Ta ló fi àlòkù kọ́ńdọ́mù ránṣẹ sí obìnrin akẹ́kọ̀ọ́jáde 65? Ọlópàá n ṣewádìí

Oríṣun àwòrán, NLD.COM.VN
O tọ ka yannana ọrọ wipe awọn akẹkọọ to pari ẹkọ wọn ni ile ẹkọ kanna ni wọn fi kọndọọmu ranṣẹ si.
Kii ṣe awọn eleyi to ṣi wa nile ẹkọ lọwọlọwọ.
Eyiuun wa lẹgbẹ kan naa.
Iwadii awọn ọlọpaa Melbourne ni Australia ti bẹrẹ lati mọ alaburu to fi aloku kọndọọmu ranṣẹ sawọn akẹkọọ jade obinrin marundinlaadọrin.
Wọn fi awọn kọndọọmu yi ṣọwọ ninu akoto iwe ti wọn si kọ ọrọ ranṣẹ pẹlu wọn.
Awọn ọlọpaa lawọn fura si pe awọn ti iṣẹlẹ yi kan wa lara ọpọ eeyan ti alaburu yii foju si lara.
Gbogbo awọn obinrin taa n wi yi jijọ kẹkọ jade ni ile ẹkọ Kilbreda College lọdun 1999.
Pupọ ninu wọn gba lẹta ọran ọpọlọpọ aloku kọndọọmu ni.
Awọn oluwadii n ṣe ayẹwo DNA lati le mọ ẹni to wa nidi iwa buruku yii gẹgẹ bi ọlọpaa to n lewaju iwadii naa Sajẹẹnti agba Grant Lewis ti ṣe sọ.
Bawo lo se ri adirẹsi wọn ko jọ?

Oríṣun àwòrán, WIKIPEDIA COMMONS/ANDREW OWENS
Iwadii sọ pe ninu iwe ipari ẹkọ ọlọdọọdun taa mọ si "year book" tawọn akẹkọọ yii ko orukọ ati adirẹsi si lọdun mẹrinlelogun sẹyin lo ti ri iroyin nipa wọn.
O fi ọwọ kọ awọn kan ninu awọn lẹta to kọ si wọn ti o si tun fi kọmputa tẹ awọn mii.
Ṣugbọn gbogbo awọn lẹta yi lo kọ ọrọ alufansa sinu rẹ.
Ọga ọlọpaa to n ṣe iwadii ọrọ yi wa fi ikilọ ranṣẹ pe alaburu yii ''ni lati dẹwọ iwa buruku to n hu ati pe awọn yoo ṣawari rẹ''.
''A ko mọ nkan to so oun ati awọn akẹkọọ yi pọ. O ṣeeṣe ki o jẹ oṣiṣẹ ile ẹkọ yii nigba kan ri ni tabi akẹkọọ to pari ẹkọ nibẹ. O si le jẹ ẹni to ri iwe ipari ọlọdọọdun yii he to si bẹrẹ si ni fi ṣe ere kere''.
Pupọ awọn obi awọn akẹkọọ tẹlẹ ri yi lo gba awọn lẹta taa n sọrọ nipa rẹ yii.
Ohun to ba ni ninu jẹ si lo jẹ fawọn obi wọn lati ba aloku kọndọọmu ninu lẹta ti wọn kọ si ọmọ wọn.
Ọkan ninu awọn ti ọrọ kan Bree sọ pe awọn obi oun lo ṣi lẹta yi.
A fi orukọ bo ẹniyi laṣiri la fi pe ni Bree.
''Mama mi jaya pupọ nigba ti wọn ri lẹta yii, bẹẹ naa ni baba mi. Wọn bẹrẹ si ni jaya boya eeyan kan lo fẹ ṣe mi ijamba''.
Awọn ọlọpaa ti rọ ẹnikẹni to ba ni iroyin nipa iṣẹlẹ yii ko tara wa lati bun awọn gbọ.
Ile ẹkọ ti wọn ti kẹkọ jade naa n ba ọlọpaa ṣiṣẹ lati tu iṣu de isalẹkoko ọrọ yii.












