Wọ́n sanwó fún mi láti jẹ́ kí Portable lù mí ní - Kelvin Power

Aworan Kelvin Power

Oríṣun àwòrán, Instagram/Kelvin Power

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbajugbaju aṣoni, Kelvin Power ti ni ipolowo ọja ni oun ati gbajumọ olorin, Habeeb Okikiola, ẹni ti ọpọ mọ si Portable gunle lasiko ti awọn jọ wọ iya ija lọdun 2024.

Power ni awọn to gbe iṣẹ fun oun lo fun oun lowo pe ki Portable la oun mọlẹ ko ki n ṣe pe Portable kaju oṣuwọn lati ni pe o fẹ doju ija kọ oun.

Pẹlu ẹrin ni Power fi ṣalaye eyi lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ lori irinajo igbesi aye ati awọn ohun to lakọja ko to de ibi to wa lonii.

Ọdun 2024 ni Portable ati Kelvin Power wọ iya ni paapa iṣere abẹsẹkubioju to wa nipinlẹ Eko.

"Awọn eeyan ni Portable na, ẹni to jẹ pe nigba to ri pe emi lo fẹ ba jẹ, o kọ jalẹ pe ki n lọ ba Anthony Joshua ja dipo oun.

"Mọ mọmọ dibọ pe mo ṣubu lasiko ti Portable gba mi. Wọn jọ san owo fun awa mejeeji ni."

Yoruba bọ̀, wọn ni, ẹni ija o ba lo n pe ara rẹ ni ọkunrin.

Kelvin Power ni kan kọ ni Portable ti ba ja, lọdun 2023, Portable, ati oṣerekunrin, Charles Okocha, jọ fija pẹẹta ni ọjọru, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kejila ọdun 2023, nigba ti wọn fi ẹṣẹ kikan wọya ija

Ija naa to waye ni eti okun Landmark, ni agbegbe Victoria Island nipinlẹ Eko, ni iroyin sọ pe o bẹrẹ ni nnkan bi aago kan oru.

Bi ogoji iṣẹju si ni wọn fi ja.