega Oyetola ati Gomina tuntun, eyiun, Ademola Adeleke lori gbese owo nipinlẹ naa kii ṣe ohun ti oun sọ ni pato.
Sola Fasure, ninu atẹjade to fi lede lowurọ ọjọ Aiku, ni ko si nkan to jẹ mọ Minisita fun ọrọ abẹlẹ ti sọrọ lori ọrọ ati pe akọroyin to ba oun sọrọ si oun gbọ ni.
O ni oniruuru iroyin lo ti tẹ oun lẹti, to si ya oun lẹnu nitori pupọ ninu awọn ọrọ ti akọroyin naa ni oun sọ ni ko ki n ṣe ọrọ ti to oun rara
“Mo ti ka omiruuru iroyin ti wọn ni Ogbeni Rauf Aregbesola sọ lori itakun ọrọ to n lọ lọwọ lori bii ijọba ṣe yawo nilpinlẹ Osun
“Eyi ni lati sọ pe Minisita ko buwọlu atẹjade kankan lori ọrọ naa. Bakan an, ọrọ ti akọroyin kan gbe jade ni ko ki n ṣe ọrọ mi rara.
“Ogbeni lọwọ bayii gbajumọ isẹ rẹ gẹgẹ bii minisita, ti ko si fẹ ki ohun kohun tabuku si isẹ rẹ, ti ko si fẹ fi ẹnikẹni tabuku si orukọ rẹ.
“Ti Minisita ba ti sọrọ, a yoo kan si gbogbo ile isẹ irotin gẹgẹ bii a ṣe ma ṣe.”

Oríṣun àwòrán, Screenshot
A ti san gbèsè tí mo gbà padà – Aregbesola dá sí ọ̀rọ̀ gbèsè Osun
Gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Osun, Rauf Aregbesola ti dá sí gbogbo ìfańfà tó ń wáyé láàárín gómìnà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbésẹ̀ ní ìpínlẹ̀ náà Gboyega Oyetola àti gómìnà tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bọ́ sórí ipò, Ademola Adeleke.
Láti ìgbà tí wọ́n ti búra wọlé fún Adeleke gẹ́gẹ́ bí gómìnà ni onírúurú awuyewuye ti ń wáyé láàárín Oyetola àti Adeleke lórí gbèsè tí ìpínlẹ̀ náà jẹ kalẹ̀.
Adeleke ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbèsè ni Oyetola fi kalẹ̀ fún òun àmọ́ Oyetola ń tẹnumọ wí pé òun kò gba gbèsè kankan fún ọdún mẹ́rin tí òun lò nípò.
Lẹ́nu lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí tún ni Adeleke tún fẹ̀sùn kàn Oyetola wí pé ó gba gbèsè bílíọ̀nù méjìdínlógún náírà lẹ́yìn tó fìdí rẹmi níbi ètò ìdìbò tó wáyé lọ́jọ́ Kẹrìndínlógún oṣù Keje ọdún 2022.
Ṣùgbọ́n nígbà tó ń fèsì, Oyetola ní Adeleke kàn fẹ́ mọ̀-ọ́n-mọ̀ ba òun lórúkọ jẹ́ ni nítorí òun kò yá kọ́bọ̀ lọ́wọ́ ilé ìfowópamọ́ kankan fun gbogbo ìgbà tí òun lò nípò àti pé gbogbo gbèsè tó wà lọ́rùn ìpínlẹ̀ Osun jẹ́ èyí tí òun jogún lọ́wọ́ Aregbesola.
Ẹ má dà á tèmi si ìfaǹfà àárín Oyetola àti Adeleke - Aregbesola
Ní báyìí, Rauf Aregbesola ti wá dá si ọ̀rọ̀ náà.
Aregbesola ní olùṣírò àgbà fún ìpínlẹ̀ Osun ló ní gbogbo ìwé ẹ̀rí bí ìjọba kọ̀ọ̀kan ṣe gba owó lọ́wọ́ àti pé òun ló le sọ bí ọ̀rọ̀ gbèsè ìpínlẹ̀ náà ṣe jẹ́ gan.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ Aregbesola, Sola Fasure fi síta ní gbèsè méjì gbòógì tí òun gbà nígbà tí òun wà ní gómínà Osun ló ti jẹ́ sísan tán.
Ó ní àwọn yòókù jẹ́ èyí tí àwọn gbà lọ́wọ́ ìjọba àpapọ̀ àti pé ọdún pípẹ́ ni àwọn máa fi san owó náà padà fún ìjọba àpapọ̀.
