Nollywood: Wo àwọn òṣèré tíátà Yorùbá tó ti kú àmọ́ tí iṣẹ́ wọn ń fọhùn síbẹ̀

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Aimọye awọn oṣere tiata ni irawọ wọn n tan lọwọ lọwọ, bẹẹ si ni ọpọ lawọn ti irawọ wọn ti tan sẹyin, amọ to ti wọọkun pada nitori pe wọn ti jade laye.
Ṣugbọn niwọn igba to jẹ pe, ba ku la a dere, eeyan ko sunwọn laaye, idi si ree ti BBC Yoruba fi boju wẹyin lati ṣe akọsilẹ iṣẹ awọn akọni oṣere mẹwaa to ti ku, lati fi ṣe iranti wọn.
Awọn oṣere mẹwaa to ti ku amọ ti iṣẹ wọn n fọhun sibẹ:
Oyin Adejobi:

Oríṣun àwòrán, others
Baba Oyin Adejobi jẹ agba ọjẹ oṣere tiata nigba aye rẹ, to si dabira ni agbo oṣere tiata pẹlu ọpọ awọn ere akọnilọgbọn.
Bi o tilẹ jẹ pe baba naa ni ipenija ara, ti ko si le da rin, sibẹ eyi ko ṣe idiwọ fun lati fi ipa rere lelẹ, ko to jade laye.
Lara awọn ere manigbagbe ti Oyin Adejobi ṣe ko to dagbere faye ni Orogun Adedigba, Kuyẹ, Kootu Asipa, Ọgba iwosan, Ekurọ ọlọja, Iyekan Sọja ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ọpọ oṣere tiata lo kọ iṣẹ lọdọ oloogbe Oyin Adejobi, lara wọn ni Baba Wande ati oloogbe Alabi Yellow, ti akọni oṣere naa si faye silẹ ni ọdun 2000 lẹni ọdun mẹrinlelaadọrin.
Adeyemi Afolayan (Ade Love):

Oríṣun àwòrán, Premium times
Ọdun 1940 ni wọn bi Adeyemi Afolayan, ti ọpọ eeyan mọ si Ade Love, to si jade laye lọdun 1996 lẹni ọdun mẹrindinlọgọta.
Oṣere tiata, Onkọrin, onijo oludari ati Olootu sinima ni Ade Love, to si jẹ ẹni akọkọ to ṣe fiimu jade ni Naijiria yatọ si ere itage to wọpọ nigba naa.
- 'Ọ̀rá tó tó 35,000 ni mo ṣà jọ láti fi kọ́ ilé mi yìí' - BBC News Yorùbá
- KÍ Ọlọ́run dáwọ òkú òjìji dúró lágbo èrè tíátà - Odunlade ráwọ ẹ̀bẹ̀ sí Eledumare - BBC News Yorùbá
- Baba Wande- Ìdí tí aáwọ̀ èmi àti Tunde Kelani ṣe dá -Part 2 Ti Oluwa Nile- dúró tí mi ò tún gba owó kankan lára fíìmù náà rèé
- Ẹ pàdé Manuella, ọmọ ọdún méje tó ń ṣe àkàrà òyìnbó 'cake' - BBC News Yorùbá
Ade Love to ni awọn ọmọ bii mẹrin to n ṣe ere tiata bayii, Kunle, Aremu, Gabriel ati Moji Afolayan, lo gbe ọpọ sinima jade, ko to jade laye.
Lara awọn sinima ti Ade Love ṣe, ko to silẹ bora ni Ija Ominira, Ajani Ogun, Kadara, Taxi Driver ati Iya ni Wura.
Funmi Martins:

Oríṣun àwòrán, legit.ng
Oṣu Kẹsan ọdun 1963 ni orekelẹwa Funmi Martins dele aye, to si papoda lọdun 2002 lẹni ọdun mọkandinlogoji.
Ọmọ bibi ilu Ilesa nii ṣe, to si ṣe gudu gudu meje ati ya ya mẹfa ninu isẹ tiata, lara awọn ere to ti kopa ni Ija ọmọde, ẹru ẹlẹru, Pẹlumi ati Ẹtọ mi.
Ọmọ rẹ, Mide Martins naa jẹ eekan lagbo tiata bayii, Funmi si ṣẹṣẹ bi ọmọ ti ko ju ogoji ọjọ lọ, nigba to jade laye.
Alade Aromire:

Oríṣun àwòrán, others
Ẹni ọdun marundinlaadọta ni Alade Aromire nigba to jade laye ninu ijamba ọkọ kan lopopona marosẹ Eko si Ibadan ni ọjọ kẹrin oṣu Keje ọdun 2008.
Alade si ni oṣere, oludari ati Olootu ere tiata akọkọ to ṣe ifilọlẹ ere sinima agbelewo.
Lara awọn ere sinima to ṣe nigba aye rẹ ni Ṣoṣo meji, Ọmọ inu oku, Olori, Oro Idile ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Akin Ogungbe:

