Olaiya Igwe yóò yọjú síwájú ìgbìmọ̀ TAMPAN nítorí fídíò ìhòhò tó ṣe fún Tinubu

Mr Latin/Olaiya Igwe

Oríṣun àwòrán, Mr Latin/Olaiya Igwe

Ẹgbẹ awọn oṣere tiata Yoruba, TAMPAN, ti sọ pe awọn yoo bẹrẹ iwadii lori ẹsun aṣemaṣe ti wọn fi kan ọkan lara awọn agba ẹgbẹ ọhun, Olaiya Igwe ti yoo si jẹ iya to tọ labẹ ofin ẹgbẹ to ba jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

Aarẹ TAMPAN, Otunba Bolaji Amusan, ti ọpọ eeyan mọ si Mr Latin lo sọ bẹẹ nibi ipade ẹgbẹ naa to waye lẹnu lọọlọ yii lẹyin ti wọn yan awọn adari ẹgbẹ tuntun.

Ipade naa lo n waye lẹyin ti wọn yan Mr Latin gẹgẹ bii Aarẹ ẹgbẹ naa fun saa ọdun mẹrin mii.

Olaiya Igwe hu iwa to lodi si ohun ti ẹgbẹ duro fun

Lara awọn ọrọ to jẹyọ nibi ipade naa ni fidio kan ti ọkan lara awọn agba ẹgbẹ naa, Ebun Oloyede ti ọpọ mọ si Olaiya Igwe gbe jade, nibi to ti bọ ara rẹ si ihoho ọmọuabi leti okun lati ṣadura fun Bola Tinubu ko le wọle gẹgẹ bii Aarẹ Naijiria ninu eto idibo ọdun 2023.

Ẹgbẹ naa fẹsun kan Olaiya pe o hu iwa to lodi si ohun ti ẹgbẹ naa duro fun ati eyii to le doju ti ẹgbẹ pẹlu bo ṣe bọ ara rẹ si ihoho ọmọluabi.

Nigba to n sọrọ, Aarẹ ẹgbẹ ọhun, Mr Latin sọ pe TAMPAN gẹgẹ bii ẹgbẹ ko le maa fi ara rẹ yi ẹrẹ nitori oloṣelu kankan tabi ọrọ oṣelu.

Mr Latin ni ti TAMPAN ba kọ lati gbe igbesẹ lori ohun ti Olaiya Igwe ṣe, awọn ọmọ ẹgbẹ mii le maa da irufẹ iwa bẹẹ laṣa lọjọ iwaju.

O ni bo tilẹ jẹ pe gbogbo ọmọ ẹgbẹ lo lẹtọ labẹ ofin lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu to ba wu wọn, wọn ko gbọdọ maa ṣe ohun ti yoo tabuku orukọ ẹgbẹ ọhun.

A o fọ ẹgbẹ TAMPAN mọ

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

O fi kun un pe awọn oṣere tiata gbọdọ nii lọkan pe gbogbo oju lo n wo awọn, wọn ko si gbọdọ maa ṣe ohun ti ko tọna.

Lẹyin naa lo ni awọn gbọdọ fọ ẹgbẹ ọhun mọ, awọn ọmọ ẹgbẹ ko si gbọdọ tọwọ bọ ohun to lodi si ofin ẹgbẹ.

Mr Latin pari ọrọ rẹ pe Olaiya Igwe yoo yọju siwaju igbimọ oluwadii TAMPAN lori ohun to ṣe, yoo si foju wina ofin ẹgbẹ naa to ba jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

O ni eyii yoo jẹ ẹkọ fun awọn ọmọ ẹgbẹ mii to ba fẹ ṣe irufẹ nkan ti Olaiya ṣe.