Sexually transmitted diseases: Kọ́ńdọ́mù 587 mílíọ̀nù lọmọ Nàìjíríà ń lò lọ́dún

Aworan condom

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iwadii kan ti ajọ Aids Healthcare center gbe jade ni ifọwọsowọpọ pẹlu ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun AIDS, NACA ati NOIPolls ti fihan pe ọrinlelẹẹdẹgbẹta o le meje rọba idaabobo condom lawọn ọmọ orilẹede Naijiria n lo lọdun.

Amọṣa iwadi naa tun jẹ ko di mimọ pe bilisnu kan o le aadọja miliọnu rọba idaabobo kọndọọmu lorilẹ-ede Naijiria nilo lọdọọdun lati lee dẹkun ọwọja arun ibalopọ lorilẹede Naijiria.

Awọn ajọ naa tun fi idi iwadii wọn mulẹ peiye alafo to wa laarin iye to wa nilẹ ati iye ti orilẹede yii nilo jẹ ọtalelẹẹdẹgbẹta ati mẹrin, 564.

Àkọlé fídíò, Oladele Ogbeyemi Albert: Irin tí mò ń lò máa ń bá mi sọ̀rọ̀ nínú ẹ̀mí kí ń tó gbẹ́ wọn sóh

Iwadii ijinlẹ naa tun sọ ọ di mimọ pe awọn eeyan ẹkun aringbungbun ariwa (North Central), aringbungbun guusu (South-south) ati ariwa gusu (South east) orilẹede Naijiria lo n lo kọndọmu julọ.

Bakan naa lo tun fi kun un pe awọn ọkunrin n lo kọndọmu ju awọn obinrin lọ.

Àkọlé fídíò, Lori iro: Ká ni àwọn Òbí mi gbà fún mí, èmi àti Sunny Ade á jọ máa 'Compete- Baba Lórí ir