Àwọn afurasí adigunjalè kun àwọn ènìyàn lọ́rùn, jà wọ́n lólè, fipá bá wọn lòpọ̀

Oríṣun àwòrán, Ondo Amotekun
Awọn afunrasi adigunjale ti wọn maa n fi afẹfẹ kun eeyan lorun ki wọn to ja a lole lọwọ awọn ikọ amọtẹkun ti tẹ nilu Akure to jẹ olu ilu ipinlẹ Ondo.
Awọn afunrasi ọhun ni adari ikọ amọtẹkun ni ipinlẹ Ondo, Akọgun Adetunji Adeleye, o fi oju wọn lede pe wọn wa lara awọn afunrasi mejilelọgbọn ti wọn fi panpẹ ofin mu un fun oniruuru ẹsun to fi mọ igbiyanju lati jini gbe, ifipabanilopọ, igbiyanju lati gbẹmi eeyan, rira ẹru ole ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Adetunji ṣee lalaye pe awọn afunrasi naa ni wọn maa n rapala wọ ayika awọn ti wọn fẹẹ ja lole ti wọn yoo si fẹ afẹfẹ to n kun eyan lorun naa sinu ile wọn lati oju ferese.
O wipe “lẹyin ti wọn ba fẹ atẹgun naa sinu ile ti wọn ti fẹ jale pẹlu, wọn a lọ fara pamọ sibi kan ti awọn ara ile naa yoo ti sun fọnfọn lẹyin eyi ni wọn yoo fọ ferese wọle ti wọn yoo si ko gbogbo ẹru ti wọn ba fẹ ninu ile naa”.
Adari ikọ amọtẹkun naa tẹsiwaju pe “lakoko ti wọn ba n ṣe iṣẹ laabi ọun, ko si ẹnikẹni ti yoo taji ninu ile naa nitori iṣẹ ti afẹfẹ naa ti ṣe lagọ ara wọn leyi ti yoo mu ki wọn sun asunpiye fun ọpọ wakati”.
“Nigba miran, wọn a ba awọn obirin to ba wa ninu ile naa ni aṣepọ to si di igba ti wọn ba taji ki wọn to mọ ohun to ṣe wọn. Nigba miran, ti afẹfẹ buruku naa ba pọju ninu ile ti wọn fun si, awọn miran ko nii ji fun ọpọ wakati abi ọpọ ọjọ.”
Adetunji ni “ọpọ olugbe ilu Akure lawọn adigunjale ti lo iru afẹfẹ yi lati ja lole, paapaa julọ awọn ti wọn mọ fẹnsi yi ile wọn ka ti ko nii sẹni to mọ oun to n ṣẹlẹ ninu ile naa”.
Bakan naa ni adari amọtẹkun wipe wọn fi ṣikun ofin mu awọn marun kan ti wọn ji awọn ọdọmọbirin mẹta ko nilu Akure pẹlu ibọn lagbegbe Post Office amọ ti awọn ẹṣọ amọtẹkun tọ ipasẹ wọn de ilu Iwo nipinlẹ Osun nibi ti wọn ti riwọn mu ti wọn si doola ẹmi awọn ti wọn jigbe lọ.
Adetunji to tun jẹ olugbaninimọran pataki fun gomina Akeredolu wa fi da awọn olugbe ipinlẹ loju pe gbogbo ipa ni awọn yoo sa, pẹlu atilẹyin awọn ẹṣọ alaabo to ku nipinlẹ naa lati ri pe awọn olugbe ibẹ ṣe odun keresi ati ọdun tuntun ninu ifọkanbalẹ lai si idiwọ latọdọ awọn amookunṣika.















