Wo bí o ṣe lè lo ẹ̀rọ ìgbàlódé, 'App' tí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo gbé kalẹ̀ láti mójútó ètò kólẹ̀-kódọ́tí

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/other
Ijọba ipinlẹ Ọyọ ti ṣe agbekalẹ ohun elo igbalode lori ẹrọ ilewọ, 'App' ti yoo sọ amojuto itọju ayika di irọrun.
Agbekalẹ ohun elo ori ẹrọ ilewọ yii lati ọwọ ileeṣẹ to n ṣe amojuta imọtoto ayika fun ijọba ipinlẹ Ọyọ, 'Mottainai Recycling' yoo mu ki awọn ilẹẹṣẹ kolẹ-odọti ti ijọba buwọlu lu ati awọn eeyan ilu le palẹmọ idọti ati ẹgbin ni irọwọrọsẹ.
Alamojuto agba fun ileeṣẹ naa, Ms. Uloma Airhienbuwa ṣe alaye wi pe agbekalẹ ohun elo igbalode naa lo ni ifojusun lati mu ki imọtoto ayika di irọrun n'ipinlẹ Ọyọ.
O ni ohun elo naa yoo mojuto lilọbibọ panti ati ẹgbin, ti yoo si jẹ ki o ṣeeṣe lati mọ odiwọn idọti ti ileeṣẹ kolẹ-kodọti ko ati ibi ti wọn ti koo.
Bawo ni awọn eeyan ilu ṣe le gba ohun elo yii si ori ẹrọ ilewọ wọn?

Oríṣun àwòrán, other
Alaye ti Arabinrin Uloma Airhienbuwa ṣe ni pe gbogbo eeyan lo le gba ohun elo naa si ori ẹrọ ilewọ wọn lati ori atẹ fun awọn ohun elo ori ẹrọ ilewọ ti a mọ si, 'Google Playstore(gbogbo foonu lo ni atẹ yii yatọ si Iphone).
Orukọ ti wọn a fi wa ohun elo naa lori atẹ 'Google Playstore' ni, 'Mottainai- Waste & Recycling'.
Ọfẹ si ni wọn o gbaa lori atẹ naa.
Lẹyin ti ẹni ti o ba fẹ lo 'app' naa ba ti gbaa si ori ẹrọ ilewọ rẹ, yoo ṣe iforukọsilẹ ati ipese awọn idahun si ibeere mii bii orukọ nọmba ile, oruko agbegbe, adugbo ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Lẹyin eleyii ni ẹni ti o ba gba ohun elo yii si ori ẹrọ ilewọ rẹ yoo lanfani lati maa ri asiko ti ileeṣẹ kolẹ-kodọti yoo ko idoti adugbo wọn, ati orukọ ileeṣẹ ti yoo ko idọti naa. Bakan naa ni yoo ni anfani lati san owo fun ileeṣẹ naa lori ohun elo igbalode yii.
Ti idoọti ba ti pọju ki asiko ti o yẹ ki ileeṣẹ akodọti wa to pe, a le fi 'app' ke si wọn lati wa ko idọti to n bẹ ladugbo.
Igbagbọ ijọba ipinlẹ Ọyọ ni pe igbesẹ yii yoo mu adinku na panti ati ẹgbin to n da idọti silẹ layika.












