'Ọ̀rá tó tó 35,000 ni mo ṣà jọ láti fi kọ́ ilé mi yìí'
'Ọ̀rá tó tó 35,000 ni mo ṣà jọ láti fi kọ́ ilé mi yìí'
Arakunrin Gary Bencheghib bẹrẹ eto kólẹ̀-kódọ̀tí ati ipolongo, to pe ni Sungai Watch, lati maa ko gbogbo awọn ike ati ọra to n ṣan sinu odo ni orilẹ-ede Indonesia, paapaa ni agbegbe Bali ati Java.
O le ni miliọnu tọọnu idọti ti awọn eeyan jù sọnu ni orilẹ-ede naa, lọdun 2021 nikan.
Inu òkun ati awọn odò mii si ni wọn n pada si.
Ọgbẹni Bencheghib fi ọra to ṣa jọ kọ ile to n gbe.
Arakunrin naa sọ fun BBC pe ọra to to ẹgbẹrun lọna marundinlogoji ni oun fi kọ ile naa.
Ile alarabara yii ni ibusun, ile idana, baluwẹ ati awọn nnkan amayedẹrun mii to nilo.
O ni oun fi ọra kọ ile oun lati fihan pe awọn ọra ti "a n ṣà ninu odo le wulo fun awọn nnkan mere-mere mii".



