Texas weather: Ìjì òtútù pa èèyàn 21 ní Amẹ́ríkà, ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ míràn ń dojúkọ ìṣoro àìsíná ẹ̀lẹ́ńtíríkì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iji nla kan to la gusu orilẹ-ede Amẹrika kọja ti ran eeyan mọkanlelogun lọ sọrun, o si ti gba anfani ina mọnamọna lọwọ ọkẹ aimoye miliọnu awọn eeyan nibẹ.
Ko sina ni ilu Texas pẹlu bi awọn olugbe ibẹ ṣe n wa ina lati fi seto ooru fun ara wọn.
Ọpọ awọn olugbe ipinlẹ naa lo n pariwo pe awọn ko ri iru otutu bayii ri.
Ohun ti awọn onimọ nipa oju ọjọ sọ ni pe o ṣeeṣe ki oju ọjọ ri bi o ṣe ri yii titi di opin ọsẹ yii.
Nitori iji otutu yii, awọn eeyan ti ku ni Texas, Louisiana, Kentucky, North Carolina ati Missouri.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ to n mojuto ọrọ nipa oju ọjọ ni orilẹ-ede Amẹrika ti ṣalaye pe iye awọn ọmọ orilẹ-ede naa to wa labẹ ijamba iji otutu bayii le ni aadọjọ miliọnu.
Iji otutu naa tilẹ tun de Mexico nibi ti omilẹgbẹ awọn eeyan ko ti ri ina mọnamọna to ja geere lo.
Gẹgẹ bi iroyin lati orilẹ-ede naa ṣe sọ, pupọ awọn to ku lo jẹ wi pe afẹfẹ oloro Carbon monoxide lo pa wọn nibi ti wọn ti tan mọto wọn silẹ ninu ile lati lee fi dooru mu ara wọn.
Bakan naa lawọn miran tun kagbako iku nipasẹ ijamba mọto.
Awọn majẹ-o-bajẹ nibẹ ti n kọminu pe eyi lee fa ọpọlọpọ wahala fun ilera ilu.

Bawo ni Texas ṣe n fara gba otutu yii si bayii?
Bii miliọnu mẹrin eeyan ni Texas ni ko ri ina mọnamọna lo, awọn bii miliọnu kan ati aabọ miran si tun kun wọn ninu iriri ati iṣoro yii ni Houston.
- Kílódé tí àwọn èèyàn ṣe ń gbé òkú pamọ̀ sílé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ní ìlú yìí?
- Ìrọ́ ní ò, a o fí ìgbà kankan fí Olupelumi Fagboyegun, Ìbátan Akeredolu sí ẹ̀wọ̀n- Iléẹ́jọ́ ìpínlẹ̀ Ondo
- Ọwọ́ tẹ Sani fọganáísà tó fipá bá ọ̀dọ́mọbìnrin ẹni ọdún 15 lò pọ̀ tó fi kú
- Wo àwọn ohun méje tó yẹ kí o mọ̀ nípa Ngozi Okonjo-Iwealla àti ọkọ rẹ̀ Ikemba
- Agbaṣẹ́ṣe jẹ búlálà méjìlá lẹ́yìn tó jí ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀


















