Sunday Igboho: Adájọ́ ní ìjọba kò gbọdọ̀ gbẹ́sẹ̀ lé àpò owó tàbí mú Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Instagram sunday_igboho1
Ajijagbara ilẹ Yoruba, Sunday Adeyemo ti ọpọ èèyàn mọ sí Sunday Igboho, tún ti fẹyin ijoba gbalẹ nile ẹjọ.
Agbẹjọro agba ati mínísítà eto idajo ni Naijiria, Abubakar Malami ati ijoba Ààrẹ Muhammadu Buhari fẹ kí ilé ẹjọ fagile aṣẹ to pa pe ijoba ko gbodo mu Igboho, wọn ko sì gbọdọ dunkooko mọ.
Amọ adajọ Ladiran Akintola tile ẹjọ gíga ipinlẹ Oyo naa tun pàṣẹ pé ijọba ko gbọdọ gbẹsẹ le akaunti ọwọ Sunday Igboho.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìdí rèé tí ń kò fi pòórá ní àhámọ́ ọlọ́pàá lẹ́yìn ìwọ́de Yoruba Nation - Ọba Ogboni
- Ilé Ife tako èrò Alaafin lórí ìfoyè dánilọ́lá nílẹ̀ Yorùbá
- Mo ní ẹ̀rí tó dájú pé àwọn Fulani fẹ́ gba gbogbo ilẹ̀ Nàìjíríà - Ortom
- Rotimi Ameachi sọ̀rọ̀ lórí bóyá lóòtọ́ ni àjọsọ wà láàrin Tinubu àti Buhari
- Ṣé lóòtọ́ ni tírélà ti gba ààrin Laide Bakare àti Kemi Afolabi nítorí ọkunrìn?
- "Ọkàn mi gbọgbẹ́ lórí aya, ọmọ àti ẹbí mi márùn ún tí agbébọn pa lọ́jọ́ kan"
- Èmi nìkan ni ọba tó lẹ́tọ̀ọ́ láti fi oyè ilẹ̀ Yorùbá dá èèyàn ńlá lọ́lá - Alaafin
- Wo àṣírí márùn-ún tí obìnrin kò gbọdọ̀ sọ fún ọkọ rẹ̀
Gbogbo nkan yii ni ijọba fẹ kí ilé ẹjọ yi danu ṣugbọn adajọ yi ẹbẹ Malami ati ijọba apapọ danu.
Adajọ ni ohun ti wọn n bèèrè fun lodi sí ẹtọ ọmọnìyàn.
Nigba to n fidi isẹlẹ naa mulẹ, agbẹjọro fun Sunday Igboho, Yomi Aliyu ni igba keji ree ti ijọba apapọ ati Malami yoo fi ẹyin janlẹ nile ẹjọ lori ọrọ Sunday Igboho.
O ni ile ẹjọ ti wa kede pe ọjọ Isẹgun, ọjọ Keje osu Kẹsan ọdun 2021 ni igbẹjọ naa yoo maa tẹsiwaju.













