World Cancer Day: Ènìyàn 26,000 ni àìsàn jẹjẹrẹ ń pa lóòjọ́
Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àkọlé àwòrán, Ọjọ́ Kẹẹ̀rin, Osù Kejì ọdọọdún ni Àjọ Ètò Ìlera Lagbaye(WHO), là kalẹ̀ láti pe akíyésí àwọn ènìyàn sí àìsàn jẹjẹrẹ.
Ajọ Eto Ilera Lagbaye, WHO ti pe akiyesi awọn eniyan si ipa ti aisan jẹjẹrẹ n ko lawujọ, pẹlu akiyesi pe miliọnu mẹjọ eniyan ni yoo ku lọdun yii nipa aisan jẹjẹrẹ.
Ajọ Agbaye to ni akọri ti ọdun yii ni 'I am and I will', fikun wi pe ẹgbẹrun mẹrinlelọgbọn eniyan lo n ku lojoojumọ nitori aisan jẹjẹrẹ.
Ajọ naa fikun wi pe o ṣeeṣẹ ki o peleke si ninu ọdun yii pẹlu bi oju ọjọ ṣe n bajẹ si, ti igbe aye awọn eniyan o gbe pẹẹli si ati iru ounjẹ ti awọn eniyan n jẹ.
Àkọlé fídíò, Cancer: Àṣe ara mi ni iso ti n run gbogbo bí mo ṣe n ṣèrànwọ́ lórí jẹjẹrẹ
Kini awọn nkan to n fa aisan jẹjẹrẹ?
Ọjọ ori
Gbigbe igbe aye inira
Fifi taba lile ati oti mimu
Aisan inu ara
Sisanra lasanju le fa aisan jẹjẹre ọmu, ikun ati isalẹ inu pẹlu aisan jẹjẹrẹ ile ọmọ.
Àkọlé fídíò, World Cancer Day: Mo pàdánù ọkọ àti ọ̀rẹ́ bí mo ṣe ni 'Cancer'- Iwalade Adebimpe Adetunji