Ohun tó pa Yemi Adegunju, òṣèré tíátà tó jáde láyé rèé

Oloogbe Yemi Adegunju

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Yemi Adegunju ṣe àìsàn fún oṣù méjì, kó tó jáde láyé - Owolabi Ajasa

Igi ti da, Erin wo, Ajanaku ti sun bii oke, ọfọ nla si tun ti sẹ ni agbo awọn osere tiata Yoruba, eyi to mu ọmọ ẹgbẹ gbajumọ osere tiata miran lọ.

Orukọ oloogbe gbajumọ osere tiata naa ni Aarẹ Yemi Adegunju, ẹni to kọkọ se sinima agbelewo to jẹ kikida awọn obinrin nikan, to pe akọle rẹ ni "Lágídígba".

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ BBC Yoruba lọwọ, Adegunju jade laye lasiko aisan kan to ba afinra, eyi ti ko ju osu meji pere lọ.

Ologbe Yemi Adegunju ni wọn ti sin sile rẹ to wa nilu Ibadan l'Ọjọru.

Ọjọ Isẹgun, ọjọ kẹtala osu Kejila ọdun 2022 ni Yemi Adegunju jade laye, ti ọpọ awọn osere tiata lede Yoruba si ti n se idaro rẹ, paapaa lawọn oju opo ayelujara wọn.

Loju opo Instagram rẹ, gbajugbaja osere tiata kan, Odunlade Adekola lo kọkọ kede oku oloogbe naa, to si ni ko sun re.

Bakan na ni osere tiata miran, Bose Aregbesola naa kọrin re ki Oloogbe Yemi Adegunju pe ẹni ire lọ loju opo Instagram rẹ.

Ọrọ idaro Odun Adekola nipa iku emi Adegunju

Oríṣun àwòrán, odunomoadekola/Instagram

Bawo ni Yemi Adegunju ṣe ku?

Owolabi Ajasa, tii se gbajumọ osere tiata mii ba akọroyin BBC Yoruba sọrọ nipa iku Yemi Adegunju.

Ninu ọrọ rẹ, Owolabi Ajasa ni Yemi Adegunju ti wa lori idubulẹ aisan fun bii oṣu meji si mẹta, ko to di pe ọlọjọ de.

O ni ere sinema tuntun kan ni Ologbe naa n dari lọwọ, ko to di pe ọlọjọ de.

Bakan naa lo kẹdun iku Yemi Adegunju, to si ṣalaye pe ọpọ ere sinema agbelewo to ti kọ silẹ ni ko tii fi ṣe ere tiata.

Ajasa ni bo tilẹ jẹ wipe Yemi Adeyanju gbe ọpọ sinima agbelewo sita, amọ awọn ti wọn maa n ṣe ẹda sinima lati ta sita, lo n ko ọpọlọpọ ere to yẹ ki awọn oṣere rí.

Gbajumọ osere tiata naa wa rawọ ẹbẹ si ijọba lati ṣe iranlọwọ fun awọn oṣere tiata lati ri ẹyin awọn ti kii jẹ ki osere jere nidi isẹ afooju ogun wọn ṣe naa.

Ọrọ idaro Bose Aregbesola lori iku Yemi Adegunju

Oríṣun àwòrán, officialbosearegbesola/Instagram

Yemi Adegunju lo gbe sinima ti mo kọkọ kopa ninu rẹ jade - Bose Akinola

Bakan naa, Bose Akinola, tii se gomina ẹgbẹ awọn oṣere tiata lede Yoruba nipinlẹ Oyo, TAMPAN sọrọ lori iku Yemi Adegunju.

Bi o tilẹ jẹ pe ilu Abeokuta ni Adegunju tẹdo si lati maa sisẹ tiata amọ ọmọ bibi ipinlẹ Oyo nii se.

Akinola ni iku Yemi Adegunju ya oun lẹnu nitori sinima akọkọ ti oun yoo kopa ninu rẹ, iyẹn Lagidigba, ologbe Yemi Adegunju lo gbe e jade.

"Ere agbelewo tuntun ti Yemi Adegunju n ṣe lọwọ nibiti mo ti kopa gẹgẹ bi Olori Ọba, ko ti jade fun wiwo.

N ko mọ pe ere ikẹyin ti maa ba wọn kopa kẹyin niyẹn. "

Gomina ẹgbẹ TAMPAN nipinlẹ Oyo naa wa rawọ ẹbẹ si ijọba lati ṣeto owo fun awọn oṣere, kí wọn le ri owo ṣe sinima sita, eyi ti yoo mu owo wọle fun wọn lati tọju ara wọn ti aisan ba de.

Yemi Adegunju

Oríṣun àwòrán, Collage

Ta ni Yemi Adegunju to jade laye?

Odu ni Yemi Adegunju ni agbo awọn osere tiata Yoruba, ti kii si ṣe aimọ fun oloko, paapaa lọdọ awọn ọmọ kaarọ oojire.

Ọmọ bibi ipinlẹ Oyo ni Yemi Adegunju, ko to lọ tẹdo silu Abeokuta lati maa bawọn kopa ninu ere tiata.

Yatọ si pe Yemi Adegunju jẹ osere tiata, o tun jẹ olootu sinima, adari ere, Akewi ati oludari sinima.

Diẹ ninu awọn sinima ti Yemi Adegunju ti gbe sita ni Lagidigba (ILU-BIRIN), Arole Olodumare, Posi Alaaye, Lalaalu, Aye ku sibikan, Olowo kan otoṣi mẹfa ati awọn sinima miiran.

Lara awọn akẹgbẹ oloogbe naa la ti ri Jide Kosoko, Adebayo Salami, Madam Saje, Mr Latin ati bẹẹ bẹẹ lọ.