Èèwọ̀ méje tí kò fi ìdí múlẹ̀ nípa nǹkan oṣù obìnrin nílẹ̀ Yorùbá

nǹkan oṣù

Oríṣun àwòrán, others

Jakejado agbaye ni igbagbọ ti wa pe eniyan ara ọtọ ni awọn obinrin, akanṣe iṣẹ Olodumare si ni wọn pẹlu nitori iṣẹda wọn.

Lara ohun to si mu ki awọn obinrin jẹ eniyan ọtọ ni ṣíṣe nnkan oṣu, eyi ti yoo mu ki wọn loyun ati bímọ.

Ṣugbọn bi nnkan oṣu obinrin ti ṣe pataki to fun ibisi ẹda yìí, sibẹ oniruuru awọn igbagbọ ti ko fi idi mulẹ lode oni, ni Yoruba so mọ, eyi ta mu lẹsẹ lẹsẹ wa fun yín.

Igbagbọ meje nipa nnkan oṣu obinrin ti ko fi idi mulẹ

Nnkan oṣu n ba oogun ibilẹ jẹ:

Igbagbọ Yoruba ni pe obìnrin to ba n ṣe nnkan oṣu ko mọ rara, ohun ẹgbin si ni. Irufẹ obinrin bẹẹ si ni wọn kii jẹ ko fi ọwọ tabi ara kan oogun ibilẹ nitori igbagbọ pe oogun naa yoo bajẹ ni.

Koda, obinrin to ba n ṣe nnkan oṣu ni wọn kii gba ko jokoo ti ẹni to ni oogun ibilẹ lara nitori igbagbọ pe, oogun naa yoo bajẹ.

Bẹẹ ni irufẹ obinrin bẹẹ ko gbọdọ ja ewe ati egbo tabi fi ọwọ kan wọn, titi ti nnkan oṣu rẹ yoo fi pari.

Ṣugbọn ko si imọ sayẹnsi ati ẹri to daju lati fi idi igbagbọ yii mulẹ.

nǹkan oṣù

Oríṣun àwòrán, others

Nnkan oṣu obinrin wulo fun oogun owo:

Igbagbọ kejì ti ko tun fi idi mulẹ nipa nnkan oṣu obinrin ni pe aṣọ, òwú , pata, páàdì abi ohunkohun ti obinrin ba fi ṣe nnkan oṣu lee wulo fun oogun owo lọdọ awọn adahunse tabi onisegun ibilẹ.

Idi si ree ti ọpọ obinrin kii ṣe jafara pẹlu awọn eroja ti wọn fi n ṣe nnkan osu wọn, bi o tilẹ jẹ pe eyi lee ni nnkan ṣe pẹlu iwa imototo.

Bẹẹ si ni ko si iṣẹ iwadii abi arigbamu ẹri kankan to fi idi rẹ mulẹ pe eroja nnkan osu obinrin lee wulo fun oogun owo.

Obinrin to n ṣe nnkan oṣu ko le jọsin fun Ọlọrun:

Igbagbọ kẹta ti ko fi idi mulẹ nipa nnkan oṣu obinrin ni pe obinrin ko ba n ṣe nnkan oṣu ko le jọsin niwaju Oluwa, ko jẹ itẹwọgba.

Bi o tilẹ jẹ pe ẹsẹ Bibeli ni majẹmu laelae ati Kurani tọkasi eyi, ti awọn Kristẹni alaṣọ funfun atawọn Musulumi si n tẹle, ti awọn ẹlẹṣin abalaye naa si fara mọ igbagbọ yii, sibẹ awọn ọlaju ati imọ sayẹnsi kan tako igbagbọ naa pe ko tọna, ti ọpọ obìnrin miran si maa n jọsin lasiko ti wọn n ṣe nnkan oṣu lọwọ.

Ọkunrin to ba ni ibalopọ pẹlu obinrin to n ṣe nnkan oṣu yoo ku:

Igbagbọ kẹrin nipa nnkan oṣu obinrin ti ko fi idi mulẹ ni pe, ọkunrin to ba ni ibalopọ pẹlu obinrin to n ṣe nnkan oṣu lọwọ yoo ku.

Eyi si maa n mu ki ọpọ ọkọ ninu ile yẹra fun iyawo rẹ to ba n ṣe nnkan osu, yatọ si ero ti wọn tun ni pe iru obinrin bẹẹ ko mọ.

Amọ iwadii imọ ijinlẹ lode oni ti tako igbagbọ naa, to si ni ko si ewu kankan ninu ki obìnrin ni ibalopọ pẹlu ọkunrin lasiko to ba n ṣe eela lọwọ, o kan nilo ko wẹ mọ tonitoni ko to wọle tọ ọkunrin ni.

Obinrin maa n ni arun ọpọlọ diẹ diẹ lasiko nnkan oṣu

Igbagbọ karun nipa nnkan oṣu obinrin ti ko fidi mulẹ ni pe, awọn obinrin to n ṣe nnkan oṣu maa n ṣe gan gan gan fun isẹju diẹ lasiko nnkan oṣu wọn.

Idi si ree ti awọn ọkunrin fi maa n ba obinrin sere pe "ṣe nnkan oṣu rẹ tun ti de si ọ ni?"

Ṣugbọn ko si iwadii imọ ijinlẹ kankan to fara mọ ero yii, iwa abuku si ni wọn lo jẹ fawọn obìnrin.

Àkọlé fídíò, Coronavirus survivor: Àntí Korona ni wọ́n n pè mí l'ádùúgbò láti ìgbà tí mo ti ní Covid-19

Awọn ounjẹ kan wa ti obìnrin ko le ṣe lasiko nnkan oṣu rẹ

Igbagbọ kẹfa nipa nnkan oṣu obinrin ti ko tun fi idi mulẹ ni pe awọn oriṣi ounjẹ kan wa ti ko ni jinna laelae, ti obinrin to n ṣe nnkan oṣu lọwọ ba se e.

Apẹẹrẹ iru ounjẹ bẹẹ ni mọinmọin tabi ọlẹ, ti igbagbọ wa pe yoo pẹ ko to jinna tabi ko ma jinna laelae ti obinrin to n ṣe nnkan oṣu ba se e.

Amọ ko si iwadii imọ sayẹnsi tabi ẹri to daju, to fi igbagbọ yii mulẹ.

Àkọlé fídíò, Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìnira lojú àwọn ọ̀dọ́ ilẹ̀ Áfíríkà t''o ń wá ìgbé ayé rere lọ sí Yúróòpù ń rí

Obinrin le loyun to ba ni ibalopọ lasiko to n ṣe nnkan oṣu

Igbagbọ keje nipa nnkan oṣu obinrin ti ko fi idi mulẹ ni pe obinrin to ba ni ibalopọ lasiko to n ṣe nnkan oṣu le loyun.

Igbagbọ yii si ni awọn onimọ ijinlẹ sayẹnsi tako pe ko lee rí bẹẹ laelae.

Àkọlé fídíò, Coronavirus: Kí ní wọ́n ń pè ní “Herd Immunity?”