Àwọn ajínigbé tó jí dókítà gbé l'Edo ṣìrìn, wọ́n fi ẹsẹ̀ ara wọn rìn wọnú àhámọ́ òfin

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Akọda oro ko da bii adagbẹyin ni ọpọ eeyan n wi bayii latari awọn ajinigbe meji kan ti wọn ji Dokita gbe nipinlẹ Edo, ti wọn tun pa aburo dokita naa, amọ ti wọn fi aimọ bẹ dokita ọhun lọwẹ lẹyin itusilẹ lati doola ẹmi ọmọ wọn.
Tẹ o ba gbagbe, oṣu to kọja yii ni iroyin gbode, pe awọn ajinigbe ji Dokita kan, Abu Babatunde, gbe ni Auchi, ipinlẹ Edo .
Koda, ninu ijinigbe naa ni wọn tun pa aburo dokita yii ti wọn jọ ji wọn gbe, ti wọn si tun beere fun miliọnu lọna ọgọrun (100m) owo itusilẹ.
Ọpọ eeyan ti ko mọ Dokita Abu ri ni wọn fi ti ọmọniyan ṣe dawo naa nigba naa, ko too di pe awọn ajinigbe naa yọnda rẹ.
Ajinigbe wọ gau

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, meji ninu awọn afurasi to ji Dokita Abu gbe, mu ọmọ wọn wa sile iwosan ti Dokita naa ti n ṣiṣẹ lati gba itọju lalẹ ọjọ Iṣẹgun to kọja.
Dokita naa da wọn mọ, ṣugbọn ko fu wọn lara. O tọju ọmọ naa gẹgẹ bi ilana iṣẹ to gba.
Lẹyin idanimọ ati atidaju pe awọn ẹlẹgiri naa lo fẹsẹ ara wọn rin wa sileewosan, Dokita Abu gbe igbesẹ ofin, awọn agbofinro si waa ko awọn afurasi meji naa lọ.
Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju?

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ọjọ keji, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 ni awọn ajinigbe ji Dokita Abu Babatunde ati aburo rẹ, Abu Tahir, gbe nile wọn ni Auchi, ipinlẹ Edo.
Ojọ kẹta lẹyin ijinigbe naa ni wọn ri oku Abu Tahir nitosi odo Igbira Camp. Awọn ajinigbe naa ni iroyin sọ pe wọn pa a.
Ko ti I pẹ pupọ ti Dokita Babatunde pari ẹkọ ti ijinigbe naa fi waye, ko si tilẹ ti I ṣe eto tawọn oloyinbo n pe ni Housemanship ti awọn ajinigbe fi gbe e lọ.
Ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kin-in-ni ni iroyin ro o pe wọn ti yọnda Dokita Abu Babatunde, iyẹn lẹyin owo itusilẹ miliọnu lọna aadọta (₦50 million).
Baba to bi Dokita Abu sọrọ nigba naa, o ni bo tilẹ jẹ pe Babatunde pada wale, oun padanu ọmọ oun keji.
O fi kun un pe wọn yinbọn mo Dokita Babatunde paapaa lẹsẹ nigba naa.
Ki ni ọlọpaa wi?
Alaye ọlọpaa lori iṣẹlẹ yii ree, wọn ni afurasi mẹta ni ọwọ ba.
Atẹjade ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Edo, Eno Ikoedem, fi sita nirọle ọjọ Aiku, ṣalaye pe nigba ti awon ọlọpaa n tẹlẹmuyẹ lagbegbe Auchi ni wọn ri ọkunrin kan mu.
O ni fífọ́ igbo ka ti ọlọpaa n ṣe pẹlu awọn fijilante, ti wọn wọ igbo Warake lo mu esi wa lọjọ kẹta oṣu Keji ọdun 2026.
Nibi ti wọn ti n ṣe eyi lo ni awọn ti mu ọkunrin kan torukọ rẹ n jẹ Saminu Kawujie.
Alukoro sọ pe awọn pe ipade to ṣafihan afurasi naa ni teṣan, nibẹ lo si ti han pe ọkan lara awọn to ji Dokita Abu gbe ni.
Awọn afurasi meji mi-in lo ni ọwọ ba nileewosan Auchi Specialist Hospital, nibi ti wọn ti lọ tọju mọlẹbi wọn kan.
O ni Dokita ti wọn ji gbe naa lo da wọn mọ ti wọn fi pada fọwọ ofin mu wọn.
Awọn meji to ni ọwọ ba nileewosan naa ni Idris Abubakar ati Sani Abubakar.
"Idris Abubakar gan-an ni ẹni ti wọn tọka bii ẹni to gba owo itusilẹ fun Dokita Abu."
Bẹẹ ni Alukoro wi.
O ni iṣẹ ti n lọ lati tu ikọ ajinigbe naa ka ni Auchi.


























