BBC 100 Women 2023: Àwọn wo ló wà nínú àkọsílẹ̀ obìnrin tó lààmì-laaka jùlọ ní àgbáyé lọ́dún yìí?

Ileeṣẹ BBC lo ti fi orukọ obirin ọgọrun to n ṣe moriya fawọn obirin ẹgbẹ wọn ti wọn si tun gbajugbaja julọ lagbaye lede fun ọdun 2023.
Lara awọn ọgọrun yii ni a ti ri aya aarẹ ilẹ America tẹlẹ ri Michelle Obama ati agbẹjọro to n ja fẹtọ ọmọniyan Amal Clooney.
Awọn yoku ni obinrin to mọ bọọlu gba julọ lagbaye Aitana Bonmati, onimọ nipa AI Timnit Gebru, ajafẹtọ awọn obirin Gloria Steinem, oṣere sinima nilẹ America Ferrera ati oniṣowo aṣaraloge Huda Kattan.
Ninu awọn ọgọrun yii, a boju wo awọn to jẹ ọmọ ilẹ Africa nibẹ lati ṣe moriya fun gbogbo obirin jakejado ilẹ adulawọ

Paulina Chiziane, Mozambique,
Paulina Chiziane ni obirin akọkọ ti yoo tẹ iwe jade lorilẹ-ede Mozambique pẹlu ‘Ballad of Love in the Wind’ ni nkan bii ọdun 1990.
Chiziane dagba nitosi Maputo to jẹ olu-ilu Mozambique nibi to ti kọ ede potoki nile-ẹko aguda kan. O tun kẹkọ nipa ede ni fasiti Eduardo Mondlane amọ ko ṣetan nibẹ.
Oriṣiriṣi ede bii Gẹẹsi, German, ati Spanish ni wọn ti ṣe ẹda awọn iwe rẹ si, to si ti gba ami ẹyẹ loniranran.

Susan Chomba, Kenya,
Susan Chomba ni adari World Resources Institute (WRI). O wi pe iya ti oun jẹ ni kekere lo mu ki oun o maa ran awọn eeyan lọwọ.
Iddabobo awọn aginju, sisọ ilẹ di ọtun ati mimu ayipada rere ba ọrọ ounjẹ ni Africa lo jẹẹ logun.
Jakejado Africa ni Chomba ti n ba awọn agbẹ kekeeke ṣiṣẹ, paapaa julọ awọn obirin ati ọmọde, lati bawọn tun ilẹ wọn ṣe.
O si maa n fi imọ rẹ ran ijọba atawọn oluṣewadii lọwọ.
Esi Buobasa, Ghana, Apẹja

Esi Buobasa jẹ ọmọ bibi ilu Fuveme tii se ọkan lara awọn abule ti okun ti wọ lọ.
O si mọ akoba nla ti ayipada oju ọjọ mu wa lara pupọ.
Nigba ti okun kun si, ti awọn eeyan ko si fẹ kuro ni agbegbe ti wọn n gbe, oun ati ọkọ rẹ pẹlu awọn ọmọ wọn marun ko lọ si ibomiran.
Buobasa, tii se gbajumọ iya ẹlẹja ni abule rẹ wa da ẹgbẹ kan silẹ pẹlu awọn akẹẹgbẹ rẹ.
Afojusun wọn si ni lati seranlọwọ fawọn obinrin apẹja lagbegbe naa nitori bi agbara eti okun se n dunkooko mọ orisun ọrọ aje wọn.
Ẹgbẹ naa, ti ko ni ju ọgọrun ọmọ ẹgbẹ lọ, lo maa n se ipade ni ẹẹkan lọsẹ lori awọn ọrọ to n se akoba fawọn obinrin ati okoowo wọn.
Ẹgbẹ naa si da owo fawọn mọlẹbi to se alaini ni abule naa.

Neema Namadamu, Democratic Republic of Congo, Ajafẹtọ awọn akanda
Ajọ Hero Women Rising (abi Mama Shuja) ni o n gbiyanju lati mayedẹrun fun awọn obinrin ati ọdọbirin ni DRC.
Ajafẹtọ awọn akanda Neema Namadumu lo da ajọ yii silẹ to si n eto ẹkọ ati imọ-ẹrọ lati sọrọ nipa igbe aye awọn obinrin ati lati jẹ ki wọn mọ ẹtọ wọn.
Wọn bi Namadumu ni ileto kan lapa ila-oorun Congo. O ni arun ‘polio’ nigb to wa lọmọ ọdun meji. Oun si ni akanda akọkọ lati lati ẹya rẹ ti yoo jade ile-ẹkọ fasiti.
O di ọmọ ile aṣofin o si tun ti jẹ olubadamọran fun minisita fọrọ awọn obinrin ati idile.

