Ikọ̀ ológun Nàìjíría pa agbébọn mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) láàrín ọ̀sẹ̀ kan

Oríṣun àwòrán, Getty
Ikọ ologun orileede Naijiria sọ pe ko din ni agbebọn mọkandinlọgọrun-un (99) to dagbere faye laarin ọsẹ kan latọwọ awọn.
Bẹẹ naa ni wọn tun sọ pe ọwọ tẹ mejidinigba (198) nibi awọn ikọlu ti wọn ṣe si ibuba awọn agbebọn naa lawọn ipinlẹ kan l’Oke-ọya.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ologun lorilẹede ọhun, Ọgagun Edward Buba sọ eyi di mimọ lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ l’Ọjọbọ, ọjọ kẹtalelogun oṣu kọkanla, 2023, niluu Abuja.
Yatọ sawọn agbesunmọmi to pade iku atawọn eyi tọwọ ba, Ọgagun Buba ṣalaye pe eeyan mọkandinlogoje (139) ti wọn wa nigbekun awọn ajinigbe naa lawọn tun gba kalẹ lọwọ wọn.
''Ibọn AK47, ibọn ilewọ ẹlẹnu meji ati oriṣiiriṣii nnkan ija la gba lọwọ wọn''
O fi kun alaye rẹ pe nnkan ija ogun bii ibọn AK 47, ibọn ilewọ ẹlẹnu meji rẹpẹtẹ atawọn ẹlẹnu kan, ibọn ibilẹ pẹlu ogunlọgọ irufẹ ibọn mii lawọn tun gba lọwọ awọn agbebọn ọhun.
Apapọ awọn nnkan ija naa si le lẹgbẹrun kan bo ṣe sọ (1,463).
Nigba to n ṣalaye nipa awọn agbegbe ti wọn ti koju awọn eeyan naa, Ọgagun Buba sọ pe Ila-Oorun Ariwa (North East), Aarin-Gbungbun (North Central) ati Iwọ Oorun Ariwa (North-West) Naijiria ni ikọlu pẹlu awọn agbebọn yi ti waye.
Agbebọn 108 pẹlu awọn ẹbi wọn jọ́wọ́ ara wọn
Ikọ ologun to pe ni Operation Hadin Kai, kọlu awọn agbebọn lọjọ kẹtadinlogun oṣu kọkanla, wọn si mu afurasi agbebọn mẹta nijọba ibilẹ Gujba, ni Yobe gẹgẹ bi Buba ṣe sọ.
Bakan naa lo ni agbebọn 108 pẹlu awọn ẹbi wọn ni wọn jọwọ ara wọn lọjọ kẹtadinlogun si ọjọ kẹtalelogun oṣu kọkanla yii .
Pupọ ninu awọn agbesunmọmi naa ni wọn si tun gba nkan ija lọwọ wọn gẹgẹ bi alaye Ọgagun Buba.
Awọn ipinlẹ bii Taraba, Yobe, Katsina, Sokoto , Zamfara, Benue, Kaduna atawọn mii ni iṣẹ aabo yii ti waye.
Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn tó gé orí àti nǹkan ọmọkùnrin DPO ní Rivers

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG
Ẹwẹ, ikọ ọtẹlẹmuyẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Bayelsa ti fi ṣikun ofin mu ọkunrin ti wọn fura si pe o lọwọ si iku DPO ọlọpaa, Bako Angbashim, ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun pa ni ipinlẹ Rivers.
Nigba to n fidi aṣeyọri naa mulẹ ninu atẹjade kan, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni Bayelsa, Butswat Asinim sọ pe ẹni ọdun mẹtalelogoji ni afurasi naa, Onyekachi Ikowa.
Asinim ni igbagbọ wa pe Onyekachi ni igbakeji ọkunrin kan ti wọ n pe ni 2Baba, to jẹ olori ẹgbẹ okunkun Icelanders to ge ori ati nnkan ọmọkunrin DPO naa.
Iroyin ni afurasi naa ti kọkọ salọ si ilu Sagamu, nipinlẹ Ogun, amọ o pada lọ silu Yenagoa nibi ti ọwọ ofin ti tẹ lọjọ Abamẹta, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2023 yii.
Atẹjade naa sọ pe “Awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Bayelsa ti mu ọkan lara awọn to ṣekupa oloogbe SP Bako Angbashim, to jẹ DPO Ahoada, nipinlẹ Rivers.”
“Afurasi naa, Onyekachi, to jẹ ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogoji ni igbakeji 2Baba to jẹ olori ẹgbẹ okunkun Icelanders”
Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Bayelsa, CP Fransis Iduh ti ke si awọn agbofinro lati ṣawari awọn akẹgbẹ rẹ ti wọn ṣi n farapamọ nipinlẹ Bayelsa.
O fi kun pe ipinlẹ Baylesa ko ni jẹ ibuba awọn ọdaran labẹ iṣakoso oun
Ẹwẹ,awọn ọlọpaa Bayelsa ti fa afurasi ọhun le ileeṣẹ ọlọpaa Rivers lọwọ to jẹ ọdọ wọn ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa ti ṣekupa ọlọpaa ọhun.
Ti ẹ ko ba gbagbe, inu oṣu Kẹsan an, ọdun 2023 yii ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Icelanders naa, ti 2Baba n dari wọn ṣekupa DPO naa, ti wọn si ge ori ati nnkan ọmọkunrin rẹ.
Koda wọn tun ya fidio awọ ẹya ara rẹ ọhun, eyi ti wọn fi lede lori ayelujara.













