Mi ò sọ pé àwọn ọmọ Bàbá Rasaq Okoya kékeré ni yóò jogún rẹ̀, ohun tí mo sọ rèé - Shina Peller

Oríṣun àwòrán, Shina Peller/Instagram
Ggbajugbaja oniṣowo ati oloṣelu n ni, Shina Peller, ti ke gbajare wi pe iroyin ofege ni iroyin kan to sọ pe oun sọ pe awọn ọmọ kekeke Baba Rasaq Okoya ni yoo pin ogun rẹ fun un.
Ninu fidio kan ti o fi lede loju opo Instagram rẹ ni Peller ti yanana ọrọ naa wi pe irọ nla to jinna si oootọ ni ọrọ naa.
Ọgbẹni Peller sọ ninu fidio naa wi pe ko si nnkan to jọ bẹẹ rara lati ọdọ oun.
''Mi o sọ nnkan to jọ bẹẹ rara, irọ nla ni, baba Okoya kii kan ṣe agbaọjẹ oniṣowo lasan an.
Bii baba ni wọn Okoya jẹ si mi, ati pe ọmọ Yoruba gidi ni mi to mọ itumọ Ọmọluabi.
Nilẹ Yoruba, ọmọde kii tabuku agbalagba tabi ẹnikẹni to ba ti ju eeyan lọ.
Ile ire ni mo ti jade, mo si jẹ ọmọ to gba ẹkọ lati ile wa,'' Peller lo sọ bẹẹ.
Ilumọọka oloṣelu naa sọ pe nnkan toun sọ da lori iṣọkan ẹbi.
O ni nnkan toun sọ ni pe ''ko dara to lati maa fi ọmọ we ọmọ.
Gẹgẹ bii baba ati adari, eyi ṣe pataki ki ọta ma ba wa laarin awọn ọmọ.''
Peller ni Baba Okoya lo ṣiṣẹ lati ko dukia rẹ jọ funra rẹ, nitori naa, oun ko lẹtọọ lati sọ fun un bi yoo ṣe pin ogun rẹ.
O ni oun kọ loun maa sọ fun baba nipa awọn ọmọ ti ogun rẹ tọ si.
Gbajugbaja oniṣowo naa ko ṣai sọ fawọn akọroyin to n gbe iru iroyin bayii kaakiri wi pe ki wọn maa ṣe iwadii daadaa ki wọn to gbe iroyin wọn jade.
Peller ni ko si ibi ti oun ti sọrọ ninu iroyin ti ẹnikan gbe jade naa, eyi to tumọ si pe irọ ni gbogbo rẹ.
''Mo fẹ ki gbogbo ẹyin ti ẹ maa n gbe iru iroyin bayii maa beere lọwọ ara yin idi ti ẹ fi n kọ iru iroyin bẹẹ.
Ṣe ẹ n kọ iroyin yii lati le jẹ ki ọpọ eeyan maa tẹle yin loju opo ayelujara ni, abi lati ba orukọ awọn eeyan kan jẹ?''
Peller wa dupẹ lọwọ gbogbo awọn ololufẹ rẹ ti wọn ti gba ẹri oun jẹ wi pe oun ko le sọ iru nnkan bayii laelae.
O ni alaafia loun maa n lepa ni gbogbo igba, oun kii si nidi madaru.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post



























