Ọmọ mi méjì, ọmọ ìyáálé mi kan ni Amọtẹkun pa ni Akinlalu l'Osun, ìdájọ́ òdodo ni mo fẹ́ - Arábìnrin Oyebamiji
Arabinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Oyebamiji Alaba ti sọ pe ọmọ oun meji ati ọmọ iyaale oun kan ni awọn Amotekun pa niluu Akinalu nipinlẹ Osun.
Arabinrin Alaba ni ọmọkunrin oun akọkọ Oyebamiji Ismail ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn de lati oko pẹlu baba rẹ nigba tawọn ẹṣọ Amotekun gbe ọkọ mẹta ati alupupu mẹfa de ti wọn si pa a.
Obinrin naa sọ pe awọn ẹṣọ Amotekun tun pa aburo rẹ, Oyebamiji Sefiu, naa nibi ti o ti fẹ gbija ẹgbọn rẹ.
Arabinrin Alaba ni awọn ẹṣọ Amotekun tun lo aake lati ṣa ọkọ oun to ṣe itara abiamọ.
Ninu ọrọ tiẹ, Oyebamiji Rebecca, toun naa padanu ọmọ rẹ kan nibi iṣẹlẹ ọhun ni ṣadeede loun bẹrẹ si ni gbọ iro ibọn tako tako.
Arabinrin Oyebamiji sọ pe ''Ọmọ mi Ibrahim to wa wo wa nile nigba to gbọ pe wọn n yinbọn, nigba to n pada lọ sita ni wọn yinbọn fun oun naa lapa lẹyin to gbọ pe wọn ti pa aburo rẹ Sumaila.''
Awọn obi to padanu awọn ọmọ wọn naa n beere fun idajọ ododo.
Ẹwẹ, awọn iyawo awọn oṣiṣẹ Amotekun tọrọ kan naa ti sọ nnkan toju wọn ti ri lati igba ti ọrọ naa ti ṣẹlẹ.
Arabinrin Eluyode Sijuade to jẹ iyawo oṣiṣẹ Amotekun nipinlẹ Osun to wa ni atimọle ọlọpaa sọ pe ṣadeede lawọn akẹgbẹ ọkọ oun wa sọ foun nile wi pe awọn ọlọpaa ti mu ọkọ oun lọ lori iṣẹlẹ to waye ni Akinalu.
Obinrin naa sọ pe lati oṣu Kẹwaa ọdun 2025 ti wọn ti ju ọkọ oun si atimọle ni ẹbi rẹ ti n daamu kiri lati ri pe o gba ominira rẹ pada.
Arabinrin naa sọ pe ẹgbọn oun naa wa nibẹ.
Ni ọdun to kọja ni awọn ọlọpaa mu awọn ọkọ wọn lori ẹsun ipaniyan ni Akinlalu.
Ọkan lara awọn iyawo awọn oṣiṣẹ Amotekun to wa lahamọ ọlọpaa naa, Ademola Aminat wa rọ ijọba Gomina Ademola Adeleke lati ṣe iranwọ fawọn ki awọn ọkọ awọn le gba itusilẹ.






