Wo irú ẹ̀dá tí Yahaya Sinwar, olórí ikọ̀ ológun Hamas jẹ́?
Lati ọwọ Frank Gardner akọroyinBBC nipa ọrọ aabo

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Yahya Sinwar ti poora.
Eyi ko jẹ iyalẹnu pẹlu bi ẹgbẹgbẹrun awọn ọmọ ogun Israel ti ṣe n lo gbogbo ọna lati mọ ibi to wa.
Sinwar ti irun ori rẹ funfun bi yinyin, ti irun ipenpeju rẹ si dudu birikiti l'olori ẹka oṣelu ẹgbẹ Hamas ni Gaza to si wa lara awọn ti Israel n wa.
Israel ni isẹ ọwọ rẹ ati awọn miiran ni ikọlu to waye lagbegbe Guusu Israel lọjọ Keje oṣu kẹwaa nibi ti eeyan ẹgbẹfa ti padanu ẹmi wọn, ti wọn si ji awọn to le ni igba gbe salọ.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọmọ ogun Israel Daniel Hagari ni ipari oṣu Kẹwaa sọ pe '"Yahya Sinwar ni ọgagun wọn... O si ti di ẹni taa n le lati pa"
"Yahya Sinwar lo pete ikọlu buruku yi" tori naa ọgagun agba IDF Herzi Halevi sọ pé "ati oun ati awọn to wa labẹ rẹ la o ṣeku pa"
O ni to fi mọ Mohammed Deif olori ìkọ ologun Hamas,Izzedine al- Qassam to n yọ bọrọ naa ni iku n run lori rẹ.
Hugh Lovatt to jẹ onimọ agba ni
Ibi to dagba si ati iye igba ti wọn mu
Sinwar, ẹni ọdun mọkanlelọgọta ti ọpọ mọ si Abu Ibrahim la bi ni ibudo awọn atipo Khan Younis to wa ni agbegbe ariwa Gaza.
Ashkelonn lawọn obi rẹ ti wa amọ wọn di atipo lẹyin iṣẹlẹ tawọn ọmọ Palestine n pe ni al Naqba,iyẹn iṣipo kuro ni ilẹ babanla wọn lẹyin idasilẹ orileede Israel lọdun 1948.
O kẹkọ nileẹkọ girama Khan Younis fawọn ọmọ ọkunrin to si kawe gboye nidi imọ ede larubawa ni fasiti Islam to wa ni Gaza.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nigba taa n wi yi, Khan Younis jẹ ilumọọka fun atilẹyin awọn ẹgbẹ Muslim Brotherhood gẹgẹ bi alaye ti Ehud Yari,onimọ ẹkọ agba Washington Institute for Near East Policy.
Ẹmẹẹrin lo ti gba ọrọ lẹnu Sinwar nigba to wa lẹwọn.
''Ẹgbẹ yi jẹ iwuri fawọn ọdọ to n lọ n si mọṣalasi ni ibudo awọn atipo ti iṣẹ ohun iya kun bẹ''
Yaari sọ pe eyi yoo si pada wa ṣe pataki lọna to sunmọ iru ipo ti Hamas ni lonii.
Ọdun 1982 ni Israel kọkọ mu Sinwar nigba to wa lọmọọdun mọkandinlogun ti wọn si tun mu lọdun 1985 bakan naa.
Asiko yi lo dẹni ti olori ikọ Hamas Sheikh Ahmed Yassin fa sọdọ gẹgẹ bi ẹni taa fọkan tan an.
Kobi Micheal oniwadii agba ni Institute for National Security Studies to wa ni Tel Aviv sọ pe ''awọn mejeeji sunmọ ara wọn gidi'' ti eleyi si jẹ okunfa bi awọn ọmọ ẹgbẹ naa ṣe n pada foju ayanfẹ wo Sinwar.
Lẹyin ọdun meji ti wọn da Hamas silẹ ni 1987 Sanwar da ikọ ẹsọ alaabo ẹgbẹ naa silẹ lẹni ọdun mẹẹdọgbọn.
Orukọ ikọ yi a si maa jẹ al-Majd.
Al-Majd pada dabi ikọ ọlọpaa ẹsin to n fiya jẹ awọn to ba hu iwa aitọ labẹ ofin ẹsin.
