Nigeria Army recruitment 2021: Àlàkalẹ̀ rè é láti darapọ̀ mọ́ ìkọ̀ ọmọogun Nàìjíríà

Nigeria Army

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army/Facebook

Ileeṣẹ ọmọogun Naijiria ti ṣi oju ọpọ silẹ lati Ọjọ Karundinlogun, Oṣu Kini, ọdun 2021 fun ẹni to ba fẹ darapọ mọ wọn.

Awọn oṣiṣẹ karakata ati awọn eleyii ti kii ṣe karakata naa ni yoo le fi orukọ silẹ.

Ileeṣẹ ọmọogun ni oju opo Twitter wọn ni awọn ti wọn ba mu yoo kọkọ ṣe idanwo lori ẹrọ kọmputa wọn.

Ninu atẹjade naa ni ileeṣẹ ọmọogun fi lede ọna ti wọn yoo gba fi orukọ silẹ.

Bi o ṣe le fi orukọsilẹ re e:

  • Lọ si oju ọpọ https://recruitment.army.mil.ng
  • O nilo Username ati Password lati wọ oju opo naa
  • Lẹyin iforukọsilẹ naa, 'print' ẹ jade ki o si lọ fun awọn oniduro rẹ
  • Ri daju wi pe o mu lẹta iforukọsilẹ rẹ pẹlu ti awọn oniduro rẹ dani lọ si ojuko idanwo naa.
Àkọlé fídíò, Ẹ̀yin olórin ẹ̀mí tó ń bóra, lo èékáná gígùn, oò yàtọ̀ sí aṣẹ́wó hòtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n ń gbé bíi súùtì Pepper Menti - Bola Are

Ki ni awọn ilana to gbọdọ ni lati fi orukọ silẹ

  • Awọn olukopa gbọdọ jẹ ọmọ orilẹede Naijria, o si gbọdọ ni paali idanimọ
  • Olukopa gbọdọ pe ni ara, ilera ati ọkan
  • Olukopa ko gbọdọ ni akọsilẹ gẹgẹ bi ọdaran.
  • Gbogbo awọn olukopa gbọdọ ni esi idanwo WASSCE/GCE/NECO/NABTEB, ti ko ju ijoko eemeji lọ pẹlu 'credit 4', lai yọ ẹkọ imọ Ede Gẹẹsi kuro.
Àkọlé fídíò, Bí àlááfíà yóò ṣe wà láàrin Fulani àti Yorùbá ni Ooni bá lọ sọ́dọ̀ Buhari- Ààfin Ile Ife
  • Awọn to fẹ ṣiṣẹ gẹgẹ bi onibara gbọdọ ni sabuke ''Trades Test/City Guild'', pẹlu ọpọlọpọ alaye loju opo wọn.
  • Olukopa ko gbọdọ ju ọdun mejidinlogun si mejilelogun lọ, amọ awọn to fẹ ṣiṣẹ gẹgẹ bi awọn onibara gbọdọ jẹ laarin ọdun mejilelogun si ọdun mẹrindinlọgbọn lasiko ti igbaradi yoo bẹrẹ ni Ọjọ Kọkandinlọgbọn, Osu Karun un, ọdun 2021.
  • Olukopa ko gbọdọ kere ju iwọn ẹsẹ 1.68 metre ati 1.62 metre fun obinrin ati ọkunrin.
Àkọlé fídíò, Lori iro: Ká ni àwọn Òbí mi gbà fún mí, èmi àti Sunny Ade á jọ máa 'Compete- Baba Lórí ir

Awọn ohun miran to yẹ ki ẹ mọ

Ileeṣẹ ọmọogun Naijiria yoo fi orukọ awọn ti wọn ba mu lasiko iforukọsilẹ si oju opo Nigerian Army website.

Awọn ti wọn ba mu naa yoo lọ ṣe idanwo ni ipinlẹ wọn ni Ọjọ 12 to 26 April, 2021.

Nigeria Army

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army/Facebook

Ileeṣẹ Naijiria ni gbogbo sabuke ti awọn eniyan ba fi silẹ ni awọn yoo wo finifini, amọ ẹni to ba mu ayederu esi wa yoo foju wina ofin.

Àkọlé fídíò, Ondo Fulani Herdsmen: Àgbe mẹ́ta ní àwọn Fulani darandaran tún pa Ọ̀wọ̀, Ondo