Itan Manigbagbe: Olorì Luwoo, Gbàgìdí jẹ́ obìnrin tó ṣáájú àsìkò rẹ̀ jẹ Ooni Ife tó sì tún jẹ́ alágbára gidi nílẹ̀ Yorùbá

Olori Luwoo

Oríṣun àwòrán, others

Olorì Luwoo, Gbàgìdí jẹ́ obìnrin tó ṣáájú àsìkò rẹ̀ jẹ Ooni Ife tó sì tún jẹ́ alágbára gidi nílẹ̀ Yorùbá

Olorì Luwoo, Gbàgìdí jẹ́ obìnrin tó ṣáájú àsìkò rẹ̀ jẹ Ooni Ife tó sì tún jẹ́ alágbára gidi nílẹ̀ Yorùbá.

Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ṣe sọ ó rẹwà púpọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìtàn ṣe sọ, ẹwà yìí a sì máa jẹ́ ìwúrí fún pẹ̀lú.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtàn to pọ̀ lóde kò fi bẹ́ẹ̀ dárúkọ rẹ̀, nítorí pé ìtàn àtẹnudẹ̀nu ló pọ̀jù nínú ìtàn orile-ede Naijiria, ọ̀pọ̀ sí ló máa ń sọ ìtàn bí ẹni pé ọkùnrin nìkan ló n jẹ Ooni Ife.

Luwoo jẹ́ ọba Ọ̀ọ̀ni ìkọkanlélógún ni sẹ́ntúrì kẹwàá, òun ló jẹ lẹ́yìn ọba Gẹ̀ẹ́sì ti Ọ̀ọ̀ni Lumobi sì jẹ lẹ́yìn rẹ̀.

Nínú àkọsílẹ̀ kan, a gbọ́ pé wọ́n n pè é ní Luwoo Gbàgìdí nítorí o jẹ́ ọmọ bíbí Otaataa láti ìdílé Owode Okerewe, ó sì fẹ́ olóyè Obaloran ti Ilode, Elédùà fi Adekola Telu tó jẹ́ ẹni tó tẹ ìlú Iwo dó.

Lẹ́yìn ti Ọ̀ọ̀ni Geisi kú, òun ni obìnrin láti gorí àpèrè gẹ́gẹ́ bí Ọ̀ọ̀ni.

Nítorí pé Ọ̀ọ̀ni yìí rẹwà púpọ̀, tí èyí si máa n mú inú rẹ̀ dùn ní gbogbo ìgbà mu ki àwọn ará ìlú Ife àti ọkùnrin àti obìnrin máa sapá wọ́n láti mu kí àyíká wọ́n rẹwà gidi kí ó sì dùn wò.

Àkọlé fídíò, Akure incest Momoh Usman case: Láti ẹni ọdún mẹ́tàlà ni Bàbá mi ti ń ba mi sùn- Fatimah Us

Nítorí pé Ọ̀ọ̀ni Luwoo ko fẹ́ràn láti máa tẹ iyanrìn lásán, nítorí rẹ̀ ló ni kí wọ́n ṣe àwọn pèpéle (ó ti di ti àwọn ilé ìkó ǹkan ìṣẹ̀mbáyé Ife si),pẹ̀lú àwọn ǹkan ọ̀gbìn tó rẹwà láti fi mú àyíká rẹ̀ dùnwò.

Àkọlé fídíò, Ìtanijí lórí BBC Yorùbá: Odú Iwori Obara bá wa sọ̀rọ̀ lórí ìfaradà tó pọ̀

Lílo àwọn iṣẹ́ ọ̀nà amọ̀ láti fi ṣe àyíká rẹ̀ lọ́jọ́ àti gbogbo ilẹ̀ Yorùbá to bá ṣe àbẹ̀wò sí jẹ àbùdá adámọ́ tí wọ́n mọ̀ ọ́ sí.

Bákan náà lo má n ló o láti fi jẹ́ ẹnikẹ́ni to ba rúfin níyà láti ṣe Irúfẹ́ rẹ̀ sí àwọn òpópónà ilé ìfẹ́ pẹ̀lú òkúta akọ àti àwọn afọ́kù kòkò amọ̀.

Àkọlé fídíò, Big breast: Oluwatosin Adegboro, Oluwaseun Amoo, Remi Fatolu: Ẹlòmíì ń fi irú ọyàn wa tọrọ

Àwọn tó bá jẹ́ ọmọ ìta ló máa ń lò láti sún amọ̀ tí yóò sì ni kí wọ́n fi ọwọ́ wọn lásán fọ́ọ pada, wọ́n yóò wá tòó sí ojú ọ̀nà tí Ọ̀ọ̀ni yóò gbà kọjá.

Yàtọ̀ sí èyí ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ni fáwọn ọkùnrin nítorí ìtàn sọ pé, ó kórira ọkùnrin tó bá n ṣe ìmẹ́lẹ́ tó tú n rúfin.

Láyé Luwoo, kò sí ìyàtọ̀ nínú ẹrú àti ọmọ, bákan náà ni ó ṣe máa n ṣe sí wọn.

Àwọn àgbààgbà ìlú rí wípé apá ò ká Luwoo mọ́, o si tún jẹ́ apàṣẹ wàá, wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ lẹ́yìn tí àsìkò tirẹ̀ parí pé obìnrin kankan kò ní jẹ Ọ̀ọ̀ni mọ́.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìgbìmọ̀ ọba tí wọ́n fún Luwoo ni orúkọ burúkú yii náà ló rán Ọmọkùnrin rẹ̀ Adekola Telu lọ́wọ́ láti tẹ ìlú Iwo dó, ti o sì jẹ́ Oluwo tí ìlú Iwo àkọ́kọ́.