Micheal sọ pe Sanwar a maa foju si awọn ile itaja to n ta fiimu ibalopọ bẹẹ naa lo si tun fi ikọ yi tọ pinpin awọn ti wọn ba furasi pe o n lẹdi apopọ pẹlu Israel ti wọn a si maa pa iru eeyan bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Yaari sọ pe Sanwar lọwọ ninu iṣekupa awọn eeyan kan ti wọn fura si pe wọn n lẹdi apopọ pẹlu Israel.''O fi ọwọ ara rẹ pa awọn kan ninu wọn to si dunnu lati sọ nipa rẹ fun emi ati awọn miran''
Gẹgẹ bi awọn oṣiṣẹIsrael ti ṣe sọ, o jẹwọ pe oun paṣẹ ki ọmọ iya arakunrin kan sin laaye to si fi ṣibi da yepẹ bo o dipo ko lo sọbiiri.
Lọdun 1988 Sinwar gẹgẹ bi wọn ṣe fẹsun kan ṣagbatẹru ijinigbe ati pipa awọn ọmọ ogun ilẹ Israel meji kan.
Ọdun to tẹle, Israel ran lẹwọn lori ẹsun pe o ṣeku pa ọmọ Palestine mejila.
Ẹwọn gberee mẹrin ọtọọtọ ni da fun lẹjọ.
Ọdun to lo lẹwọn
Ọpọ igbesi aye rẹ ni Sanwar lo lọgba ẹwọn-ọdun mejilelogun-lawọn ọgba ọwọn ilẹ Israel laarin ọdun 1988 si 2011.
Igba to lo nibẹ ṣsṣe ki o ti jẹ ko di alakatakiti ju ti tẹlẹ lọ.
Yaari sọ pe ''laarin awọn ẹlẹwọn, o sọ ara rẹ di olori ti o si n dari idunadura laarin awọn ẹlẹwọn ati oṣiṣẹ ọgba ẹwọn''

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ayẹwo kan ti ijọba Israel ṣe fun Sanwar nigba to wa lẹwọn ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi ẹni to ''jẹ ika,to fẹran lati jẹ gaba to lọla,to ni ete ti nkan diẹ to to si tun mọ bi a ṣi n fi aṣiri pamọ laarin awọn ẹlẹwọn..O mọ bi wọn ṣe n dari ọpọ eeyan''
Yaari ni Sanwar jẹ ẹni to wa ni iwa ika lọkan ati pe to ba n ṣawada nipa pẹ wọn ni lati pa Israel rẹ, a maa sọ fun oun pe awọn yoo ṣe oun ku ti wọn ba pa Israel rẹ''
Sinwar kọ ede Hebrew nigba to wa lẹwọn a si maa ka iwe iroyin Israel.Yaari sọ pe ede Hebrew ni Sanwar maa n sọ si oun tohun ti pe o mọ wipe oun gbọ ede larubawa.
''O n gbiyanju lati mọ ede Hebrew sọ daada ni.Molero pe o fẹ kọ ede naa lọdọ ẹlomiran ti ede Hebrew rẹ tun dara ju tawọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn lọ.''
Ọdun 2011 ni wọn tu Sinwar silẹ lara eto idunadura kan ti wọn fi ṣe paṣiparọ ti wọn fi ọmọ ogun Israel kan Gilad Shalit paarọ ẹlẹwọn Palestine 1,027.
Ọdun marun un ni Shalit fi wa lẹwọn lẹyin ti aburo Sinwar ati awọn kan ninu ọmọ ogun Hamas ji gbe.Lati igba naa ni Sanwar ti ni ki wọn ji awọn ọmọ ogun Israel mii gbe.
Lasiko taa n wi yi,Israel ti pari ikogunja Gaza ti Gaza si ti pada sọwọ Hamas lẹyin ti wọn fidi ẹgbẹ Fatah janlẹ ninu idibo nipa jiju awọn ọmọ ẹgbẹ Fatah bọ lori orule ile sẹnu iku nisalẹ.
Ifarajin to buru
Micheal sọ pe ''Nigba to pada si Gaza, awọn eeyan tẹwọ gba gẹgẹ bi olori.
Eyi ni ṣe pẹlu bi wọn ṣe foju wo bi ọkan ninu awọn oludasilẹ Hamas to koju iya lọgba ẹwọn Israel fun ọpọ ọdun.
