Ṣe orí máa ń fọ ọ tí o bá mu ‘red wine’ tán? Ìdí rèé...

Red wine

Oríṣun àwòrán, Pixabay/Christiane

Awọn onimọ kan nilẹ Amẹrika ti sọ pe o ṣeeṣe ki awọn ti ṣawari eredi ti awọn eeyan kan ṣe n ni ẹfọri lẹyin ti wọn ba mu ọti waini tan.

Fasiti University of California ni awọn onimọ naa ti sọ pe awọn eroja kan to wa ninu eso ti wọn fi n pọn ọti ọhun, lo n mu ki ori maa fọ awọn eeyan kan ti wọn ba mu ọti naa tan.

Orukọ eroja naa ni wọn pe ni “quercetin’ eyii ti wọn ni o n ṣiṣẹ lati fọ awọn oró to wa ninu agọ ara danu, ‘antioxidant.’

Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ, eso ajara ‘red grape’ ti wọn fi n po ọti naa, maa n pese ‘quercetin’ ọhun, to ba wa ninu oorun fun igba pipẹ.

Ọti waini

Oríṣun àwòrán, Getty Images

"Ọti ‘red wine’ olowo gọbọi le mu ẹfọri pupọ wa ju olowo pọọku rẹ lọ"

Ọkan lara awọn onimọ naa, Ọjọgbọn Andrew Waterhouse ni eyii n tumọ si pe ọti ‘red wine’ olowo gọbọi le mu ẹfọri pupọ wa ju olowo pọọku rẹ lọ.

Waterhouse sọ pe “awọn eso ajara olowopọku maa n dagba lagbegbe to ni iboji, o si maa ni ewe pupọ, eyii to n daabo bo o lọwọ oorun.

“Amọ awọn ọmọ eso ajara olowo nla kere pupọ, bẹẹ si ni ewe rẹ kii pọ lapọju.”

Ṣugbọn awọn onimọ mii ko gba ọrọ Ọjọgbọn yii wọle.

Ọjọgbọn Roger Corder ni fasiti Queen Mary to wa niluu London ṣalaye fun BBC pe awọn ẹri kan fi han pe awọn eso ajara olowopọku gan lo n fa ẹfọri to pọ ju.

Eso Ajara

Oríṣun àwòrán, Getty Images

"Awọn eroja ‘sulphite’ ti wọn n fi sinu ọti waini ko ma baa bajẹ, lo n fa ẹfọri"

Awọn iwadii kan sọ pe awọn eroja ‘sulphite’ ti wọn n fi sinu ọti naa ko ma baa bajẹ lo n fa ẹfọri.

Ẹfọri naa si le bẹrẹ laarin ọgbọn iṣẹju ti eeyan ba mu ọti naa tan.

Wọn ni nnkan mii to le maa fa ẹfọri ninu ọti waini ni eroja ‘histamine.’

Eroja yii le ṣakoba fun iṣan to n gbe ẹjẹ ninu agọ ara, eyii to le fa ẹfọri.

Wayi o, awọn onimọ ti sọ pe mimu ọti lapapọ le ṣe akoba fun ara.

Fun apẹrẹ, ọti amuju le ba ẹdọforo ẹni jẹ, o si le fa aisan rọlapa-rọlẹsẹ ati asisan ọkan.

Yatọ si eyii, oniruru arun jẹjẹrẹ meje ni ọti mimu le ṣokunfa rẹ.

Ajọ Cancer Reasearch UK ati NHS ilẹ gẹẹsi sọ pe, ida kan ninu eeyan mẹwaa to ni arun jẹjẹrẹ ọmu, lo lugbadi arun naa nipasẹ ọti mimu.