Ọfà ni wọ́n ta mọ́ mí tó sọ mi di arọ, àwọn tó wà nídìí ọ̀rọ̀ mi kò jáwọ́ lẹ́yìn tí mo gbádùn tán - Ọ̀rọ̀ tí Okemesi sọ kó tó kú

Oloogbe Bamidele Tope Saint tawọn eeyan mọ si Okemesi wọ aṣọ dudu, o si de fila

Oríṣun àwòrán, Okemesi/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajugbaja adẹrinpoṣonu, Bamidele Tope Saint, ti ọpọ mọ si Okemesi sọ nipa iru aisan to ṣe e ki o to dagbere faye.

Okemesi sọrọ yii ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe lori itakun ayelujara pẹlu Jeff Owolewa.

Oloogbe naa sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo naa pe ọfa ni wọn ta mọ oun ti oun fi ṣe aisan.

''Ohun ti oju mi ri lagbara nigba ti ọfa naa wọle si mi lara, lori iduro bayii ni mo ti mo ti ṣubu lulẹ.

Ọfa to ba mi kii ṣe ọfa lasan, ẹyin araale, ọfa nla ni o.

Ọfa naa jẹ ki n ya arọ ni o, o le debi wi pe mo n da itọ lẹnu nigba kugba ti mo ba fẹ sọrọ.

Wọn gbe mi lọ si ile iwosan Bisland, nigba naa lawọn eeyan bẹrẹ sii dawo fun mi.

Nigba to ya ni wọn pe ẹgbọn mi kan to wa niluu Osogbo, wọn si sọ fun un pe ara mi ko ya.

Ẹgbọn mi yii lo ni ki wọn fi mi le ọkọ wa si ilu Osogbo ki oun le tọju mi.

Mi o le da duro funra mi mọ, niṣe ni mo n da itọ lẹnu, bayii lawọn eeyan bẹrẹ sii maa gbadura fun mi,'' Okemesi lo sọ bẹẹ.

Ni ṣọọṣi ti wọn gbe mi lọ ni Arakeji ni mo ti ri iwosan - Okemesi

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Oloogbe Tope ṣalaye pe ẹgbọn oun to wa niluu Osogbo lo gbe oun lọ sọdọ aafa rẹ.

O ni aafa naa beere wi pe oun ati ta lawọn jọ n du nnkan, oloogbe naa si sọ pe oun ko ba ẹnikẹni du nnkan kan.

Okemesi ni bi oṣu meji loun fi wa lọdọ ẹgbọn oun to n tọju oun niluu Osogbo.

Oloogbe naa ni ṣadeedee ni ẹgbẹ oun ni ijamba pẹlu ọkada to n gun.

O ni ninu ṣọọṣi to wa ni Arakeji toun tẹle awọn pasitọ toun wa ni ṣọọṣi wọn lọ loun ti ri iwosan.

Okemesi ni nibẹ ni oun ti sọ ọpa toun fi n rin nu, toun si bẹrẹ sii fi ẹsẹ oun rin.

Oloogbe naa ni lẹyin naa loun pada lọ sọdọ iyawo oun ni ilu Ado Ekiti nibi ti o ti tọju oun ti oun si dun un wo pada.

Amọ, o ṣalaye pe aṣiṣe toun ṣe ni pe oun pada si ilu Eko nibi tawọn to ta oun lọfa tun ti ri oun.

Okemesi sọ pe bayii loun bẹrẹ si ni ru, ti awọ ara oun ṣi n ṣi mọ kan-in-kan-in lara toun ba ti n wẹ.

Okemesi ni a gbọ pe o jade laye ni ile iwosan kanni ọjọ Isẹgun, ọjọ Kẹrinlelogun oṣu Keji ọdun 2026 ni dede ago mejila ku isẹju mẹwaa.