Oríṣun àwòrán, Premium times
Ọdun 1934 ni Akintola Ogungbe, ti ọpọ eeyan mọ si Baba Ibeji dele aye, oṣere, Onkọrin, onijo, Olootu ati oludari ere nii ṣe ko to jade laye ni ọdun 2012.
Lara awọn ere olokiki taa mọ Akin Ogungbe mọ ni Ireke Onibudo, Asiri Baba Ibeji, Lisabi, Igba Funfun ati Ologbo Jigọlọ.
- Murphy Afolabi- Àwọn èèyàn máa ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ torí èdè ẹ̀nu mi ṣùgbọ́n bí màá ṣe sọ̀rọ̀ di ọjọ́ ikú nìyí – Murphy Afolabi,
- Murphy Afolabi- A ti na owó tótó mílíọ̀nù mẹ́wàá náírà lórí àìlera ọmọ ẹgbẹ́ - Mr Latin - BBC News Yorùbá
- Murphy Afolabi- Àwọn mọ̀lẹ́bí àti àwọn aláwo Osogbo ti kọ́kọ́ gbáradì fún ìsìnkú Murphy àmọ́ ... - Olori Ẹbi - BBC News Yorùb
Bukky Ajayi:

Oríṣun àwòrán, others
Ọmọwe ati ọlaju ni Zainab Bukola Ajayi nigba aye rẹ, o kawe nilẹ Gẹẹsi, to si tun ṣiṣẹ nileesẹ tẹlifisan NTA bii Olootu eto, ko to dara pọ mọ awọn oṣere tiata.
Bi Bukky Ajayi, to dele aye lọdun 1934, ṣe n sere lede oyinbo naa lo n ṣe ti Yoruba, lara awọn ere to ṣe, ko to jade laye ni Critical Assignments, Diamond Ring, Wiches, Iya mi tootọ, Bolode o ku, Amoye, Orere Aye ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ọjọ kẹfa oṣu Keje ọdun 2016 ni agba ọjẹ oṣere tiata naa jade laye.
Yekini Ajileye:

Oríṣun àwòrán, others
Ọmọ bibi ilu Osogbo ni Alhaji Yekini Ajileye, ti ọpọ ere rẹ si maa n da lori ihuwasi awọn ajẹ, ati iṣẹ ibi ti wọn n ṣe.
Lara awọn ere to ti ṣe ni Koto Aye, Koto Ọrun, Ide, Ẹran Iya Osogbo, Aye Alaye ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Oṣu Kẹwa ọdun 2006 ni agba oṣere naa dagbere faye lasiko aisan oṣu mẹta to ṣe.
Lukuluku Bantaṣi:

Oríṣun àwòrán, others
Adẹrinposonu ati alawada gidi ninu ere tiata ni Lukuluku Bantasi, ẹni to ki aye pe o digbose lọdun 1995.
Lukuluku, ẹni to jẹ irọ̀ awọn alawada bii Baba Suwe lagbo tiata, lo kopa ninu ọpọ ere bii Legal Wife, Ami ọrun, Itunu ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Isola Ogunsola, I Show Pepper:

Oríṣun àwòrán, others
Agba ọjẹ oṣere tiata ni Olusola Isola Ogunsola, ti ọpọ eeyan mọ si I Show Pepper nigba aye rẹ, o si jẹ ọmọ bibi ilu Abeokuta.
Onkọrin, onilu, onijo, Olootu ati oludari ere ni I Show Pepper, to si ṣe awọn ere bii Iyawo Alalubosa, Efunsetan Aniwura, Alaafin Aganju, Fere bi Ekun, Eru Jẹjẹ, Ko see gbe, Ọmọ laja ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ogunsola dagbere faye lọdun 1992 lẹni aadọta ọdun, to si fi ọpọ iyawo ati ọmọ saye lọ.
Duro Ladipo:

Oríṣun àwòrán, dawn commission
Akọni oṣere tiata, Onkọrin ati onijo ni Durodola Ladipo, ti ọpọ eeyan tun n pe ni Sango.
Ọdun 1931 ni Duro dele aye, o ṣe bẹbẹ lagbo tiata, to si gbe ere itage de ilu oyinbo ko to papoda lọdun 1978 lẹni ọdun mẹtadinlaadọta.
Lara awọn ere to ṣe, ko to silẹ bora ni Ọba Koso, Ọba Waja, Ṣango ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Diẹ lara awọn oṣere tiata to ti di ara ilẹ ree, ta si n ranti iṣẹ ọwọ wọn, a wa gbadura pe ki Ọlọrun tubọ dẹ ilẹ fun gbogbo awọn oṣere tiata to ti dagbere faye.












