Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ìyá onílé tí wọ́n ló fún ọmọ ayálégbé rẹ̀ ní májèlé mu l'Ondo

Aworan ike ti majele naa wa ninu rẹ ati ami idanimọ ileeṣẹ ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Police

Àkọlé àwòrán, Aworan ike ti majele naa wa ninu rẹ ati ami idanimọ ileeṣẹ ọlọpaa
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti mu iya onile kan, Nofisat Lateef, ẹni ti wọn fẹsun kan pe o fun ọmọ ayalegbe rẹ, Abdulrasheed ti ko ju ọmọ ọdun mẹta lọ ni majele mu.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abayomi Jimoh, ṣalaye pe iṣẹlẹ yii waye lọjọ kẹrin, osu Keji ọdun 2026, lagbegbe Omifon, nijọba ibilẹ Odigbo, ipinlẹ Ondo.

Ede aiyede kan ni a gbọ pe o ti waye ṣaaju laaarin iya ọmọ naa to n jẹ Rofiat ati iya onile ẹni ogoji ọdun naa.

Kí ló ṣẹlẹ̀ gan?

Ninu alaye Alukoro, o ni lẹyin majele ọhun ni Abdulrasheed bẹrẹ si bi, eyi ti wọn fi sare gbe e digbadigba lọ si ileewosan, nibi ti wọn ti du ẹmi rẹ.

Owurọ ọjọ keji iṣẹlẹ naa iya ọmọ fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti bi Alukoro Jimoh ṣe ṣalaye, ni teṣan ọlọpaa to wa ni Odigbo.

Ifisun naa lo ni o mu ọlọpaa bẹrẹ iwadii, ti iwadii si fi han pe ọjọ kẹrin oṣu Keji ọdun yii ni Nofisat fun Abdulrasheed ni nnkan mu.

O fi kun un pe ayẹwo fi han rẹ pe majele lo fun ọmọ naa mu.

Ija to ti waye ṣaaju laaarin iya onile ati iya Abdulrasheed lo ni o fa a ti iya onile fi fun ọmọ kekere naa ni majele mu lati gbẹsan.

Kia ni ọlọpaa lọ gbe Nofisat lẹyin eyi, o si ti jẹwọ pe loootọ loun fun Abdulrasheed ni majele mu, bi Alukoro ọlọpaa Ondo ṣe fidi ẹ mulẹ.

Iya onile naa yoo foju bale ẹjọ lẹyin iwadii kikun ni ọlọpaa sọ.