Fulani mẹ́ta tó wà ní àhámọ́ àwọn aṣọ́gbó nílùú Oloka l'Ogbomoso la fẹ́ dá sílẹ̀ ló jẹ́ ka ṣekúpa aṣọ́gbó márùn ùn - Afurasí jẹ́wọ́

Oríṣun àwòrán, Other
Ọkan lara awọn afurasi agbẹbọn to ṣekupa aṣọgbo marun un niluu Oloka, ni ijọba ibilẹ Oriire lOgbomoso, Abubakar Abdullahi, ti sọ pe nitori awọn Fulani darandaran mẹta to wa lahamọ awọn aṣọgbo naa lo jẹ kawọn ṣekupa wọn.
Afurasi Abdullahi ni Mohammed Dangi to jẹ igbakeji olori ẹgbẹ janduku agbebọn ọhun lo pe oun wi pe kawọn jọ ṣiṣẹ naa.
Ti ẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹfa oṣu Kinni ọdun 2026 yii lawọn agbebọn ya wọ ọfiisi awọn aṣọgbo niluu Oloka nibi ti wọn ti pa awọn marun un.
Ni nnkan bi ago mẹsan an alẹ ni a gbọ pe awọn janduku agbebọn naa ti wọn jẹ mẹwaa gun ọkada wọ ilu Oloka pẹlu ibọn atawọn oniruuru nnkan ija oloro mii.
A tun gbọ wi pe awọn agbebọn naa ji ibọn meji ati alupupu tawọn eeyan mọ si ọkada mẹta gbe lọ lẹyin ti ṣekupa awọn aṣọgbo naa tan.
Bakan naa ni wọn tun dana sun ọkada meji ni ọfiisi awọn aṣọgbo ọhun.
Nigba to n ṣalaye bi ọwọ ṣe tẹ awọn afurasi naa, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, DSP Olayinka Ayanlade, ṣalaye pe CSP Ayodeji Adepetu ni kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Oyo, CP Femi Haruna, paṣẹ wi pe ko lewaju iṣẹ iwadii lẹyin tawọn agbebọn naa ṣọṣẹ tan.
DSP Alayande ni iṣẹ iwadii lo ṣokunfa bọwọ ọlọpaa ṣe kọkọ tẹ afurasi mẹta, ninu awọn méwaa.
O ni lẹyin naa tun ni iwadii tẹsiwaju ti ọwọ ọlọpaa tun tẹ mẹrin mii ninu wọn, eyi to jẹ kawọn afurasi tọwọ ti tẹ bayii di meje.
Orukọ awọn afurasi agbebọn to ṣekupa awọn aṣọgbo marun un niluu Oloka ni Mohammed Dangi to jẹ olori wọn; Abubakar Abdullahi, Sheu Usman, Toro Malami, Usman Alhaji Umaru, Laolo Muhammadu ati Usman Alhaji Isah.
Lẹyin ti a ṣekupa awọn aṣọgbo naa tan ni a doola awọn Fulani darandaran mẹta to wa lahamọ wọn - Abubakar
Abubakar to jẹ ọkan lara awọn afurasi jabduku agbebọn naa sọ pe Fulani loun lati ipinlẹ Kebbi, agbegbe B'Olorunduro loun si n gbe niluu Ogbomoso.
Abubakar ni darandran loun, oun si tun maa n kopa ninu ijinigbe pẹlu awọn akẹgbẹ oun.
O ni lati ilu Bode Saadu nipinlẹ Kwara loun ti da ẹran de ilu Ogbomoso.
Abubakar ṣalaye pe ''Mohammed Dangi lo ranṣẹ pe mi, o si sọ fun mi atawọn yooku wi pe ki a lọ pa ẹnikẹni ti a ba ri ni ọfiisi awọn aṣọgbo niluu Oloka.
Nnkan to sọ fun wa ni pe awọn aṣọgbo naa ti ju darandaran Fulani mẹta si ahamọ.
O ni ki a doola awọn Fulani mẹta ọhun ti a ba ti pawọn aṣọgbo naa tan.
Bayii ni a ṣe doola awọn eeyan wa léyin ti a pa awọn aṣọgbo naa tan.
Mẹwaa ni gbogbo wa, ọkada marun un ni a gbe lọ si ilu Oloka lọjọ naa pẹlu ibọn AK-47 marun un.
Bakan naa ni a tun gbe awọn nnkan ija oloro mii dani.
Ọna jinjin ni a gbe awọn ọkada wa si ki a to fẹsẹ rin lọ si ọfiisi awọn aṣọgbo naa nibi ti a ti ṣina ibọn bolẹ
Mi o mọ igba ti wọn ti n gbero lati ṣe ikọlu naa, amọ, mo darapọ mọ wọn lọjọ ti iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ gan an gan an.''
Ẹwẹ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti sọ pe iwadii si n lọ lọwọ lati mawọn afurasi mẹta toku ki wọn le foju bale ẹjọ.



























