Yoruba Films: Ọmọba Femi Oyewunmi tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Laditi ti jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Facebook/Prince Kehinde Oyewunmi
Iku n pa ni, ilẹ n jẹ eniyan. Iku tun ti mu gbajugbaja oṣere tiata, Ọmọba Femi Oyewunmi ti ọpọ mọ si Laditi lọ.
Ọrẹ oloogbe naa, Ọgbẹni Sayo Alagbe lo fidi ọrọ naa mulẹ fun ileeṣẹ iroyin BBC Yoruba.
Ọmọba Oyewunmi ni a gbọ pe o ti n ṣaisan fun ọjọ pipẹ, koda Ọgbẹni Alagbe fidi rẹ mulẹ pe o ṣiṣẹ abẹ lori ẹyin rẹ.
- Mercy Aigbe kò mọ ọ̀dá owó, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tuntun ló fà yọ lásìkò Coronavirus
- Ǹjẹ́ o mọ àwọn òṣèré bí Oyin Adejọbi, Funmi Martins àtàwọn míì tó ti dágbére fáyé?
- Mo kábàámọ̀ pé n kò kàwé, kí n tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà - Sanyeri
- Femi Adebayo di àgbà àáfà òníláwàní, Iyabo Ojo fi sìgá dárà, Allwell Ademola di ọmọdé padà, tí Wazo si bímọ tuntun
- Ẹ wo àwọn gbajúmọ̀ òṣèré tíátà tó jogún eré ṣíṣe lọ́dọ̀ òbí wọn
- Ìtàn ìgbésí ayé Oshodi, ọmọ Tápà léǹpe tó di akọni ní ìlú Eko
- Àwọn ìbejì Akeugbagold kò le rìn dáadáa mọ́ lẹ́yìn tí wọ́n dáwọn padà
O pada jẹ Ọlọrun ni pe lẹni ọdun mẹrinlelọgọta lọjọ Jimọ, ọjọ kejilelogun oṣu karun un ọdun 2020.
Oloogbe Oyewunmi kopa ninu awọn ere tiata bii Aye Toto, Koto Ọrun, Ija Eleye atawọn ere tiata.
O tun kopa ninu ere Ogun O Jalu Ogbomoṣo ki o to dagbere faye.
Ọmọba Femi Oyewumi fi iyawo ati ọmọ meje si aye lọ.








