Ìjọba àpapọ̀: A óò dá ẹnikẹ́ni tó bá gbé ìwé àti àṣírí ìjọba síta lórí ayélujára lọ́nà àìtọ́ dúró

Folashade Yemi-Esan

Oríṣun àwòrán, @eniola_opeyemi

Àkọlé àwòrán, Folashade Yemi-Esan ló fi ìpè naa síta pé ẹnikẹ́ni tí ìjọba ba mú yóò fẹnu fẹ́ra

Ìjọba àpapọ̀ ni ìwé ìdáró ni òun yóò fún ẹnikẹ́ni tí aje ìwà ìbàjẹ́ gbígbé ìwé àti àṣírí ìjọba síta lórí ayélujára lọ́nà àìtọ́

Ó ní ìwé ìjọba kan tó fara han lórí ayélujára láìpẹ́ yìí níbi tí o ti fi ìwé wa wí tẹnu rẹ sọwọ́ sí akọ̀wé ilé iṣẹ́ àpapọ̀ kan jẹ́ èyí tó tini lójú gidigidi.

Olórí òṣìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ Ọ̀mọ̀wé Folashade Yemi-Esan ló fi ìpè naa síta pé ẹnikẹ́ni tí ìjọba ba mú yóò fẹnu fẹ́ra.

Ìkìlọ̀ yìí kò sẹ̀yìn ìwé ìkìlọ̀ tí wọ́n fun akọ̀wé àgbà ilé iṣẹ́ tó n rí sí ìmọ̀ sáyẹ́nsì Mohammed Bello Umar fún ríra ilé tí wọn ò kọ́ tan ni bilionu méje náírà fún ilé iṣẹ́ to n rí sí ǹkan ọ̀gbìn bo ṣe lu síta lórí ayélujára.

Olórí òṣìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ ni Umar lo mójú tó ìdúnadúrà naa lásìkò to jẹ́ akọ̀wé ilé iṣẹ́ ǹkan ọ̀gbìn

Bákan naa lo ní akọ̀wé ọ̀un tún gbé iṣẹ́ gbígbẹ́ kànga ìgbàlódé méje síta ni bilionu kan ó lé dí lọ́nà àìtọ́.

Ìdáhùn Umar tó fi ṣọwọ́ padà sí olórí òṣìṣẹ́ níbi tó ti fèsì pé irọ́ pọ́nbélé ni gbogbo ọ̀rọ̀ náà tún jẹ jáde lórí ayélujára bakan náà.

Ọ̀rọ̀ tí Ààrẹ Muhammadu Buhari kà sétí ìgbọ́ ọmọ Nàìjíríà ni ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹrin lórí ààrùn Covid19 ti ṣáájú Ààrẹ dé orí ayélujára wákàtí díẹ̀ kí Ààrẹ tó dórí afẹ́fẹ́.

Àkọlé fídíò, Coronavirus: Kí ní wọ́n ń pè ní “Herd Immunity?”

Ẹ̀wẹ̀ Yemi-Ẹsan ṣàpèjúwe àwọn ǹkan wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bíi ǹkan to burú jáì lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba tó sì pè fún yíyọ eni ti aje ọ̀rọ̀ náà bá sí mọ́ lórí ní ṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí òfin iṣẹ́ ìjọba ṣe gbe kalẹ..

Gbogbo ẹ̀ka ìjọba pátá ní ọ̀rọ̀ naa kàn.

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Nigerians Evacuated from UK: Ko tẹ́wa lọ́rùn bi ijọba ṣe ń ṣe wá

Folashade Yemi-Esan, adarí ẹ̀ka òṣìṣẹ́ tuntun tí ààrẹ Buhari yàn

Folasade Omolara Yemi-Esan

Oríṣun àwòrán, Folasade Omolara Yemi-Esan/Facebook

Àkọlé àwòrán, Folasade Omolara Yemi-Esan

Lọjọru ọsẹ ni aarẹ Muhammadu Buhari yọ adari ẹka awọn oṣiṣẹ ọba Naijiria, arabinrin Winnifred Oyo-Ita to si yan akọwe agba ile iṣẹ to n ri si ọrọ epo rọbi, Ọmọwe Folashade Esan lati rọpo rẹ gẹgẹ bii adele.

Ọmọ Yoruba ni arabinrin Folashade. Lara ohun to ṣeeṣe ko jẹ titun ti ẹ ko tii mọ nipa adele adari ẹka oṣiṣẹ tuntun ree.

  • Ọmọwe Folashade Yemi-Esan kẹkọọ gboye gẹgẹ bi akẹkọọ to fakọyọ julọ ninu imọ nipa iṣẹ abẹ eyin ni fasiti Ibadan lọdun 1987.
  • Folashade bẹrẹ iṣẹ gẹgẹ bi oṣiṣẹ́ ijọba ni ile iṣẹ to n ri si eto ilera nibi ti o ti goke titi to fi di oludari.
  • O ṣiṣẹ to fi di akọwe agba lọdun 2012 nileeṣẹ adari ẹka oṣiṣẹ ọba ni Naijiria
Àkọlé fídíò, South Africa: Àwọn ọmọ Nàìjíríà tó kù ní ìjọba SA ń kó ọ̀pọ̀ tó fẹ́ wále sí ọgbà ẹ̀wọ̀n
  • Oun lo jẹ oludari ni ẹka iroyin nile aarẹ ni olu ilu orilẹede yii laarin ọdun 2012 si ọdun 2014.
  • Bakan naa, o ṣiṣẹ gẹgẹ bi alabojuto iroyin ibudo fun iroyin ti ile iṣẹ Naijiria to wa ni orilede Abidjan, Cote d'Ivoire laarin ọdun 1992 si 1995.
  • Yemi-Esan tun ni oludari ẹka iroyin ati aṣa ni ile iṣ naijiria to wa ni Paris, France laarin ọdun 2001 si dun 2003.
Àkọlé fídíò, 'Mo fọ kọ́mú, pátá, ògiri ilé lórí 200,000 láìlèfọhùn lórílẹ̀èdè Oman'