Ṣugbọn o tun sọ pe awọn eeyan ''bẹru rẹ''-o ni ẹni taa n wi yi fi ọwọ ara rẹ ṣeku pa ọpọ.''Ko loju aanu, o ni giragira, o si tun fa eeyan mọra bakan naa''
Yaari sọ pe kii ṣe eeyan ti ẹnu rẹ da nidi ọrọ sisọ.To ba n ba awọn eeyan sọrọ, bi igba oe ọkan lara awọn janduku lo n sọrọ ni.
Yaari fi kun pe kete to kuro lọgba ẹwọn Sinwar fọwọ sowọpọ pẹlu ikọ Izzedine al-Qassam ati olori awọn oṣiṣẹ alaṣẹ Marwan Issa.
Ni ọdun 2013 ni wọn dibo yan gẹgẹ bi ọkan lara ọmọ ẹka oṣelu Hamas to wa ni Gaza ki o to wa pada di olori rẹ ni ọdun 2017.
Aburo rẹ Mohammed naa ko ipa ribiribi ninu ikọ Hamas ki wọn to kede iku rẹ lọdun 2014.
Iroyin ti pada jade pe o ṣeeṣe ko ṣi wa laye to si sa pamọ sabẹ ilẹ.
Koda wọn lo ṣeeṣe ki o ko ipa ninu ikọlu ọjọ Keje oṣu Kẹwaa

Iwa Sanwar nipa bo ṣe buru mu ki wọn fun ni inagije alapata eeyan Khan Younis.
Yaari sọ pe wọn loun lo wa nidi igbepamọ ati ifiyajẹni ọgagun Hamas kan Mahmoud Ishtiwi ti wọn fẹsun ajẹbanu ati ibalopọ laarin ọkunrin si ọkunrin kan lọdun 2015.
Ni 2018, o sọ fawọn akọroyin pe oun faramọ ki awọn ọmọ Palestine ja wọ inu odi ọgba ti o ya Gaza sọtọ pẹlu Israel lati le fi ṣe ẹhonu bi Amẹrika ṣe gbe ileeṣẹ ilẹ rẹ ni Israel kuro ni Tel Aviv lọ si Jerusalem.
Tohun ti gbogbo eleyi, o tun ṣafihan ẹni to ni laakaye ati oye nipa fifaramọ idawọduro ija pẹlu Israel,ṣiṣe paṣiparọ awọn ẹlẹwọn ati pipari ija pẹlu ikọ Palestinian Authority.
Micheal sọ pe koda awọn kan a tun maa bẹnu atẹ lu wi pe o ti dẹ ju.
Wọlewọde pẹlu Iran
Ọpọ to wa lẹka eto aabo Israel sọ pe aṣiṣe nla lo jẹ bbi wọn ṣe jẹ ki wọn tu Sanwar silẹ lara awọn ti wọn fi ṣe paṣiparọ ẹlẹwọn laarin Israel ati Palestine.
Awọn ọmọ Israel yi ni ẹtan nla lo jẹ pẹlu bawọn ṣe ro pe pipese iṣẹ fawọn Hamas ko ni jẹ ki wọn nifẹ si ogun jija mọ.Wọn ni aṣiṣe nla leleyi jẹ.
Yari sọ pe Sanwar''ri ara rẹ gẹ́ẹ bi ẹni ti wọn yan lati wa tu awọn eeyan Palestine silẹ lọwọ amunisin''

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lọjọ Kẹrinla oṣu Kẹwaa ni agbẹnusọ ileeṣẹ ologun Israel Richard Hecht pe Sanwar ni ''Oju iwa aburu''.
O fikun pe arakunrin taa n wi yi ati awọn ikọ rẹ laa foju si lara.Ọwọ wa yoo tẹ arakunrin yẹn''
Sinwar tun sunmọ orileede Iran.Ko wọpọ ki ifọwọsowọpọ wa laarin orileede Shia ati ikọ Sunni amọ ero wọn papọ nipa pipa orileede Israel rẹ ki wọ situ Jeruslaem silẹ kuro lọwọ ajaga Israel.
Wọn ni lati fọwọsowọpọ tori owo ti Iran fi n ranṣẹ ni wọn fi n ṣe igbaradi fawọn ọmọ ikọ ologun Hamas lati le doju ija kọ awọn ilu Israel.
Ninu ọrọ rẹ kan to sọ lọdun 2021 Sanwar fi ẹmi imoore han pe ''bi kii ba ṣe ti Iran awa ajafẹtọ nilẹ Palestine ki ba ma ni ikapa eleyi taa ni bayii''
Afikun iroyin lati ọwọ Jon Kelly