Ó fi kun pé díẹ̀díẹ̀ ni ìjọba àpapọ̀ yóò máa yọ owó náà títí tí àwọn fi máa sán owó náà tán.
Fasure ní olùṣírò owó àgbà ní ìpínlẹ̀ Osun ló ní ìmọ̀ nípa gbogbo owó tó wà lápò ìjọba, gbogbo gbèsè tí ìjọba jẹ, ìgbà tí wọ́n gba gbèsè àti ibi tí wọ́n san gbèsè náà dé.
Ó ní nítorí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ mọ̀ bí ọ̀rọ̀ gbèsè ìpínlẹ̀ Osun ṣe jẹ́ kó kàn sí olùṣírò owó àgbà.
Bákan náà lọ rọ àwọn ènìyàn láti má dà á ti Aregbesola sí gbogbo awuyewuye tó ń lọ ní Osun nítorí àárín Adeleke àti Oyetola ni ọ̀rọ̀ náà wà.
Ó tẹ̀síwájú pé Oyetola ló dá gbogbo wàhálà tó ń wáyé sílẹ̀ nítorí pé kò gbé ìjọba kalẹ̀ lọ́nà tó tọ́.
Fasure ní tó bá jẹ́ wí pé Oyetola yan ìgbìmọ̀ tí yóò gbé ìjọba lé gómìnà tuntun lọ́wọ́, gbogbo àwọn nǹkan tó ń fa awuyewuye yìí ni wọ́n á ti yanjú tí yóò sì wà ní àkọ́ọ́lẹ̀.
Ó fi kún pé tí ìjọba tuntun bá fi lè gbé ọ̀rọ̀ náà lọ síwájú EFCC Oyetola máa ní ìṣoro tó pọ̀.
Irọ́ pọ̀! Ẹ mú ẹ̀rí wá pé mo yá owó nígbà tí mo wà nípò - Oyetola sí Adeleke

Oríṣun àwòrán, Other
Ẹ ó rántí pé a ti ṣaájú mú ìròyìn wá pé Gómìnà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kúrò nípò ní ìpínlẹ̀ Osun, Gboyega Oyetola ti tẹnumọ pé òun kò yá kọ́bọ̀ láti ṣe ìjọba nígbà tí òun wà nípò gẹ́gẹ́ bí gómìnà.
Agbẹnusọ Oyetola, Ismail Omipidan sọ nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta pé tí gómìnà tuntun tó wà lórí ipò bá ní ẹ̀rí tó dáwọn lójú pé Oyetola yá owó kankan kí wọ́n fi síta kí gbogbo ayé ri.
Omipidan ní gbogbo ìjọba Rauf Aregbesola ló jẹ gbèsè tó wà lọ́rùn ìpínlẹ̀ Osun àti pé ìbanilórúkọ jẹ́ lásán ni Adeleke ń ṣe fún Oyetola pẹ̀lú gbogbo ìròyìn irọ́ tí wọ́n ń gbé síta nípa rẹ̀.
Ó ní àìmọ̀kan gómìnà tuntun ló jẹ́ kó máa ní Oyetola gba gbèsè bílíọ̀nù méjìdínlógún náírà ní èyí tó jẹ́ wí pé kò rí bẹ́ẹ̀.
Ó wá pe gómìnà Ademola Adeleke nínà láti fi ọdún àti ìgbà tí ìjọba ìpínlẹ̀ Osun gba àwọn gbèsè náà síta fún gbogbo ènìyàn láti rí.
Omipidan tẹ̀síwájú pé ó dàbií wí pé àwọn tó kọ àkọ́lẹ̀ tí gómìnà Adeleke kò ṣe ìwádìí dáadáa ní àbí wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ kàn fẹ́ bá Oyetola ní orúkọ jẹ́.
Ó fi kun pé nígbà tí ọ̀gá òun ń gbé ìjọba kalẹ̀, òun tó kọ ni pé ìjọba àpapọ̀ ń fún àwọn bílíọ̀nù mẹ́ta ni oṣooṣù láti ṣàtìlẹyìn fún àwọn ìpínlẹ̀ káàkiri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà nítorí àdínkù tó bá àbá ìsúná.
Ó ní láti inú oṣù Kejìlá ọdún 2021 ni èyí sì ti bẹ̀rẹ̀ fún oṣù mẹ́fà gbáko àmọ́ bó ṣe wá di pé lẹ́yìn tí àwọn parí eto ìdìbò ni àwọn gba owó náà ni kò yé òun.
