Iyabo Oko: Mo ti ń gbádun, àmọ́ ìyà ọkọ̀ ń jẹ mi láti lọ fún àyẹ̀wò nílé ìwòsàn

Oríṣun àwòrán, iyabo_oko
Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba to dubulẹ aisan, Iyabo Oko, ti ke si awọn ololufẹ rẹ lati ṣe iranlọwọ owo fun ko le fi tọju aisan to n ba finra.
Iyabo Oko lo fi ẹbẹ naa lede lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori aisan to n ba finra.
Agba oṣere naa kọkọ dupẹ lọwọ awọn ololufẹ rẹ fun aduroti wọn lati igba ti wọn ti gbọ pe o n ṣaisan, o si ṣe adura fun wọn pe wọn ko ni fi iru rẹ gba a.
- Ìròyìn ayọ̀, Iyabo Oko kúrò nílé ìwòsàn, ó ń sọ̀rọ̀ fatafata àmọ́...
- Báyìí ni ìrìnàjò àìsàn Iyabo Oko ṣe bẹ̀rẹ̀ láti ọdún márùn ún ṣẹ́yìn
- Àwa ọmọ Iyabo Oko ló dá owó gọbọi fi gbé ìyá wa lọ sí India fún ìtọjú- Ewa, ọmọ Iyabo Oko
- A ti gbálé ati gbáta, kò sí ǹkankan lọ́wọ́ wa mọ́ ni a ṣe kígbe síta- Adebisi Aisha, Ọmọ Iyabo Oko
- Ẹ dákun ẹ ran Iyabo Oko lọ́wọ́, ìyá ti ń ṣàárẹ̀ láti ọdún márùn ún sẹ́yìn, o ti kọjá agbára wa- Foluke Daramola Salako
- "Àìsàn tó ń ṣe Iyabo Oko ti ṣàkóbá fún ọmọ ìka ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀"
O sọ pe oun ti n gbadun, bẹẹ si ni alaafia ti n de ba agọ ara oun ju ti iṣaaju lọ, amọ o ku ni bọn n ro.
Iyabo Oko ni "Ara mi ti n ya, mo ti n wa ok, ṣugbọn mo ṣi nilo adura ati owo."
Gẹgẹ bii ohun to sọ, ọkọ ayọkẹlẹ meji ni oun fi n ṣe ẹsẹ rin tẹlẹ, ṣugbọn oun ti ta awọn ọkọ naa lati le ri owo fun itọju.
Agba oṣere naa sọ pe "Iṣẹ ti mo fẹ ran si awọn ololufẹ mi ni pe, mọto n jẹ mi niya gan."
"Mọto meji ni mo ni tẹlẹ, ṣugbọn mo ti ta ọkọ mejeji lẹyin ti aisan yii bẹrẹ, iya mọto si n jẹ mi bayii"
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "Ká ní wọ́n fún Awolowo láyèè láti tukọ̀ Nàíjíríà ni, nǹkan kò ní rí báyìí"
- FFK ti kó èébì rẹ̀ jẹ, Buhari dáa pẹ̀lú bó ṣe gba ọmọ onínàákúnàá padà - Femi Adesina
- Buhari san $500 fáwọn aláwọ̀ dúdú l‘Amẹ́ríkà láti takò ẹ̀hónú wa - Yoruba/Biafra Nation
- Ọ̀pọ̀ àwọn tó fẹ́ ràn mí lọ́wọ́ ló fi ìlọ̀kulọ̀ lọ̀ mí, àyàfi Dudu Heritage nìkan
- A pàdánù Ìyá Nkechi Blessing láìpẹ yìí- Toyin Abraham
- Mílíọ́nù méje èèyàn ni ìdọ̀tì inú afẹ́fẹ́ "Air polution" ń pa lọ́dọodún - WHO
- "Màálù tó ya sójú pópó kọlu ọ̀kadà ọkọ mí, tó sì kú ní ìkómọ ọmọ rẹ ku ọ̀la"
- Sunday Igboho kò tíì bọ́ lọ́wọ́ wa, á fi ẹ̀sùn míì kàn-án - Malami
Iyabo Oko ni ọpọ igba ti oun ba fẹ lọ sile iwosan ni kii si ọkọ ti yoo gbe oun lọ sibẹ.
O ni "Igba miran ti mo ba fẹ lọ sile iwosan a kii ri mọto, awọn to ni mọto ni adugbo yoo maa sọ pe ko si ọkọ wọn nilẹ.
"Nigba mii ẹwẹ, awọn miran a sọ pe wọn ti fi ọkọ wọn ran eeyan niṣẹ, nitori naa ni wọn ko ṣe le gbe silẹ fun mi. Iya ọkọ n jẹ mi pupọ."
Iyabo Oko pari ọrọ rẹ pẹlu idupẹ ati adura fun awọn ololufẹ rẹ, to ti n na ọwọ si lati igba ti aisan ọhun ti bẹrẹ.
Ọdun 2015 ni Iyabo Oko kọkọ dubulẹ aisan, ti ẹni to duro gẹgẹ bii akọbi ọmọ rẹ ọkunrin si gbe lọ silẹ India fun itọju, nibi to ti lo ọdun kan.
Lẹyin to pada de Naijiria, lo tun tẹkọ leti silẹ Gẹẹsi, o gbadun, amọ nnkan bii ọsẹ melo kan sẹyin ni aisan naa tun bẹrẹ.



















