Ronke Odusanya: Àwọn olólùfẹ́ Ronke Odusanya Ìdídowó ti ń fọnmú lórí àṣẹ àyẹ̀wò DNA tí iléẹjọ́ pa lórí ọmọ tó bí fún Saheed

Ronke odusanya

Oríṣun àwòrán, Instagram/ronkeodusanya

Ile ẹjọ Majistreti kan nilu Eko ni iroyin sọ pe o ti paṣẹ pe ki wọn lọ ṣe ayẹwo tani baba ọmọ, iyẹn DNA test fun ọmọbinrin ti eekan oṣere Ronkẹ Odusanya ti ọpọ mọ si ididowo bi fun ọkọ rẹ.

Gẹgẹ bi awọn iroyin iwe iroyin abẹle kan ṣe gbe, adajọ Majistreti M. O. Tanimọla paṣẹ naa larin ọsẹ to kọja nigba ti wọn gbe ẹjọ naa wa siwaju rẹ.

Ọlanrewaju Saheed to jẹ ọkọ Ronkẹ Odusanya rọ ile ẹjọ naa lati paṣẹ fun ayẹwo DNA naa lati mọ boya lootọ oun ni baba ọmọ naa nitori oun n funra pe irin ẹsẹ iyawo oun ko mọ.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, agbẹjọro fun Ronkẹ ididowo ko ba a jiyan lori rẹ, nitori oun naa gba bẹẹ pe ki wọn ṣe ayẹwo naa.

Bayii ti ile ẹjọ naa si gba lati ṣe atọna ayẹwo ọhun ni ileewosan ti wọn ko ni darukọ nibi ti wọn yoo si ti fi esi rẹ ṣọwọ si ile ẹjọ naa taara.

Ọdun kan ati oṣu diẹ sẹyin ni Ronkẹ Odusanya bi ọmọbinrin rẹ nileewosan kan loke okun.

Ronke odusanya

Oríṣun àwòrán, Instagram/ronkeodusanya

Ki lawọn eeyan n sọ lori rẹ?

Amọ bayii awọn ololufẹ elere itage naa ti n fọnmu lori rẹ.

@hotyjay ni "Ọmọ jọ ẹ bayii o si tun n wa ayẹwo DNA? O dara o, ohun oju rẹ n wa, yoo rii o."

@Studedsavage ni tirẹ kọ pe " Ọmọ ti mo rii yii jọ baba rẹ bi imumu ni o.

O fẹ fi iwọnba owo to ku ti Ronkẹ ko tii gba ṣofo leyi o."

@kxngrivo ni tirẹ kọ wi pe, "O san ni kiakiao, mo ti ri ọkunrin kan to jẹ wi pe mẹrin ninu awọn ọmọ rẹ ni kii ṣe tirẹ.

Bẹẹ, eyi to kere ju ninu wọn, ọmọ ọdun mejidinlọgbọn ni. bawo ni baba ẹni ọdun marundinlaadọrin tun aye rẹ to o.

Yara tete ṣe e bayii o arakunrin mi."

@marigoldconcepts, " ka maa wulẹ bopo lọle olooro lori ayẹwo DNA o, ẹda baba rẹ ni ọmọdebinrin yii o"

Àkọlé fídíò, Ẹ̀yin olórin ẹ̀mí tó ń bóra, lo èékáná gígùn, oò yàtọ̀ sí aṣẹ́wó hòtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n ń gbé bíi súùtì Pepper Menti - Bola Are