Omipidan tún tẹnumọ pé àwọn kò yá owó kankan ní báǹkì fún ọdún mẹ́rin tí àwọn lò nípò àti pé tó bá dá ìjọba tuntun lójú kó fi iye tí wọ́n bá nínú akoto ijoba Osun nígbà tí wọ́n gba ipò nínú oṣù kọkànlá síta fún gbogbo ayé.
Oyetola yá ₦18bn lẹ́yìn tó kùnà ìbò gómìnà, àpápọ̀ gbèsè tó fi sílẹ̀ jẹ́ ₦331bn - Adeleke

Oríṣun àwòrán, @TheNationNews
Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ti sọ pe gbese biliọnu mejidinlogun naira ni gomina ana, Gboyega Oyetola ya lẹyin to padanu ibo gomina ninu oṣu Keje, ọdun 2022 yii.
O fi kun pe nigba ti yoo fi di inu oṣu Kọkanla ọdun 2022, apapọ iye owo ti ipinlẹ naa jẹ ti le diẹ ni irinwo biliọnu naira.
Adeleke lo fi ọrọ naa lede nibi ipade kan pẹlu awọn lọbalọba, eyii to waye niluu Osogbo.
"Gbese ọna mẹjọ ni ijọba mi jogun lọwọ ijọba Oyetola, yatọ si gbese owo oṣu ati ifẹyinti"
Gẹgẹ bii ohun to sọ, gbese ọna mẹjọ ọtọtọtọ ni ijọba rẹ jogun lọwọ ijọba Oyetola, yatọ si awọn gbese owo oṣu ati owo ifẹyinti.
O ni akoko ti yoo gba ipinlẹ Osun lati san owo naa pada yoo to ọdun mejidinlọgbọn.
Adeleke ni “Ẹyin eeyan mi nipinlẹ Osun, apapọ iye gbese to wa nilẹ bayii jẹ ọọdunrun ati bilọnu mọkanlelọgbọn naira.”

Oríṣun àwòrán, @SimplyTEEWHY
"Ta ba sanwo osu kọkanla tan, korofo ni apo ipinlẹ Osun wa"
“Ti a ba fi biliọnu mẹrindinlọgọrin naira tii se gbese owo oṣu ati owo ifẹyinti kun, apapọ gbese naa yoo jẹ irinwo biliọnu ati biliọnu meje naira, bẹẹ ni a ko mọ iye owo ti a jẹ awọn agbaṣẹse.”
“Iye to ku si apo iṣuna ijọba bayii jẹ owo oṣu oṣiṣẹ fun oṣu Kọkanla ọdun yii nikan, lẹyin naa, korofo ni apo iṣuna ijọba wa.”
Adeleke ni o jẹ ohun iyalẹnu fun oun pe ijọba ana nipinlẹ Osun ya owo ti iye rẹ le ni ọọdunrun bilọnu naira lai sí ohun kan pato ti ijọba ọhun fi owo naa ṣe.
"Oyetola gbọdọ ṣalaye ohun to fi owo to ya lẹyin eto idibo ṣe"
Adeleke fi kun o ṣe pataki ti gomina ana, Gboyega Oyetola wa ṣalaye awọn ohun to fi owo to ya lorukọ ipinlẹ Osun ṣe.
O ni “Gomina Oyetola gbọdọ ṣalaye bo ṣe na ₦331b lorukọ ipinlẹ Osun ti a ko si fi oju ri nnkankan ti wọn fi owo naa ṣe.”
“O tun gbọdọ ṣalaye nipa biliọnu mejidinlogun naira owo to ya lẹyin to lulẹ ninu eto idibo saa keji rẹ to waye ninu oṣu Keje.”
“Gomina Oyetola gbọdọ ṣalaye eredi ti ijọba Osun ṣe jẹ gbese owo oṣu ti iye rẹ to ₦76b lẹyin ti ijọba apapọ ṣeto iranwọ ₦50b owo oṣu fun awọn ijọba ipinlẹ.”
Adeleke pari ọrọ rẹ pe awọn ile ifowopamọ ti ọrọ naa kan gbọdọ ṣalaye eredi ti wọn fi ya ijọba Oyetola lowo nigba ti wọn mọ pe saa ijọba rẹ ti pari.














