Death, Living with the dead in Torojan: Kílódé tí àwọn èèyàn ṣe ń gbé òkú pamọ̀ sílé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ní ìlú yìí?

Oku

Nilu yii, ki lo mu awọn eeyan maa gbe oku pamọ sile fun ọpọ ọdun ?

Wo bi awọn ara ilu yi ti se n tọju oku sinu ile fun ọpọ ọdun.

Yoruba bọ, wọn ni ida ilu ni iṣe ilu.

Ohun to si kọju si ẹnikan, ẹyin ni wọn ni o kọ si ẹlomiran.

Eleyi lo difa fun awọn ara ilu kan lorile-ede Indonesia to se wi pe kaka ki wọn sin oku lasiko, wọn a maa gbe oku pamọ si ile ti wọn a si maa tọju rẹ bi igba to wa laye.

Isesi yi wa laarin awọn eeyan to n gbe lagbegbe Toraja ni iwọ oorun Indonesia.

Lati ọwọ awọn babanla wọn ni wọn ti kọ ise yi ti wọn a si maa tẹsiwaju pẹlu rẹ titi di ode oni.

Bi eeyan ba ku lọdọ wọn, o le to ọpọ osu koda wọn a maa se ọdun pupọ ki isinku to waye.

oku

Ni ilẹ kaarọ o jiire wa nibi, awọn eeyan a maa se asa bi ayẹyẹ isinku eyi taa ma mu kawọn mi gbo oku pamọ si aaye igbokupamọ si ki wọn to dajọ isinku.

Lọdọ awọn eeyan Toraja yi, kaka ki wọn gbe oku pamọ si mọsuari, inu ile ni wọn maa n gbe oku pamọ si ti wọn a si maa tọju oku naa bi igba to wa laye.

Àkọlé fídíò, Lori iro: Ká ni àwọn Òbí mi gbà fún mí, èmi àti Sunny Ade á jọ máa 'Compete- Baba Lórí ir

Lara nkan ti wọn maa n se ni pe:

•Wọn a maa tọju oku bi igba pe wọn n se'tọju alaarẹ

•Wọn maa n gbe ounjẹ,nkan mimu to fi mọ siga wa fun oku lẹẹmeji lojumọ

oku

•Iwẹ loore koore ni wọn maa n wẹ awọn oku yi ti wọn a tun parọ asọ fun wọn

•Koda awọn oku ni abọ igbọnsẹ ti wọn gbe silẹ fun wọn lẹgbẹ kan inu ile

Àkọlé fídíò, Ẹ̀yin olórin ẹ̀mí tó ń bóra, lo èékáná gígùn, oò yàtọ̀ sí aṣẹ́wó hòtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n ń gbé bíi súùtì Pepper Menti - Bola Are

Yatọ si gbogbo awọn nkan ti a ti darukọ yi, wọn kii pa ina inu iyara ti oku ba wa.

Ero ọkan awọn mọlẹbi oku yi ni pe ti awọn ba fi oku naa silẹ ninu okunkun laitọju, ẹmi awọn oku yi ko ni jẹ ki awọn mọlẹbi gbadun lẹyin iku wọn.

Laye atijọ, ewe ati egbo ni wọn maa fi n tọju oku nilu yi sugbọn lode oni, kẹmikaa fọmalin ni wọn fi n tọju oku.

oku

Ohun ti eyi maa n dasilẹ ni pe lọpọ igba ni inu ile awọn ara ilu yi ma n run fun kẹmika.

Arabinrin kan ti akọroyin wa kan si nile rẹ salaye pe nise lo da bi pe baba oun si wa laye .

Mamak Lisa sọ pe ''awọn mọlẹbi a si maa pe lori ago lati beere alaafia baba mi''

''Igbagbọ wa ni pe baba wa si n gbọ wa o si yi wa pẹlu wa''

Ninu ise awọn Torajan, wọn a maa sise karakara lati le fi ko ọrọ jọ.

Sugbọn ọrọ yi kii se ki wọn le gbe aye irọrun bi kii se ki wọn le se idagbere ikẹyin faye.

Bi awọn Yoruba ti wọn a maa file pọti fọna roka, awọn Torajan a maa se eto isinku alarinrin.

Amọ saaju ki wọn to dagbere fun oku, wọn a se ipalẹmọ ẹmi ati owo.

Bi asiko ba ti ya, nise ni wọn maa n dana rẹpẹtẹ ti wọn a si pero pupọ wa sibi isinku .

oku

Ninu igbgbọ wọn, ayẹyẹ isinku ni ibẹrẹ irinajo oku lọ si alakeji nibi ti wọn a ti tun sọ ẹmi yi ji pada wa saye.

Lọdọ wọn,inu ẹranko ẹfọn ni ẹmi awọn to ba ti ku maa n gbe pada.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa lori BBC: Olùkọ́ Bolanle Adekanmi kọ́ wa nípa oríṣíi Àròkọ Yorùbá tó wà

Idi ree ti wọn fi maa n pa ọpọlọpọ ẹfọn lati fi se isinku mọlẹbi wọn.

Ọpọlọpọ ninu wọn , owo ti wọn ba ko jọ, isinku ni wọn ma fi n se.

Bi ẹni to ba ku ba ti se lọla si nigba to ba wa laye, bẹẹ ni isinku rẹ yoo ti se larinrin si.

A gbọ pe isinku arakunrin kan to gbajumọ nilu wọn, owo ti wọn fi se oku le ni ẹgbẹrun lọna aadọta dọla eyi to fẹẹ to miliọnu meji naira.

Nibo ni wọn n sin oku si lẹyin ayẹyẹ?

Ibi tọrọ ku si re:

Awọn eeyan Toraja kii sin oku sinu ilẹ bi awọn Yoruba.

Lẹyin isinku alarinrin ti wọn fi dagbere fun oku, ohun to tẹlẹ ni pe wọn yoo gbe oku naa pamọ sinu apata.

oku

Oríṣun àwòrán, Mamak Lisa

Bi eeyan ba wọ inu awọn apata tabi aja ilẹ to pọ lagbegbe naa, yoo ma ri awọn posi ati oku ti wọn gbe pamọ sinu ibẹ.

Ko tan sibẹ, awọn mọlẹbi a tun ma gbe owo ati siga wa fun awọn oku ki wọn ba le gbadun igbe aye wọn tuntun.

oku

Ohun ta ri kọ ninu eto isinku awọn eeyan Toraja yi ni pe jakejado agbaye ni a ti maa n se iranti oku.

Ti ti wọn kan peleke ju tara yoku lọ ni.