'Ọdún 500 sẹ́yìn ni ọmọ Ọba Aláàfin Oyo tẹ ìlú Ondo dó'
Ondo Ekimogun, Ọmọ amula meji oju ṣẹyẹ
Ọmọ amu agogo mu omi, ọmọ alade meji l'Ondo
Ọmọ lade mu, ọmọ alade ude,
Ondo mẹta, ula mẹta, Ondo mẹfa, ula mẹfa...
Bẹẹ ba n gbọ oriki yii, wọn a maa pe Ondo lẹ n ke si un.
BBC Yoruba rinrinajo lọ si ilu to n jẹ Ondo gangan ninu ipinlẹ Ondo lati mọ bi wọn ṣe tẹ ilu naa do.
Ilu yii ni ilu keji to tobi ju ni ipinlẹ Ondo.


Ọpọlọpọ eeyan jankan jankan ni Naijiria wa lati ilu Ondo bii ilumọọka agbẹjọro agba nni, oloogbe Gani Fawehinmi, Gomina Ondo tẹlẹ, Olusegun Mimiko, gbajumọ oṣerebinrin, Bimbo Oshin ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ẹwẹ ninu itan gẹgẹ bi ọkan lara awọn oloye ilu naa, Oloye Olasanya Akingbemi ṣe ba BBC Yoruba sọ, o fihan pe nnkan bii ẹẹdẹgbẹta ọdun sẹhin ni wọn ti tẹ ilu Ondo do.
Wọn tun ni "Ọbabinrin Pupupu" lo tẹ ilu Ondo do ati pe ọmọ Ọba Alaafin igba naa ni.







