Ondo killing: Ta ló pa ẹbí olùrànlọ́wọ́ Gómìnà Rotinmi Akeredolu sórí oko rẹ̀ l'Ondo?

Rotimi Akeredolu

Oríṣun àwòrán, Facebook/Rotimi Akeredolu Aketi

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Iroyin kan ti n ja rain-rain lori ayelujara pe awọn afurasi Fulani darandaran ti ṣekupa ẹbi oluranlọwọ Gomina Rotinmi Akeredolu ipinlẹ Ondo lori ọrọ iroyin, Gani Muhammed Ajowa sori oko rẹ.

Ọgbẹni Dayo Ibiye ni oluranlọwọ Akeredolu sọ loju opo Facebook pe awọn afurasi Fulani ti pa ninu oko rẹ to wa ni Ajowa.

O sọ loju opo rẹ bayii pe ''Dayo Ibiye, ọkunrin niọ, ṣugbọn bi wọn ṣe ri ọ mu lo ya mi lẹnu.''

Ṣugbọn Kọmiṣọnna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Bolaji Salami sọ fun BBC Yoruba pe ko si ẹni to le sọ bo ya awọn Fulani darandaran lo pa Ibiye bayii.

Ọgbẹni Salami ṣalaye pe apa wa lara oku oloogbe naa ṣugbọn iwadii n lọ lọwọ lati mọ ohun to ṣe okunfa iku Ọgbẹni Abiye gan an.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa Ondo: Wo ìdí tí Yorùbá ṣe ń lo Ìjàpá ni olú ẹ̀dá ìtàn Àlọ́ Àpagbé- Oyelo

''O le jẹ pe ija lo ṣẹlẹ laarin ọkunrin atawọn agbẹ mii, amọ iwadii si lọ lọwọ lori ohun to ṣe okunfa iku ọkunrin gan an,'' ọga ọlọpaa lo sọ bẹẹ.

Ọgbẹni Salami fikun ọrọ rẹ pe iyawo oloogbe naa lo fi to awọn ọlọpaa leti lẹyin ti wọn o ri Abiye ko pada wale lati oko.

Ọga ọlọpaa Ondo sọ pe awọn agbofinro ti wa ni agbegbe oko ti iṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ, wọn si ti gbe oku ọkunrin naa lọ si ile igboku si.

Àkọlé fídíò, Big breast: Oluwatosin Adegboro, Oluwaseun Amoo, Remi Fatolu: Ẹlòmíì ń fi irú ọyàn wa tọrọ