Alaafin of Oyo: Kí ni àjọṣepọ̀ tó wà láàrín Aláàfin, àwọn olorì àti àṣà igbá títí lóde Ọ̀yọ̀?

Oríṣun àwòrán, Alaafin oyo
Yoruba ni 'Ajiṣe bi Ọyọ laa rí, Ọyọ kii ṣe bii baba ẹni kọọkan', eyi to tumọ si pe ilu Ọyọ lo n lewaju ninu agbega aṣa ati iṣe nilẹ Kaarọ o jiire.
Lara iru aṣa bẹẹ to wọpọ nilu Oyo ati ni awọn agbegbe miran nilẹ Yoruba ni Igba Titi jẹ.
- Wo ipa tí ìlànà tuntun tí ìjọba Eko gbé jáde lórí Covid-19 yóò nìí ní ìgbésí ayé rẹ
- Ìtàn ìgbé ayé Bode Thomas rèé, ó kọ́ wa láti máa kó ẹnu wa ní ìjánu
- Àwọn ọba Yorùbá kan rèé tí wọ́n rọ̀ lóyè, tí ọba míràn jẹ lójú ayé wọn
- Ṣé kí òfin kónílé -ó-gbélé kásẹ̀ nílẹ̀ ni tàbí kó tẹ̀síwájú?
- "Ọ̀pọ̀ ènìyàn tó ń gbé ní Eko, Ibadan, Osogbo ló ti kú..."
- Aláàfin gbé àṣẹ kalẹ̀ láti dènà àtúnṣẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ 'Soka'nílùú Ọ̀yọ̀
Aṣa Igba Titi yii, ti wọn tun maa n pe ni Yúgbá, lo saba maa n waye ni aafin ọba Ọyọ tabi ni aafin awọn ọba alaye miran, to fẹran aṣa ati iṣẹṣe wa.
Awọn aya ọba, ta n pe ni Olori abi Ayaba lo maa n ti igba ni aafin Ọyọ, eyi si jẹ ara ojuse pataki ti wọn gbọdọ ṣe gẹgẹ bi aya ọba.
Eroja wo ni awọn ayaba n lo lati tigba?

Oríṣun àwòrán, Alaafin of oyo
Igba orisi meji ni awọn ayaba maa n lo lati tigba. Igba akọkọ lo jẹ eyi to tobi, ti ẹnu rẹ si fẹ, eyi ti wọn yoo doju rẹ bolẹ. Irufẹ igba yii si lee to meji, mẹta tabi ju bẹẹ lọ niwaju awọn ayaba to n tigba.
Igba nla kan si lee wa laarin ayaba meji tabi ju bẹẹ lọ, ti wọn yoo maa gba a bi wọn ṣe n kọrin, tawọn miran laarin wọn yoo si maa gbe orin naa.
Igba keji ni igba to kere, ti ẹnu rẹ ko si fẹ, igba ẹlẹnu kekere yii si ni wọn yoo da ẹnu rẹ kodo sinu omi. Igi gigun meji ni ọkan ninu awọn ayaba yoo fi maa na igba kekere to wa ninu omi yii.
Ayaba to n na igba kekere ọhun ni yoo jẹ onilu fun awọn ayaba to n tigba yoku, oun naa tun ni yoo lewaju orin ti wọn n kọ, nigba ti awọn ayaba yoku yoo maa gbe e.
Bawo ni àwọn ayaba ṣe n ti gba?
Ojuse ayaba to jẹ agbalagba ninu aafin ni lati kọ awọn olori kekere ni igba titi.

