Olùkọ́ fásítì tí wọ́n lù, yẹ̀yẹ́ níta gbangba pé ó ń bá akẹ́kọ̀ọ́ lòpọ̀ ní yàrá ìkàwé, ohun tí a mọ̀ rèé

Awọn ti won n wọ́ olukọ naa ree bi wọn ṣe yẹyẹ rẹ nita gbangba

Oríṣun àwòrán, Others

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Eegun to ba ti jade ti kuro ni ai wo o ni ọrọ fidio kan to gba ori ayelujara kan bayii, nibi tawọn akẹkọọ kan ti n lu ọkunrin kan ti wọn ni olukọ yunifasiti ni, ti wọn si tun fa aṣọ ya mọ ọn lara pẹlu.

Koda, iroyin sọ pe Alufaa ijọ Aguda ti a mọ si Katoliiki ni ọkunrin ti wọn n lu ninu fidio naa.

Ati pe akẹkọọbinrin kan lo n ba sun ni yara ikawe ti wọn fi ka wọn mọbẹ.

Ile ẹkọ giga Tansian University, Oba, nipinlẹ Anambra ni iṣẹlẹ naa ti waye bi iroyin ṣe sọ.

Ki lo ṣẹlẹ gan-an?

Ninu fidio to to jade lori ayelujara naa, awọn akẹkọọ n mu ọkunrin ti aṣọ funfun to wọ ti faya naa jade lati inu yarak an.

Ṣokoto nikan lo wa nidii rẹ to ṣi duro rẹgi, ẹwu funfun to wọ ni wọn ti ya mọ ọn lara.

Bi wọn ṣe n ti ọkunrin naa sọtun-sosi ni wọn n sọ pe 'Ok'. Bẹẹ naa ni wọn si ṣe n ti ọmọbinrin kan to wọ laba dudu pẹlu ọkunrin naa laaarin ero.

Gẹgẹ bi awọn akẹkọọ ti wọn ko darukọ wọn ṣe ṣalaye, o pẹ ti olukọ yii ti maa n fi ilọkulọ lọ awọn akẹkọọbinrin ninu ọgba fasiti naa.

O tilẹ ti di pe ọpọ awọn akẹkọọ obinrin lo n kọminu nipa bo ṣe maa n fẹ ba wọn ni nnkan pọ, to si maa n nawọ ifẹ si awon mi-in pẹlu.

" O jọ pe wọn ti n dọdẹ rẹ , wọn si ti pinnu lati mu un ṣinkun ni wọn fi ka a mọ ibi to ti n ba akẹkọọ ṣepọ ni yara ikawe."

Bẹẹ ni akẹkọọ kan ti ko darukọ rẹ ṣalaye.

Eyi naa ni wọn lo jẹ ki wọn yẹyẹ olukọ naa nita gbangba, ti wọn tun ṣe fidio rẹ, ti wọn si ju u sori ayelujara.

Ṣe loootọ ni pe Alufaa ijọ Aguda ni olukọ yii?

Bo tilẹ jẹ pe ohun to kari ayelujara ni pe Alufaa ijọ Aguda ni olukọ yii, a ko le fidi eyi mulẹ.

Ohun kan to foju han ṣaa ni pe yunifasiti naa jẹ ti ẹka ijọ Katoliiki.

Bakan naa ni pupọ ninu awọn olukọ ibẹ si jẹ ojiṣẹ Oluwa.

Ṣugbọn fidio to ṣafihan ẹ̀sín ti wọn fi olukọ naa ṣe ko sọ boya o ni ohunkohun pẹlu ijọ Aguda.

Lasiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, awọn alaṣẹ Tansian University ati ijọ Aguda ko ti I sọ nnkan kan lori iṣẹlẹ naa.

Bakan naa si ni wọn ko sọ ohunkohun nipa ọmọbinrin ti wọn ni olukọ n ba ṣe aṣemaṣe.