Ìlànà lórí owó tí ènìyàn le gbà jáde ní báńkì kò le ṣàkóbá fún àwọn oníṣẹ́ POS - CBN

Owo naira tuntun ati PoS

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, CBN ti kéde pé ìlànà tuntun tí àwọn gbé kalẹ̀ lórí iye tí ènìyàn le gbà lákoto àsùwọ̀n owó rẹ̀ lójúmọ́ àti lọ́sẹ̀ kì í ṣe láti fi ba ọjà àwọn tó ń òwò POS jẹ́.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé CBN ti ṣaájú kéde lọ́jọ́ kẹfà oṣù Kejìlá ọdún yìí wí pé owó tí ènìyàn le gbà jáde ní ilé ìfowópamọ́ lójúmọ́ kò le ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún náírà fún ọlọ́dọni àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta náírà fún ilé iṣẹ́, CBN ní ààyè ṣì wà láti mú àlékún bá owó náà di mílíọ̀nù márùn-ún fún ọlọ́dọni àti mílíọ̀nù mẹ́wàá fún ilé iṣẹ́.

Wọ́n ní gbígba àlékún yìí le wáyé fún ìdí tó bá ṣe pàtàkì.

Adarí ẹ̀ka tó ń mójútó iṣẹ́ báńkì ní CBN, Mustafa Haruna nígbà tó ń kópa níbi ètò ilé iṣẹ́ Channels ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kejìdínlógún oṣù Kejìlá ọdún 2022 ní àwọn tó ń fi PoS ṣiṣẹ́ kò ní ní ìṣòro pẹ̀lú ìlànà tuntun yìí.

Haruna ní èló ni àwọn tó ń ṣiṣẹ́ PoS nílò ní ojúmọ́ ti wọ́n kò ní rí gbà ní ilé ìfowópamọ́ tí wọ́n bá ti ṣàlàyé irú iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe fún àwọn ilé ìfowópamọ́ bẹ́ẹ̀.

Ó ní ipa tí àwọn oníṣẹ́ POS ń kó nínú ọrọ̀ ajé Nàìjíríà nítorí náà àwọn kò ní gbèrò láti ba ọjà wọn jẹ́.

Ó fi kun pé kò fẹ́ẹ̀ sí agbègbè kan ní orílẹ̀ èdè yìí tí ènìyàn kò ti ní bá àwọn tó ń ṣe PoS pàdé.

“Ohun tó jẹ CBN lógún ni bí owó tó yẹ kó wà ní báńkì ṣe pọ̀ láàárín àwọn ènìyàn ní CBN ń wá láti dá àwọn owó náà sínú akoto báńkì tó yẹ kí wọ́n wà.”

Ìgbésẹ̀ tí yóò so èsò rere fún àwọn ọmọ Nàìjíríà ni ìlànà tuntun yìí

Haruna tẹ̀síwájú pé ó yẹ kí àwọn ọmọ Nàìjíríà rí ìlànà tuntun yìí gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tó dára láti mú ìdàgbàsókè àti ìgbà ọ̀tun bá ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà.

Ó fi kun pé tí àwọn ènìyàn bá padà mọ àwọn àǹfàní tọ sodo sínú àwọn ìlànà tuntun yìí, inú wọn yóò dùn sí ìgbásẹ̀ tí ìjọba ń gbé.

Bákan náà ló ní kì í ṣe ohun ìyàlẹ́nu wí pé àwọn ènìyàn ń sọ onírúurú ohun nípa ìgbésẹ̀, ó ní bí awuyewuye ṣe máa ń wáyé rè é tí ìjọba bá gùnlé ìlànà tàbí ètò tuntun.

Haruna ṣàlàyé pé ìdí nìyí ti àwọn fi ń ṣe ìpolongo àti ìlanilọ́yẹ̀ fún àwọn ènìyàn láti mọ àǹfàní àti àwọn nǹkan tí ìgbésẹ̀ tuntun yìí kó sínú.