Oríṣun àwòrán, Alaafin of oyo
Irufẹ agba olori bẹẹ lee jẹ obinrin ti ọba to wa lori oye naa fẹ funra rẹ abi eyi to jogun lati ọwọ awọn ọba to ti waja, to si ba ninu aafin.
Lasiko ti awọn ayaba ba n ti igba, wọn yoo fi igba nla abi kekere siwaju ara wọn, igba nla kan lee wa niwaju ayaba kan abi meji, ayaba kan si le mu igba kan siwaju ara rẹ.
Ayaba to ba si n lewaju awọn olori yoku ni yoo fi igba kekere, to dori kodo sinu omi siwaju.
Irufẹ igba nla to wa niwaju wọn bẹẹ ni wọn yoo doju rẹ de bolẹ, awọn ayaba yoo si maa kọrin bi wọn ṣe n fi ọwọ ọtun ati osi wọn gba igba naa pẹ pẹ pẹ.
Oniruuru orin to jẹ mọ oriki Alaafin to wa lori aleefa ni awọn ayaba yii yoo maa kọ, bi wọn ṣe n tigba yii, ti wọn yoo si tun maa ki ọba naa mọ awọn baba nla rẹ, tii ṣe Alaafin to ti kọja lọ.
Lara awọn orin ti wọn n kọ naa yoo dun to bẹẹ gẹ, eyi ti yoo mu ori Alaafin wu, lati dide fẹsẹ rajo.
Igba ti awọn ayaba n ti naa, lo duro fun ilu ti wọn n lu si orin abi oriki Alaafin ti wọn n kọ, bi gbogbo awọn ayaba yii si ṣe da ọwọ bo igba, ti wọn n lu u, ati asaaju wọn to n fi igi gigun meji na igba kekere to wa niwaju rẹ, ni yoo mu kawọn igba ọhun maa ro bii ilu, ni eti awọn to n gbọ.
Bi awọn ayaba naa si ṣe n tigba yii, ti inu Alaafin n dun lati jo, ni inu gbogbo ero to wa ni aafin pẹlu yoo maa dun, ti wọn yoo si maa jo.
Lasiko ti awọn ayaba ba n yungba naa, ti inu Alaafin ati awọn eeyan n dun, wọn yoo nawo fun awọn ayaba naa, ti ori wọn pẹlu yoo si wu siwaju si lati tigba, ati lati ki oriki Alaafin.
Pataki igba titi ni aafin Oyo:

Oríṣun àwòrán, Alaafin oyo
Igba titi jẹ ara ọna ti wọn n gba ṣe afẹ ninu aafin, paapaa lasiko ayẹyẹ kan, ọdun ibilẹ tabi ti Alaafin ba gba alejo pataki ti wọn fẹ fi ere da laraya.
Awọn ayaba maa n tigba lati da ọba laraya ninu aafin rẹ lasiko idunnu tabi lati tu ninu.
Igba titi ma n mu irẹpọ ati ibọwọ funra ẹni wa si aarin awọn ayaba.
Igba titi maa n jẹ ki awọn ayaba, paapaa awọn olori kekere to ṣẹṣẹ wọnu aafin, mọ si nipa aṣa ati ise ilẹ Yoruba, to fi mọ oriki Alaafin to wa lori oye ati awọn ọba to ti jẹ siwaju rẹ, eyi ti awọn naa yoo fi kọ iran to n bọ.
Awọn ayaba kii saba yọju sita ni ọjọ lasan, inu káà wọn ni wọn saba maa n wa. Sugbọn aṣa igba titi yii yoo fun wọn ni anfaani lati wọ aṣọ to jẹ oju ni gbese, to si saba maa n jẹ aṣọ ẹgbẹjọda, lati yọju sita fun ọpọ eeyan lati ri wọn
Igba titi tun n fun awọn ayaba ni anfaani lati sọrọ nipa iwa aidaa to n lọ lawujọ, ti wọn yoo si fi ewi, oriki, rara ati orin sọ ero wọn jade.
Ọ̀kan lára àwọn ọba tọ́jọ́ orí wọn dàgbà jù ní ìpínlẹ̀ Oyo ti wàjà

Oríṣun àwòrán, The Sun Newspaper
Ọba Samuel Afolabi, Onilu ti ilu Ilua ni ijọba ibilẹ Kajola nipinlẹ Oyo ti ku lẹyin aisan ranpẹ.
Ọba Afolabi jẹ ọkan lara awọn ọba ti igbagbọ wa pe o dagba ju ni ipinlẹ Oyo.
Ọjọ Satide, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Karun, ni oriade naa darapọ mọ awọn baba nla rẹ ni ipo oku, lẹyin aisan ranpẹ.
- Èsì àyẹ̀wò tí àjọ NCDC gbé síta fihàn pé ènìyàn 265 ló tún ti ní ààrùn Covid-19 ní Nàìjíríà
- Wo ohun tí a mọ̀ nípa iléeṣẹ́ "ISON Xperiences" tí òṣìṣẹ́ 78 ti kó àrùn coronavirus ní Ìbàdàn
- 'Ìbọn dún láàfin Ọ̀ọ̀ni ilé ifẹ̀ lóòtọ́, ṣùgbọ́n kò séwù'
- Òṣèré tíátà, Ọmọba Femi Oyewunmi tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Laditi ti jáde láyé
- ₦22.5M ti pọ̀ jù fún owó fọ́ọ̀mù ìdìbò abẹ́lẹ́ sípò gómìnà APC - SERAP
Iwe iroyin The Sun sọ pe ọba naa gun ori oye lọdun 1981.
Iroyin sọ pe iṣẹ agbẹ ni ọba naa n ṣe, ni ijọba ibilẹ Itesiwaju, ko to o gun ori itẹ lẹyin Ọba Majaro.