Jennifer Uchendu, Nigeria, Agbẹnusọ lori ilera ọpọlọ
Jennifer Uchendu lo n ṣiṣẹ lori ipa ti ayipada oju ọjọ ni lori ọpọlọ awọn olugbe ilẹ Africa.
Afojusun ẹgbẹ ọdọ SustyVibes ti Jennifer Uchendu da silẹ ni lati ripe ohun gbogbo fẹsẹmulẹ to sii ṣe fọkan tan.
Ni 2022, o da ajọ The Exco-Anxiety Africa Project (TEAP) silẹ lati moju to idaabobo imọlara awọn ọmọ ilẹ adulawọ lẹyin ayipada oju ọjọ nipa iwadi ijinlẹ, ṣiṣe agbawi ati ipolongo nipa ayipada oju ọjọ.
Ohun to jẹẹ logun ni lati ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn eeyan ati ileeṣẹ to nifẹ si kikọ nipa imọlara ayipada oju ọjọ.

Wanjira Mathai, Kenya, Olugbanilamọran lori ọrọ ayika
Awokọṣe nla ni Wanjira Mathai jakejado Africa. O le logun ọdun to ti jẹ alagbawi fun ayipada ayika ati awujọ.
Oun ni adari ‘Green Belt Movement’ to jẹ ilumọọka ajọ to n ro awọn obinrin lagbara nipa igi gbigbin ni Kenya. Iya a Wanjiri, Wangari Maathai, to gba ami-ẹyẹ Nobel fun alaafia lọdun 2004, lo da ẹgbẹ naa silẹ.
Lọwọlọwọ yii, Mathai ni adari awọn abaṣepọ ni Africa ati lagbaye fun ‘World Resources Institute’, oun naa si ni alaga ‘Wangari Maathai Foundation’.
Mathai ni olubadamọran lati Africa fun ‘Bezos Earth Fund’, ‘Clean Cooking Alliance’ ati ‘European Climate Foundation’.

Yasmina Benslimane, Morocco, Oludasilẹ Politics4Her
Yasmina Benslimane lo fara rẹ jin fun imudọgba akọ ati abo. Oun ni oludasilẹ Politics4Her to n ṣe agbatẹru obinrin ati ọdọbinrin yoo ṣe maa kopa ninu oṣelu ati ohun to nii ṣe nipa igbe aye wọn.
Nigba iṣẹlẹ ilẹ riri waye lorilẹ-ede rẹ, Morocco, loṣu kẹsan ọdun yii, Benslimane ati ajọ rẹ pe fun iranwọ ti yoo maye dẹrun fawọn obinrin.
O ṣe atẹjade kan to ṣafihan awọn ipenija ti obinrin ati ọdọbinrin n doju kọ leyi ti ajalu naa yoo tunbọ jẹ ko buru sii, bii oṣi ati ifipafinifọkọ.
Gẹgẹ bii olutọni, olugbanilamọran ati ọmọ igbimọ adari lawọn ẹgbẹ ati ajọ to pọ,Benslimane maa n ran awọn ọdọbinrin lọwọ lati ṣe awari ati idagbasoke iwa adari laye wọn. Iṣẹ rẹ ti mu ko gba ami-ẹyẹ fun igbelarugẹ alaafia lawujọ awọn obinrin latọdọ ajọ UN.

Zandile Ndhlovu, South Africa, Olukọ wiwọ okun lai lo afẹfẹ atọwọda lati mi
Gẹgẹ bii obinrin akọkọ ti yoo jẹ olukọ wiwọ okun lai lo afẹfẹ atọwọda lati mi, Zandile Ndhlovu ni oun fẹẹ ki awọn to n wọnu okun o pọ sii.
O da ẹgbẹ ‘The Black Mermaid Foundation’ silẹ leyi to n fi oju awọn ọdọ atawón ileto mọ oku pẹlu afojusun pe wọn yoo le loo9 fun igbafẹ ati ere idaraya.
Ndhlovu jẹ ẹni to nifẹ okun, onkọtan, ati oṣere. O n lo gbogbo ẹbun yii lati ṣe agbekalẹ awọn ọdọ ti yoo maa moju to imọtoto okun, ẹkun omi ati kikopa ninu idaabobo agbegbe wọn.

