Wo nǹkan mẹ́wàá yàtọ̀ sí oúnjẹ àti omi tó tó lè já ààwẹ̀ rẹ lásìkò Ramadan

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọpọ nnkan ni eeyan, paapa awọn musulumi, o mọ pe o n ja awẹ wọn, ti wọn si tẹsiwaju lati ma kopa ninu awọn nnkan wọnyi.
Ọrọ nipa nnkan to le ja awẹ yatọ si ounjẹ ati omi lo n ja kiri lori ayelujara, eyi lo mi ki BBC tọ awọn omimọ lọ lati tan imọlẹ si ọrọ naa.
BBC kan si Sheikh Aminu Ibrahim Aminu Daurawa lati sọrọ nipa nnkan to le ja awẹ.
Sheikh Daurawa ni nnkan ti a n pe ni awẹ ni pe ki eeyan yago fun awọn nnkan bii ounjẹ, omi, ibalopọ ati awọn nnkan to le ja awẹ lati sarri lọ si aṣiko iṣinu.
Onimọ yii ṣe akọsilẹ nnkan to le jawẹ
- Mimọmọ jẹ ounjẹ
- Mimọmọ mu omi
- Eebi
- Nnkan oṣu obinrin
- Aniyan lati ma gba awẹ
- Ki atọ ma jade lara
Onimọ ṣorọ nipa nnkan to le fa ki ọkunrin tabi obinrin ma tọ atọ lasiko aawẹ, eyi to le ba awẹ wọn jẹ.
- Fifi ẹnu ko eeyan lẹnu
- Didimọ eeyan paapa obinrin
- Ero ọkan.
Sheikh ni to ba jẹ awọn idi lo fa ki atọ fi jade lara eeyan, o tumọ si pe awẹ ti bajẹ.
Yiyago fun ounjẹ ati omi mimu to fi mọ ṣiṣọ gbolohun to ba n jade lẹnu alaawẹ jẹ ọna kan gbogi ti alawẹ gbọdọ mojuto.
Irọ pipa, isọkusọ, sisọ ọrọ karimi wa lara awọn ọna ti alaawẹ le fi padanu oore to wa ninu awẹ gbigba.
Lati le dena eleyi, awọn onimọ ẹsin ni ki awọn musulumi sọ ọrọ ẹnu wọn ati iwa wọn.
Awọ nkan marun un toyẹ ki alaawẹ yago fun:
- Ibalopọ lọsan aawẹ
- Jijẹun ju lasiko iṣinu tabi ni asiko saari
- Lilọra lati sinu ti asiko ba to
- Sisọrọ eeyan lẹyin lasiko aawẹ maa n din laada ku
- Ṣiṣe iwa ṣekarimi pẹlu aawẹ tabi iṣẹ oloore mii ta ba ṣe ninu oṣu Ramadan



























