Sunday Igboho: Amòfin Aliyu ń bi Malami pé ẹ̀sún wo ló tún wà nílẹ̀ tó fẹ́ fi kan ẹlẹ́jọ́ òun

Oríṣun àwòrán, Sunday_igboho1/Instagram
Amofin Yomi Aliyu, tii se asaaju ikọ agbẹjọro fun Oloye Sunday Igboho ti fun ijọba apapọ lesi lori bo se kede pe oun yoo fi ẹsun tuntun kan.
Bẹẹ ba gbagbe, ileẹjọ giga kan nilu Ibadan lo ti gbe idajọ kalẹ pe ki ajọ DSS ati ijọba apapọ san ogun biliọnu naira fun bi wọn se kọlu ile Sunday Igboho, ti wsn si tun ba dukia jẹ nibẹ.
Amọ agbẹjọro agba ati Minisita feto idajọ, Abubakar Malami lo kede ni Ọjọbọ pe ijọba yoo tun wọ Sunday Igboho ls sile ẹjọ fun ẹsun tuntun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọlọ́pàá Eko ní àwọn ti mú aríbọnyọ̀ ọlọ́pàá tó yìnbọn pa arábìnrin kan ní Ijeshatedo
- "Ká ní wọ́n fún Awolowo láyèè láti tukọ̀ Nàíjíríà ni, nǹkan kò ní rí báyìí"
- FFK ti kó èébì rẹ̀ jẹ, Buhari dáa pẹ̀lú bó ṣe gba ọmọ onínàákúnàá padà - Femi Adesina
- Buhari san $500 fáwọn aláwọ̀ dúdú l‘Amẹ́ríkà láti takò ẹ̀hónú wa - Yoruba/Biafra Nation
- Ọ̀pọ̀ àwọn tó fẹ́ ràn mí lọ́wọ́ ló fi ìlọ̀kulọ̀ lọ̀ mí, àyàfi Dudu Heritage nìkan
- A pàdánù Ìyá Nkechi Blessing láìpẹ yìí- Toyin Abraham
- Mílíọ́nù méje èèyàn ni ìdọ̀tì inú afẹ́fẹ́ "Air polution" ń pa lọ́dọodún - WHO
- "Màálù tó ya sójú pópó kọlu ọ̀kadà ọkọ mí, tó sì kú ní ìkómọ ọmọ rẹ ku ọ̀la"
- Sunday Igboho kò tíì bọ́ lọ́wọ́ wa, á fi ẹ̀sùn míì kàn-án - Malami
Nigba to n fesi si ọrọ yii, Yomi Aliyu wa n kọminu loju opo Facebook rẹ lori idi ti ijọba tun se fẹ fi ẹsun tuntun kan Sunday Igboho.
"O daju pe Malami ti faramọ bayii pe oun yoo tẹle asẹ ileẹjọ giga ni Ibadan titi ti yoo fi pe ẹjọ miran.

Oríṣun àwòrán, Yomi Aliyu SAN/Facebook
Eyi tumọ si pe agbofinro tabi ijọba ko ni yaju, halẹ tabi pa Sunday Igboho titi ti ijọpa apapọ yoo fi pinnu lori ohun ti yoo se ati igbesẹ to tun kan.
Amọ ohun to n ya wa lẹnu ni pe irufẹ ẹsun tuntun wo tun ni Malami n tọka si yii!
A wa n ki pe layọ ni yoo gunlẹ pada wa lati New York nibi to ti fesi naa si ọrọ naa."

Sunday Igboho kò tíì bọ́ lọ́wọ́ wa, á fi ẹ̀sùn míì kàn-án - Malami

Bi ina ko ba tan lasọ, ẹj ko le tan lori eekanna.
Afaimọ ki ijọba apapọ ma tun fi ẹsun mii kan ajijagbara ilẹ Yoruba, Oloye Sunday Adeyemo, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho.
Lọsẹ to lọ ni ile ẹjọ paṣẹ pe ki ijọba apapọ san ogun biliọnu owo gba ma binu fún Igboho lori ikọlu ti ajọ DSS ṣe sí ile rẹ, nibi ti eeyan meji ti ku ti ọpọ dukia si ṣofo.
Àmọ́, agbẹjọro agba, to tun jẹ minisita eto ìdájọ, Abubakar Malami ti sọ pé ijoba lẹtọọ lati pe ẹjọ kotẹmilọrun lori ìdájọ náà.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo èèwọ̀ mẹ́wàá to fi lè bọ́ lọ́wọ́ ewu iná gáàsì
- El-Rufai fẹ́ kó jàndùkú wọ apá Gúúsù ló jẹ́ kó tako òfin ìdaranjẹ̀ nígboro - Akeredolu
- Ìjọba ẹ má wòran, àjà ilé Aṣòfin tó ń jò le wó lé wa lórí - Aṣòfin sọ̀rọ̀ ṣókè!
- Ondo School Without Chairs: Iléèwé kan rèé tí kò ní àga, tábìlì, olùkọ́ àti ohun èèlò ìkẹ́kọ̀ọ́
- Tá à bá ti ibodè tó wọ Naijiria, ìyà kò bá jẹ wá lásìkò Coronavirus - Buhari
- Ọ̀run yóò ya bọ́ tí ààrẹ kò bá wá láti ẹ̀kùn gúúsù Nàíjíríà - Joe Igbokwe
- Kí ló ń fa ikú ọ̀wọọ̀wọ́ lẹ́yìn Davido?
- Ààrẹ tẹ́lẹ̀, Goodluck Jonathan ti sọ̀rọ̀ sókè, Ó ní wàhálà Nàìjíríà fẹ̀rẹ̀ gbẹ̀mí ìyá òun
Bakan naa ni Malami sọ pe ijọba apapọ tun fi ẹsun tuntun kan Igboho.
Adájọ Ladiran Akintola paṣẹ pe kí agbẹjọro agba Malami ati ajọ DSS san owo gba ma binu naa lẹyin ikọlu lọjọ kinni oṣu keje.
Àmọ́, Malami ni kò sì ohun ti ijọba apapọ n ṣe ti o lodi sí ofin.
"Ijọba ni ẹtọ lati sọ fun ile ẹjọ miran lati yi idajọ ile ẹjọ giga ilu Ibadan danu.
O sí tun le wu ijoba ko tun wa awọn ẹsun mii sí Igboho lẹsẹ.
Nitori naa, a n ṣe ayẹwo ẹjọ náà lọwọ láti mọ iru igbesẹ ti a fẹ gbe bayii," Malami lo sọ bẹẹ.
Ti ẹ ko ba gbagbe, Yomi Aliyu tó jẹ agbẹjọro Igboho lo pe Malami ati ajọ DSS lẹjọ lati san ẹẹdẹgbẹta biliọnu naira fún Igboho gẹgẹ bi owo gba ma binu lẹyin ikólu DSS sí ile rẹ lagbegbe Soka niluu Ibadan.
Igboho sí wa ni atimọle lorilede Benin nibi ti wọn ti mu ùn lọnà Irinajo rẹ si orilẹ ede Germany.
Aliyu ni ile ati awọn ọkọ bọginni bọginni olowo iyebiye ni wọn bajẹ nile Igboho nibi ti wọn tun ti pa eeyan meji.





