Ulanda Mtamba, Malawi, Olugbogun ti fifi ọmọde f'ọkọ
Ulanda Mtamba dagba ni ileto kan ni Lilongwe, lorilẹ-ede Malawi, nibi ti ko ti si atilẹyin fun ẹkọ awọn obinrin, leyi to mu ki ọpọlọpọ o file-ẹkọ silẹ lati lọọ lọkọ lai tii pe ọmọ ọdun mejidinlogun.
Mtamba lo pe irufẹ aye yii nija, to si rii pe oun kẹkọ gboye ‘Master’s’ lẹyin to ṣetan ni fasiti.
O n ṣe ipolongo fun amulo awọn ofin to daabo bo awọn ọdọbirin tako igbeyawo laitọjọ ati ki wọn moju to awọn ipenija ilera to rọ mọ oyun nini ni kekere.
Lọwọ yii, Mtamba ni adari ‘AGE Africa’ ni Malawi, iṣẹ ajọ naa si ni lati rii pe awọn ọdọbirin naa ni anfani lati wọ ile-ẹkọ girama bii awọn ọkunrin naa jakejado ilẹ adulawọ.

Vee Kativhu, Zimbabwe/UK, Oludanilẹkọ lori ẹrọ ayelujara
Vee (Varaidzo) Katibhu ni ọrọ ikẹkọọ rẹ jẹ moriya fun ẹgbẹlẹgbẹ awọn eeyan jakejado agbaye. Lakoko to wa nile-ẹkọ naa lo n ṣiṣẹ pẹlu ile ounjẹ McDonald, to si tun pada kẹkọ gboye ni fasiti Oxford ati Havard.
Nigba to wa ni fasiti, o ṣe idasilẹ oju opo kan ni ikanni YouTube lati maa ṣe afihan awọn adojukọ rẹ gẹgẹ nii akẹkọọ to wa lati idile to ku diẹ kaato fun, ati lati ṣalaye ọna ifarada ati igbiyanjui lati ja ajabọ fun awọn miran bii tirẹ.
Lati igba yii wa, Kativhu ti ṣe idasilẹ ‘Empowered by Vee’ leyi to fi n ṣe iranwọfun awọn to kudiẹ kaato fun jakejado agbaye lati ni anfani ile-ẹkọ giga.
O ti kọ iwe kan pẹlu iriri rẹ lati ṣe iranwọ fawọn ọdọ, o si n kẹkọ lọwọ lati gboye ọmọwe ninu idanilẹkọ.

Gladys Kalema-Zikusoka, Uganda, Olutọju ẹranko
Gladys Kalema-Zikusoka, to jẹ gbajugbaja olutọju awọn ẹranko ati oludaabo bo ayika ni Uganda, lo n sa ipa lati daabo bo awọn inanki ori apata to ti fẹẹ tan nilẹ latari bi ayipada oju ọjọ ṣe n ba ibugbe wọn jẹ.
Oun ni oludasilẹ ati oludari ‘Conservation Through Public Health’, ajọ to n ṣe agbatẹru bi awọn eeyan, inanki, atawọn ẹda miran ninu ẹgan ṣe le maa gbe pọ ni alaafia ati ilera pipe.
Lẹyin ọgbọn ọdun, o ti mu ki inanki ori apata to wa ni Uganda o di ẹẹdẹgbẹta lati ọọdunrun, leyi to mu ka ma kawọn kun ẹranko to ti fẹẹ tan lorilẹ mọ.
Ọdun 2021 ni ajọ iṣọkan agbaye to n moju to ọrọ ayika pe Kalema-Zikusoka ‘Aṣiwaju Aye’.

Shamsa Araweelo, Somalia/UK, Olupolongo gbigbogun ti didabẹ f'ọmọbinrin
Latari ipinnu rẹ lati rii pe opin de ba didabẹ f’awọn ọmọbinrin, Shamsa Araweelo lo n ṣe idanilẹ ati ilanilọyẹ nipa rẹ pẹlu a\won fanran to lagbara lori ayelujara.
Araweelo, ẹni ti wọn bi ni Somalia amọ to n gbe ni UK lọwọ yii, ni wọn dabẹ fun lọmọ ọdun mẹfa leyi to tumọ si pe wọn diẹ abi gbogbo nkan ọmọbinrin rẹ to yẹ ko jade sita latari awọn idi ti ko ni nkankan ṣe pẹlu ilera rẹ.
Pẹlu awọn to le ni aadọrin miliọnu to ti wo awọn fanran rẹ loju opo Tiktok, Araweelo lo wi pe oun ko fẹẹ ki ẹnikẹni wa ti ko tii gbọ nipa fifopin si didabẹ f’ọmọbinrin.
Awọn ọmọ ilẹ Gẹẹsi ti wọn ha s’oke okun atawọn ti mọlẹbi wọn n ṣe bi ko ṣe tọ ni Araweelo n ṣe iranwọ fun lọwọ yii. O si tun fun ajọ ọlọpaa ilu London lamọran lori didabẹ f’ọmobinrin. Bẹẹ na lo ti ṣe ifilọlẹ ajọ iranwọ tirẹ to pe ni ‘Garden of Peace’.












