Wo àkóbá tó wà nínú àgbàdo, ẹ̀wà àti ata tí a lọ̀ ní ẹ̀rọ ìlọta fún ẹ̀dọ̀ àti kíndìnrín rẹ

Àkọlé fídíò, Wo àkóbá tó wà nínú àgbàdo, ẹ̀wà àti ata tí a lọ̀ ní ẹ̀rọ ìlọta fún ẹ̀dọ̀ àti kíndìnrín rẹ
Wo àkóbá tó wà nínú àgbàdo, ẹ̀wà àti ata tí a lọ̀ ní ẹ̀rọ ìlọta fún ẹ̀dọ̀ àti kíndìnrín rẹ

Njẹ o mọ pe akoba wa ti o ṣeeṣe ki ata, ẹwa, tabi agbado ti a lọ ninu agbelẹrọ ẹrọ ata le ṣe akoba fun ẹdọ ati kindinrin rẹ.

Ileeṣẹ ijọba apapọ to n ṣiṣẹ iwadii (FIIRO) gbe iṣẹ iwadii kan sita pe o ṣeeṣe ki ounjẹ ti a fi ẹrọ ata ti ko mọ to lọ le ṣokunfa ki ẹdọforo, kindinrin atawọn ẹya ara miran kọṣẹ silẹ.

Ọmọwe Jumai Adamu to jẹ adari FIRI lo sọ eyi di mimọ.

Iwadii fidi rẹ mulẹ pe awọn ẹrọ ilọ̀gi ati ilọta alagbelẹrọ a maa dogun lọpọ igba paapaa lẹyin ọpọ igba ti wọn ti n lo wọn.