ASUU 2021 strike: Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ UI ní ìyanṣẹ́lódì àwọn òṣìṣẹ́ fásítì ń ṣe àkọ́bá tó pọ̀ fáwọn

Ẹgbẹ awọn olukọ agba ni awọn ile ẹkọ giga fasiti to n bẹ loriẹede yii labẹ asia SSANU ati awọn oṣiṣẹ ti ki i ṣe olukọ, NASU ti bẹrẹ iyanṣẹlodi lonii.
Ọkan lara awọn aṣoju ẹgbẹ oṣiṣẹ naa ni fasiti ilẹ Ibadan, Wale Akinrẹmi ba BBC Yoruba sọrọ ninu ọgba ile ẹkọ naa l'ọjọ Ẹti.
O ni ikuna ijọba apapọ lori awọn owo ati ajẹmọnu ti wọn jẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ naa lo fa iyanṣẹlodi ti wọn gunle.
- '' Ìrọ ní ò, N51.8million kọ́ ní àwọn Naijiria dá fún Sunday Igboho, N4milion ní''
- Kábíyèsí Ooni ti forí jin Sunday Igboho lẹ́yìn tó túúbá- Ààfin Ile Ife
- Ìdí rèé tí Ibadan ṣe ja ogun Kiriji pẹ̀lú Ekiti àti Ijesha f'ọ́dún mẹ́rìndínlógún
- Bàbá mi Ooni, ẹ foríjìn mí, ẹnu mi ò gbàá láti bú yín- Sunday Igboho tọrọ àforíjìn
- Ènìyàn 1,138 tún ti lùgbàdì ààrùn Covid-19 ní Nàijíríà
Bakan naa ni Akinrẹmi fi idi ọrọ mulẹ wi pe ẹgbẹ oṣiṣẹ naa ko ni gbaa laabọ ti ijọba ba kọ lati wọn ọn kun.
O ni atunṣe gbudọ waye lori gbogbo ẹtọ ti wọn n beere fun bẹrẹ lati ori afikun owo oṣu awọn oṣiṣẹ, ẹdinwo apo aṣuwọn IPPIS, owo oṣiṣẹ fẹyinti ati bẹẹbẹẹ lọ, ki iyanṣẹlodi naa to le wa si opin.
Pupọ ninu awọn eeyan to wa ninu ọgba ile ẹkọ naa lasiko ti a ṣe abẹwo sibẹ lo jẹ akẹkọọ to wa ni opin eto ẹkọ ati awọn to ti kẹkọọ pari ti wọn n mura lati lọ ṣe agunbanirọ.

Lara wọn ti o ba wa sọrọ ṣe alaye wi pe awọn iyanṣẹlodi to n waye ni lemọlemọ ni awọn ile ẹkọ giga to n bẹ lorilẹede yii lo n ṣe akoba ti o pọ fun itẹsiwaju aye awọn akẹkọọ.
Wọn fi kun ọrọ wọn wi pe oun ti wa ni opin eto ẹkọ, nnkan to si ku ni ki igbimọ ile ẹkọ giga fasiti ilẹ Ibadan buwọ lu esi idanwo ti wọn ṣe.
Eyi ni yoo fun wọn le lanfani lati lọ sin ilẹ baba wọn gẹgẹ bi i agunbanirọ, ṣugbọn iyanṣẹlodi to n lọ lọwọ bayii ti bẹgi dina igbesẹ naa.

Bakan naa ni wọn parọwa si ijọba apapọ lati ri si ọrọ awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ naa ki itẹsiwaju le de ba awọn akẹkọọ.
Ọjọ kejilelogun, oṣu keji ọdun yii lo yẹ ki awọn akẹkọọ fasiti ile Ibadan wọle pada sẹnu ẹkọ wọn gẹgẹ bi i awọn alakoso ile ẹkọ naa ṣe kede rẹ tẹlẹri.
Sugbọn o ṣeeṣe ki ẹto ẹkọ foju wina awọn idiwọ kan tabi omii ti awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ to bẹrẹ iyanṣẹ lodi lonii ba kọ lati pada sẹnu iṣẹ wọn.
- Kábíyèsí Ooni ti forí jin Sunday Igboho lẹ́yìn tó túúbá- Ààfin Ile Ife
- Wo àwọn gbajúgbajà ojú ti EFCC máa ba ṣe ẹjọ́ ní 2021
- Ẹ rọra ṣe pẹ̀lú àwọn ará ìlú lásìkò yìí nítorí Covid 19- IGP Adamu Mohammed
- Wo àwọn gbajúgbajà ojú ti EFCC máa ba ṣe ẹjọ́ ní 2021
- Ìdí rèé tí Ibadan ṣe ja ogun Kiriji pẹ̀lú Ekiti àti Ijesha f'ọ́dún mẹ́rìndínlógún



















